Zikiri tí ó lóore jùlọ: SubhanAllah, Alhamdulillah, La ilaha illallah

Àwọn ọ̀rọ̀ zikiri kúkúrú tí ẹ̀san wọn tóbi, fún ìgbàkígbà ní ọjọ́.

1 Ẹ̀ẹ̀kan

لَا إِلَهَ إِلَّا اللَّهُ

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Jabir - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Mo gbọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí n sọ pé: "Eyi tó lọ́lá jùlọ ninu awọn iranti Ọlọhun ni gbolohun: LAA ILAAHA ILLALLOOH, eyi tó sì lọ́lá jùlọ ninu awọn adura ni gbolohun: ALHAMDULILLAH".

Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa ninu al-Kubrọ, ati Ibnu Maajah Ipò: O daa

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ fún wa pé iranti Ọlọhun tó lọ́lá jùlọ ni: "LAA ILAAHA ILLALLOOH" itumọ rẹ̀ ni pé kò sí nkankan tí a gbọdọ̀ jọsin fun pẹlu ododo ayafi Ọlọhun Allah, ati pé adura tó lọ́lá jùlọ ni ALHAMDULILLAH; iyẹn ni pé a n fi rinlẹ̀ pé dajudaju Allahu ni Oluṣedẹra fún wa, Oun ni O sì lẹtọọ si iroyin tó pé, tó sì dara julọ.

Àwọn àǹfààní

  • Ìgbani ní ìyànjú lati maa ṣe iranti Ọlọhun ni pupọ pẹlu gbolohun iṣe Ọlọhun lọ́kan, ati lati maa gbadura pẹlu gbolohun ọpẹ́.

Kà á lórí HadeethEnc.com

2 Ẹ̀ẹ̀kan

سُبْحَانَ اللَّهِ، وَالْحَمْدُ لِلَّهِ، وَلَا إِلَهَ إِلَّا اللَّهُ، وَاللَّهُ أَكْبَرُ

Ìtumọ̀ àti orísun

Láti ọ̀dọ̀ Samurah ọmọ Jundub- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ọ̀rọ̀ ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ mẹrin ni: SUBHAANALLAH, ati ALHAMDULILLAAH, ati LAA ILAAHA ILLALLOOH, ati ALLAHU AKBAR, èyíkéyìí ti o ba wù ọ ni o le fi bẹ̀rẹ̀ nínú wọn”.

Muslim gba a wa Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe ọ̀rọ̀ ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ mẹ́rin ni:

SUBHAANALLAH: O n túmọ̀ sí fifọ Ọlọhun mọ́ kuro nibi gbogbo adinku.

ALHAMDULILLAAH: Oun ni fífi pípé ròyìn Ọlọhun pẹlu ìfẹ́ Rẹ̀ ati gbigbe E tobi.

LAA ILAAHA ILLALLOOH: Ìtumọ̀ rẹ ni: Ko si ẹni ti a le maa jọ́sìn fun ni ododo ayafi Ọlọhun.

ALLAHU AKBAR: Ìtumọ̀ rẹ ni: O gbọnngbọn, O si tobi, O si ni agbara ju gbogbo nnkan lọ.

Ati pe ọla rẹ ati rírí ẹsan rẹ, ko beere fun títò ó tẹle ara wọn ti a ba n pe wọn jáde lẹ́nu.

Àwọn àǹfààní

  • Irọrun sharia, latara pe o le bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú èyíkéyìí tí o ba fẹ ninu awọn gbolohun naa.

Kà á lórí HadeethEnc.com

3 Ẹ̀ẹ̀kan

سُبْحَانَ اللَّهِ وَبِحَمْدِهِ، سُبْحَانَ اللَّهِ الْعَظِيمِ

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o gba a wa lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, o sọ pe: “Gbólóhùn meji kan ti wọn fúyẹ́ lori ahọ́n, ti wọn wúwo ninu òṣùwọ̀n, ti Ajọkẹ-aye nífẹ̀ẹ́ si méjèèjì ni: SUBHAANALLOOHIL AZEEM, SUBHAANALLOOHI WA BIHAMDIHII”.

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ nipa gbólóhùn méjì kan ti ọmọniyan maa n pe ni gbogbo iṣesi láìsí inira nibẹ, ẹ̀san méjèèjì si tobi ninu òṣùwọ̀n, ati pe Oluwa wa Ajọkẹ-aye ti ọla Rẹ ga si nífẹ̀ẹ́ si méjèèjì:

SUBHAANALLOOHIL AZEEM, SUBHAANALLOOHI WA BIHAMDIHII; fun nǹkan ti méjèèjì ko sinu bii iroyin Ọlọhun pẹlu titobi ati pípé, ati fifọ Ọ mọ kuro nibi àléébù.

Àwọn àǹfààní

  • Iranti ti o tobi ju ni ki èèyàn da afọmọ Ọlọhun papọ mọ ẹyìn rẹ.
  • Alaye gbígbòòrò aanu Ọlọhun fun awọn ẹru Rẹ, O maa n ṣẹsan iṣẹ kekere pẹlu ẹ̀san ti o pọ.

Kà á lórí HadeethEnc.com

4 Ẹ̀ẹ̀kan

سُبْحَانَ اللَّهِ، وَالْحَمْدُ لِلَّهِ، وَلَا إِلَهَ إِلَّا اللَّهُ، وَاللَّهُ أَكْبَرُ

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe: “Ki n sọ pe: Subhaanallah, wal hamdulillah, wa laa ilaaha illallohu, wallohu akbar, jẹ nnkan ti mọ nifẹẹ sí ju nnkan ti oorun ran le lori lọ”.

Muslim gba a wa Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju riranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pẹlu awọn gbolohun ti wọn tobi yii loore ju aye ati nnkan ti o wa ninu rẹ lọ, awọn naa ni:

“Subhaanallah”: Afọmọ ni fun Ọlọhun kuro nibi awọn adinku.

“Alhamdulillah”: Ẹyin ni fun Un pẹlu awọn iroyin pipe pẹlu nini ifẹ Rẹ ati gbigbe E tobi.

“Laa ilaaha illallohu”: ko si ẹni ti a le maa jọsin fun pẹlu ẹtọ afi Ọlọhun.

“Allahu Akbar”: Ẹni ti O tobi julọ ti O gbọnngbọn ju gbogbo nnkan lọ.

Àwọn àǹfààní

  • Ṣisẹnilojukokoro lori iranti Ọlọhun, ati pe o jẹ nnkan ti a nifẹẹ ju nnkan ti oorun ran le lori lọ.
  • Ṣisẹnilojukokoro lori mimaa ṣe iranti lọpọlọpọ; nitori nnkan ti o wa nibẹ bi ẹsan ati ọla.
  • Igbadun aye kere ati pe awọn adun rẹ maa tan.

Kà á lórí HadeethEnc.com

5 ìgbà 100

سُبْحَانَ اللَّهِ وَبِحَمْدِهِ

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni ti o ba sọ pe: SUBHAANALLOOHI WA BIHAMDIHII, ni ìgbà ọgọ́rùn-ún ni ojúmọ́, wọn maa pa àwọn ẹṣẹ rẹ rẹ kódà ki o da gẹgẹ bii ìfòfó agbami odò”.

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé ẹni tí o ba sọ pe SUBHAANALLOOHI WA BIHAMDIHII, ni ìgbà ọgọ́rùn-ún ni ojúmọ́, wọn maa pa ẹṣẹ rẹ rẹ, wọn si maa fi ori jin in, kódà ki ẹṣẹ rẹ pọ bii ifofo funfun ti o maa n wa lókè agbami odò nigba ti ìgbì rẹ ba n bì ati ti o ba ru sókè

Àwọn àǹfààní

  • Ẹsan yii maa jẹ ti ẹni tí ó bá wí i ni ojúmọ́ léraléra tabi kélekèle.
  • AT-TESBIIH: Oun ni mimọ Ọlọhun kúrò nibi adinku, AL-HAMDU: Oun ni fifi pípé ròyìn rẹ pẹ̀lú ìfẹ́ ati gbigbetobi.
  • Ohun ti a gbèrò nibi hadiisi naa ni pipa àwọn ẹṣẹ kéékèèké rẹ, ṣùgbọ́n ẹṣẹ ńlá, dandan ni ki èèyàn tuuba kuro nibẹ.

Kà á lórí HadeethEnc.com

6 Ẹ̀ẹ̀kan

لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ وَحْدَهُ لَا شَرِيكَ لَهُ، اللهُ أَكْبَرُ كَبِيرًا، وَالْحَمْدُ لِلَّهِ كَثِيرًا، سُبْحَانَ اللهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ، لَا حَوْلَ وَلَا قُوَّةَ إِلَّا بِاللهِ الْعَزِيزِ الْحَكِيمِ

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Sa'd- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Larubawa oko kan wa ba ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ pe: Kọ mi ni ọrọ kan ti maa maa sọ ọ: O sọ pe: " Sọ pe: Laa ilaaha illallohu wahdaHu laa shariika laHu, Allahu Akbar kabeeran, wal amdulillah katheeran, Subhaanallah Robbil 'aalameen, laa haola wa laa quwwata illa billahil Azeezil Hakeem" o sọ pe: Awọn wọnyi jẹ ti Oluwa mi, ki ni o jẹ temi? O sọ pe: Sọ pe: Allahumo igfir liy warhamniy wahdiniy warzuqniy".

Muslim gba a wa Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Arakunrin kan ninu awọn ti wọn n gbe oko beere lọwọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lati kọ oun ni iranti kan ti o ma maa sọ ọ, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pé: Sọ pe: "Laa ilaaha illallohu wahdaHu laa shariika laHu" o bẹ̀rẹ̀ pẹlu jijẹrii imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo, ìtumọ̀ rẹ ni pe ko si ẹni ti a le jọsin fun pẹlu ẹtọ afi Allahu, "Allahu Akbar kabeeran" O n túmọ̀ si pe: Ọlọhun tobi ju gbogbo nnkan lọ O si ga ju wọn lọ, "Wal amdulillah katheeran" O túmọ̀ si pe: Ọpẹ ni fun Ọlọhun ni eyi ti o pọ, lori awọn iroyin Rẹ ati awọn iṣẹ Rẹ ati awọn idẹra Rẹ ti ko ṣee ka, "Subhaanallah Robbil 'aalameen" O túmọ̀ si pe: O mọ kuro nibi adikun, "Laa aola wa laa quwwata illa billahil Azeezil Hakeem" O túmọ̀ si pe: Ko si ìyípadà lati isẹsi kan si isẹsi miiran afi pẹlu Ọlọhun ati iranlọwọ Rẹ ati ifiniṣe-kongẹ Rẹ, Arakunrin naa sọ pe: Awọn ọrọ wọnyii jẹ ti Oluwa mi lati ṣe iranti Rẹ ati gbigbe E tobi, ki ni o wa fun mi ninu adura fun ara mi? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pé: Sọ pe: "Allahumo igfir liy", Ọlọhun mi, fori jin mi Pẹlu pipa awọn aburu rẹ ati bibo o, "Warhamniy" ki O si kẹ mi Pẹlu mimu awọn anfaani ti ọrun ati ti aye ba mi, "Wahdiniy" ki O si tọ mi sọ́nà Si eyi ti o dara julọ ninu awọn isẹsi ati si oju ọna taara, "Warzuqniy" ṣe arisiki fun mi Pẹlu owo halaali ati alaafia ati gbogbo oore ati alaafia.

Àwọn àǹfààní

  • Ṣisẹnilojukokoro lori iranti Ọlọhun pẹlu mimu U lọkan ṣoṣo ati gbigbe E tobi ati didu ọpẹ fun Un ati ṣíṣe afọmọ fun Un.
  • Ṣíṣe iranti Ọlọhun ni nnkan ti a fẹ ati yiyin In ṣíwájú àdúrà.
  • Ṣíṣe ki ọmọniyan maa tọrọ adura pẹlu eyi ti o daa julọ ninu adura ni ohun ti a fẹ, ati pẹlu nnkan ti o wa ninu hadiisi ninu nnkan ti ohun ti o ko oore aye ati ọrun sinu n bẹ nibẹ, o si tun le ṣe adura pẹlu nnkan ti o ba fẹ.
  • O tọ fun ẹru ki o ṣe ojúkòkòrò lati wa imọ nipa nnkan ti o maa ṣe e ni anfaani ni aye ati ọrun.
  • Isẹnilojukokoro lori wiwa aforijin ati ikẹ ati arisiki, oun ni o kó oore sínú.
  • Ini aanu Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori kikọ ìjọ rẹ ni nnkan ti o maa ṣe wọn ni anfaani.
  • Wọn dárúkọ ikẹ lẹyin aforijin ki afọmọ naa le pe, aforijin ni bibo awọn ẹṣẹ ati pipa wọn rẹ ati imunijina kuro nibi ina, ikẹ ni mimu awọn oore ba ni ati wiwọ inu alujanna, ati pe eleyii ni ere ti o tobi.

Kà á lórí HadeethEnc.com

7 Ẹ̀ẹ̀kan

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Abu Maalik Al-Ash’ari- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Imọra ni idaji igbagbọ, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH maa n kun òṣùwọ̀n, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH ati gbolohun SUBHAANALLAH, mejeeji maa n kun- tabi o n kun- nnkan ti o n bẹ laaarin sanmọ ati ilẹ, ati pe irun jẹ imọlẹ, saara jẹ awijare, suuru jẹ imọlẹ, Kuraani maa jẹ ẹri fun ẹ tabi ki o tako ẹ, gbogbo eniyan yoo maa jáde lọ ní aarọ ni ẹni ti o n ta ẹmi ara rẹ, ninu ki o la a kúrò ninu iná, tabi ki o ko ìparun ba a”.

Muslim gba a wa Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: Dajudaju imọra ti ìta maa jẹ pẹlu aluwala ati iwẹ, ati pe o jẹ majẹmu fun irun. Ati pe sisọ gbolohun: “ALHAMDULILLAH, o n kun òṣùwọ̀n”, oun ni ẹyin fun Un- mimọ ni fun Un-, ati ìròyìn rẹ pẹlu ìròyìn pipe, wọn maa wọn ọn ni ọjọ́ igbende alukiyaamọ, o maa waa kún òṣùwọ̀n iṣẹ. Ati pe sisọ gbolohun: “Subhaanallah ati Alhamdulillah” oun ni ṣíṣe afọmọ Rẹ kuro nibi gbogbo adinku ati riroyin Rẹ pẹlu pipe ti o pe ti o tọ si titobi Rẹ pẹlu nini ifẹ Rẹ ati gbigbe E tobi, yoo kun nnkan ti o wa laaarin sanmọ ati ilẹ. Ati pe “irun jẹ imọlẹ” fun ẹru ni ọkan rẹ, ati ni oju rẹ, ati ninu sàréè rẹ, ati nibi igbedide rẹ. Ati pe “Saara ṣíṣe jẹ awijare” ati ẹri lori ododo igbagbọ olugbagbọ, ati iyapa rẹ si ṣọbẹ-ṣelu ti kii ṣe saara; nitori pe ko ni igbagbọ si ohun ti wọn ṣe adehun rẹ lórí saara ṣíṣe. Ati pe “Suuru ṣíṣe jẹ imọlẹ” -oun ni kiko ẹ̀mí ro nibi ìgbónára ati ibinu- imọlẹ kan ni ti igbona ati jijo nkan maa n waye pẹlu rẹ, gẹgẹ bii imọlẹ oòrùn; nitori pe nnkan ti o nira ni, o si n bukaata si jija ẹ̀mí naa logun ati dide e kuro nibi nnkan ti o n fẹ; ẹni ti o ba ni i ko nii yẹ ko nii gbo ni ẹni ti yoo maa mọna ti yoo si maa tẹsiwaju lori nnkan ti o tọna. Oun ni ṣíṣe suuru lori itẹle ti Ọlọhun, ati kuro nibi ẹṣẹ, ati suuru ṣíṣe lori awọn ajalu ati awọn oniran-anran àwọn nnkan ti eeyan korira ni ayé. Ati pe “Kuraani jẹ awijare fun ẹ” pẹlu kika a ati ṣíṣe ìṣẹ́ pẹlu rẹ, tabi “awijare tako ẹ” pẹlu gbigbe e ju silẹ lai fi ṣe iṣẹ́ tabi kika a. Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju gbogbo eniyan n gbiyanju ti wọn n fọnka ti wọn si n dide lati oju orun wọn ti wọn n jade lati inu awọn ile wọn tori awọn ìṣẹ́ wọn ni oríṣiríṣi, O wa ninu wọn ẹni ti o n duro deedee lori itẹle ti Ọlọhun ti yoo tu ẹ̀mí rẹ kuro ninu ina, o si wa ninu wọn ẹni ti yoo yẹ kuro nibi ìyẹn ti yoo si ko si inu awọn ẹṣẹ ti yoo si pa a run pẹlu wiwọ ina.

Àwọn àǹfààní

  • Imọra pin si meji: Imọra ti ita, o maa waye pẹlu aluwala ati iwẹ, ati imọra ti inú, o maa waye pẹlu imu Ọlọhun ni Ọkan ati igbagbọ ati iṣẹ oloore.
  • Pataki mímú ojú tó irun ati pe o jẹ imọlẹ fun erusin Ọlọhun ni aye ati ọjọ igbedide.
  • Saara ṣíṣe jẹ ẹri lori ododo igbagbọ.
  • Pataki ṣíṣe iṣẹ pẹlu Kuraani ati gbigba a lododo lati le jẹ ẹri fun ẹ ti ko nii tako ẹ.
  • Ẹmi ti o ko ba ko airoju ba a pẹlu itẹle yoo ko airoju ba ẹ pẹlu ẹṣẹ.
  • Gbogbo eniyan dandan ni fun un pe ko ṣiṣẹ; ninu pe ki o bọ okun lọrun ara rẹ pẹlu itẹle tabi ki o ko iparun ba a pẹlu ẹṣẹ.
  • Suuru ṣíṣe n bukaata si atẹmọra ati wiwa ẹsan ti ilekoko si n bẹ nibẹ.

Kà á lórí HadeethEnc.com

Àwọn ìbéèrè

Kí ló wà lórí ojú-ìwé yìí?

Zikiri tí ó lóore jùlọ: ọ̀kọ̀ọ̀kan ní èdè Lárúbáwá, pẹ̀lú ìtumọ̀ rẹ̀, hadiisi tí ó ti wá, ipò rẹ̀ àti àlàyé.

Níbo ni àwọn ìtumọ̀ ti wá?

Láti HadeethEnc.com, Ìwé Ìmọ̀ Àwọn Hadiisi Ànábì Tí A Túmọ̀. A ń fi hadiisi kọ̀ọ̀kan hàn gẹ́lẹ́ bí wọ́n ṣe tẹ̀ ẹ́ jáde, pẹ̀lú orísun àti ipò rẹ̀, àti ìjápọ̀ sí ojúlówó rẹ̀.

Báwo ni ẹ̀rọ ìkà ṣe ń ṣiṣẹ́?

Tẹ ẹ̀rọ ìkà tí ó wà lábẹ́ zikiri kan, yóò sì máa kà sẹ́yìn títí dé òdo. Ojú-ìwé yìí nìkan ni ó wà, a kò sì fi ohunkóhun pamọ́.

Ṣé mo lè gba ìrántí ojoojúmọ́?

Bẹ́ẹ̀ni. Ohun èlò Qabas ọ̀fẹ́ fún Android máa ń rán ọ létí zikiri òwúrọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ lójoojúmọ́, ó sì ní ẹ̀rọ ìkà kan náà.