Adua àforíjìn (istighfar)

Sayyidul Istighfar àti àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn tí a fi ń tọrọ àforíjìn láti inú Sunnah.

1 Ẹ̀ẹ̀kan

اللَّهُمَّ أَنْتَ رَبِّي لَا إِلَهَ إِلَّا أَنْتَ خَلَقْتَنِي وَأَنَا عَبْدُكَ وَأَنَا عَلَى عَهْدِكَ وَوَعْدِكَ مَا اسْتَطَعْتُ أَعُوذُ بِكَ مِنْ شَرِّ مَا صَنَعْتُ أَبُوءُ لَكَ بِنِعْمَتِكَ عَلَيَّ وَأَبُوءُ لَكَ بِذَنْبِي فَاغْفِرْ لِي فَإِنَّهُ لَا يَغْفِرُ الذُّنُوبَ إِلَّا أَنْتَ

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Shaddad bin Aws, ki Ọlọhun yọnu si i, lati ọdọ anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a –: “Olori iwaforijin ni ki o sọ pe: Allahummọ anta Rọbbii laa ilaaha illaa anta, khalaqtanii, wa anaa abduka wa anaa alaa ahdika wawahdika mastatahtu, auuzu bika min sharri maa sanahtu, abuuhu laka binihmatika alayya, wa abuuhu bizambii, fagfir lii, fa innahuu laa yagfiruz zunuuba illaa anta", o sọ pe: Ẹni ti o ba sọ ọ ni aarọ ti o si ni amọdaju pẹlu ẹ, ti o wa kú, ni ọjọ naa ki o to di irọlẹ, o maa wa ninu awọn ọmọ alujanna, ẹni tí ó bá sọ ọ ni alẹ ti o si ni amọdaju pẹ̀lú ẹ, ti o wa kú ki ilẹ o to mọ́, o maa wa ninu awọn ọmọ alujanna".

Bukhaariy gba a wa Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ wipe: Awọn gbolohun kan wa fun wíwá idarijin, ati pe eyi ti o dara ju ti o si tobi ju ninu wọn ni ki ẹru maa sọ pe: "Allahummọ anta Robbii laa ilaaha illaa anta, khalaktanii, wa anaa abduka wa anaa alaa ahdika wa wahdika mastatahtu, auuzu bika min sharri maa sonahtu, abuuhu laka binihmatika alayya wa abuuhu bizambii fagfir lii fa innahuu laa yagfiruz zunuuba illaa anta" Ẹru maa fi taohid rinlẹ fun Ọlọhun ni akọkọ, ati pe Ọlọhun ni O da a, Oun si ni yoo maa jọ́sìn fun ti ko si orogun fun Un, ati pe oun wa lori ohun ti o ṣe adehun rẹ fun Ọlọhun bii ini igbagbọ si I ati itẹle E ni ibamu si ikapa rẹ; torí pé ko si bi ẹrú ṣe le sin Ọlọhun tó, ko le ni ikapa lati ṣe gbogbo nnkan ti Ọlọhun pa a láṣẹ ki o ṣe, bẹ́ẹ̀ si ni ko lee kapa lati dúpẹ́ ìdẹ̀ra Rẹ bi o ṣe yẹ, o si maa sadi Ọlọhun, o si tun maa dirọ mọ ọn, torí pé Oun ni Ẹni tí a maa n sadi kuro nibi aburu ti ẹrú ba ṣe, Ó maa fi rinlẹ ó sì maa jẹ́wọ́ ìbùkún rẹ̀ fún un, ó sì maa padà sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nípa fifirinlẹ àti jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àìgbọràn rẹ̀, Lẹ́yìn ẹ̀bẹ̀ ipada si ọdọ Ọlọ́run yìí, ó maa bẹ Olúwa rẹ̀ pé kí O forijìn òun nípa bíbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀, kí O sì dáàbò bò òun kuro nibi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú àforíjìn, oore àti àánú Rẹ̀, nítorí pé kò sẹ́ni tó máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jìn, àfi Òun, Ọba ti O lágbára ti O gbọnngbọn. Lẹyin naa, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe o wa ninu awọn asikiri àárọ̀ ati alẹ, ẹni tí ó bá sọ ọ pẹ̀lú amọdaju ati ìrántí àwọn ìtumọ̀ rẹ̀, ati ini igbagbọ si i ni aarọ ọjọ́ naa, laarin yiyọ oorun si yiyẹ àtàrí rẹ, oun naa ni àsìkò ọsan, ti o wa ku, o maa wọ alujanna, Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ́ ní alẹ́, láti ìwọ̀ oòrùn títí di àfẹ̀mọ́jú, tí ó sì kú kí ilẹ o to mọ́, yóò wọ alujanna.

Àwọn àǹfààní

  • Awọn agbekalẹ fun wiwa àforíjìn yatọ si ara wọn, wọ́n si tun lọla jura wọn lọ.
  • O yẹ ki ẹru o maa ṣe ojúkòkòrò lati maa gbadura si Ọlọhun pẹlu adua yii; nítorí pé oun ni olori iwaforijin.

Kà á lórí HadeethEnc.com

2 Ẹ̀ẹ̀kan

Ìtumọ̀ àti orísun

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ninu nǹkan ti o gba wa lati ọdọ Olúwa rẹ tí Ó lágbára ti O gbọnngbọn, O sọ pe: “Ẹru mi da ẹṣẹ kan, o wa sọ pé: Irẹ Ọlọhun, fi orí ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun Àlekè-ọla wa sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o si mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti O si maa n fi iya ẹṣẹ jẹ eeyan, lẹyin naa o tun ṣẹri pada si idi ẹṣẹ, o wa tun sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga tun sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o si mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti O si maa n fi iya ẹṣẹ jẹ eeyan, lẹyin naa o tun ṣẹri pada si idi ẹṣẹ, o wa tun sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga tun sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o si mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti O si maa n fi iya ẹṣẹ jẹ eeyan, maa ṣe ohun ti o ba fẹ́, mo ti fi ori jin ọ”.

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n gba ẹgbawa láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ pe ti ẹrú ba da ẹṣẹ kan, ti o wa sọ pé: Irẹ Ọlọhun, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o wa mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti yoo waa bo o ni àṣírí, ti yoo si ṣe amojukuro fun un, tabi ki O fi ìyà jẹ ẹ lori ẹ, Mo ti fi ori jin in. Lẹ́yìn naa ni o tun tun ẹṣẹ da, o wa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun wa sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o wa mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti yoo waa bo o ni àṣírí, ti yoo si ṣe amojukuro fun un, tabi ki O fi ìyà jẹ ẹ lori ẹ, Mo ti fi ori jin ẹrú Mi. Lẹ́yìn naa ni o tun tun ẹṣẹ da, o wa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun wa sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o wa mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti yoo waa bo o ni àṣírí, ti yoo si ṣe amojukuro fun un, tabi ki O fi ìyà jẹ ẹ lori ẹ, Mo ti fi ori jin ẹrú Mi. Ki o maa ṣe ohun ti o ba fẹ́ lópin ìgbà ti o ba jẹ pe ti o ba ti n da ẹṣẹ naa ni yoo maa fi ẹṣẹ naa sílẹ̀, ti yoo si ká abamọ, ti yoo si pinnu pé oun ko nii pada síbẹ̀ mọ, ṣùgbọ́n ẹ̀mí rẹ maa borí rẹ, yoo tun wa da ẹṣẹ naa padà, lópin ìgbà ti o ba n ṣe báyìí, ti o n da ẹṣẹ, ti o si n ronupiwada, maa fi ori jin in; torí pé ìrònúpìwàdà maa n wó ohun ti o ba ṣáájú rẹ ni.

Àwọn àǹfààní

  • Gbigbaaye aanu Ọlọhun si awọn ẹru Rẹ, ati pe ẹṣẹ yòówù ki ọmọniyan da, ohunkóhun yòówù ki o ṣe, ti o ba ti ronupiwada, Ọlọhun maa gba ìrònúpìwàdà rẹ.
  • Ẹni ti o gbagbọ ninu Ọlọhun maa ni ìrètí amojukuro Olúwa rẹ, o si maa paya ìyà Rẹ̀, yoo waa tètè yára lọ ronupiwada, ko si nii tẹsiwaju nibi ẹṣẹ naa.
  • Májẹ̀mú ironupiwada ti o ni alaafia ni: Jijawọ kuro nibi ẹṣẹ, ati kika abamọ lori ẹ, ati ìpinnu pe èèyàn ko nii pada sibi ẹṣẹ naa mọ. Tí ìrònúpìwàdà naa ba jẹ kúrò nibi awọn àbòsí ti a ṣe fún awọn èèyàn nipa dúkìá, tabi ọmọlúwàbí, tabi ẹ̀mí, o maa ṣe alekun májẹ̀mú kẹrin, oun naa ni: Bíbọ́ kuro lọwọ ẹni tí ó ni ẹtọ, tabi fifun un ni ẹtọ rẹ.
  • Pataki imọ nipa Ọlọhun, eyi ti yoo sọ ẹrú di onimimọ nipa awọn alamọri ẹsin rẹ, yoo wa maa ronupiwada nígbàkúùgbà ti o ba ti ṣe àṣìṣe, ko nii sọreti nu, ko si nii tẹsiwaju.

Kà á lórí HadeethEnc.com

Àwọn ìbéèrè

Kí ló wà lórí ojú-ìwé yìí?

Adua àforíjìn: ọ̀kọ̀ọ̀kan ní èdè Lárúbáwá, pẹ̀lú ìtumọ̀ rẹ̀, hadiisi tí ó ti wá, ipò rẹ̀ àti àlàyé.

Níbo ni àwọn ìtumọ̀ ti wá?

Láti HadeethEnc.com, Ìwé Ìmọ̀ Àwọn Hadiisi Ànábì Tí A Túmọ̀. A ń fi hadiisi kọ̀ọ̀kan hàn gẹ́lẹ́ bí wọ́n ṣe tẹ̀ ẹ́ jáde, pẹ̀lú orísun àti ipò rẹ̀, àti ìjápọ̀ sí ojúlówó rẹ̀.

Ṣé mo lè gba ìrántí ojoojúmọ́?

Bẹ́ẹ̀ni. Ohun èlò Qabas ọ̀fẹ́ fún Android máa ń rán ọ létí zikiri òwúrọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ lójoojúmọ́, ó sì ní ẹ̀rọ ìkà kan náà.