Ìsìlámù nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́

Ẹ̀kọ́ 3 nínú 4

Báwo ni Mùsùlùmí ṣe gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ àti bá aládùúgbò lò?

Láti inú Al-Qur'ān

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا يَسۡخَرۡ قَوۡمٞ مِّن قَوۡمٍ عَسَىٰٓ أَن يَكُونُواْ خَيۡرٗا مِّنۡهُمۡ وَلَا نِسَآءٞ مِّن نِّسَآءٍ عَسَىٰٓ أَن يَكُنَّ خَيۡرٗا مِّنۡهُنَّۖ وَلَا تَلۡمِزُوٓاْ أَنفُسَكُمۡ وَلَا تَنَابَزُواْ بِٱلۡأَلۡقَٰبِۖ بِئۡسَ ٱلِٱسۡمُ ٱلۡفُسُوقُ بَعۡدَ ٱلۡإِيمَٰنِۚ وَمَن لَّمۡ يَتُبۡ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّٰلِمُونَ ﴿١١﴾ يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱجۡتَنِبُواْ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلظَّنِّ إِنَّ بَعۡضَ ٱلظَّنِّ إِثۡمٞۖ وَلَا تَجَسَّسُواْ وَلَا يَغۡتَب بَّعۡضُكُم بَعۡضًاۚ أَيُحِبُّ أَحَدُكُمۡ أَن يَأۡكُلَ لَحۡمَ أَخِيهِ مَيۡتٗا فَكَرِهۡتُمُوهُۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ تَوَّابٞ رَّحِيمٞ ﴿١٢﴾

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, àwọn ènìyàn kan kò gbọ́dọ̀ fi àwọn ènìyàn kan ṣe yẹ̀yẹ́. Ó lè jẹ́ pé àwọn (tí wọ́n sọ di oníyẹ̀yẹ́) dára ju àwọn (tó ń ṣe yẹ̀yẹ́). Àwọn obìnrin kan (kò sì gbọ́dọ̀ fi) àwọn obìnrin kan (ṣe yẹ̀yẹ́). Ó lè jẹ́ pé àwọn (tí wọ́n sọ di oníyẹ̀yẹ́) dára ju àwọn (tó ń ṣe yẹ̀yẹ́). Ẹ má ṣe búra yín. Ẹ má pe’ra yín ní ìnagijẹ burúkú. Orúkọ burúkú (tí kò bá òfin ẹ̀sìn mu) burú lẹ́yìn ìgbàgbọ́ òdodo. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ronú pìwàdà, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni alábòsí. Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jìnnà sí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àbá dídá. Dájúdájú ẹ̀ṣẹ̀ ni apá kan àbá dídá. Ẹ má ṣe tọpinpin ara yín. Kí apá kan yín má ṣe sọ̀rọ̀ apá kan lẹ́yìn. Ṣé ọ̀kan nínú yín nífẹ̀ẹ́ sí láti jẹ ẹran-ara ọmọ ìyá rẹ̀ ní òkú? Ẹ sì kórira rẹ̀. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

Al-Hujurat 49:11-12Kà á nínú Al-Qur'ān

Láti inú Sunnah

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- láti ọ̀dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé: “Ẹni tí ó bá gba Ọlọhun gbọ ati Ọjọ́ Ìkẹyìn, ki o maa sọ dáadáa tabi ki o dakẹ, ẹni tí ó bá gba Ọlọhun gbọ ati Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, ki o yaa maa ṣe apọnle aládùúgbò rẹ, ẹni tí ó bá gba Ọlọhun gbọ ati Ọjọ́ Ìkẹyìn, ki o maa ṣe apọnle àlejò rẹ”.

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni O ni alaafia HadeethEnc.com
Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe ti ẹrú ti o gba Ọlọhun gbọ ati Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ti o maa padà si ti wọn si maa san an ni ẹsan iṣẹ rẹ nibẹ, igbagbọ rẹ maa ṣe e ni ojúkòkòrò lori ṣíṣe àwọn nǹkan yii:

Akọkọ: Ọ̀rọ̀ dáadáa: Bii gbólóhùn SUBHAANALLAH ati LAA ILAAHA ILLALLOOH, ati pipaṣẹ dáadáa, ati kikọ ibajẹ, ati ṣíṣe àtúnṣe láàárín àwọn èèyàn, ti ko ba wa ṣe e, ki o yaa dakẹ, ki o si ma fi suta kan èèyàn, ki o si ṣọ ahọ́n rẹ.

Ìkejì: Ṣíṣe apọnle aládùúgbò: Pẹ̀lú ṣíṣe dáadáa si wọn, ati ki èèyàn si ma fi suta kan an.

Ikẹta: Ṣíṣe apọnle àlejò ti n bọ láti ṣe abẹwo rẹ: Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dáadáa, ati fífún un ní oúnjẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Amru - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Musulumi ni ẹni ti awọn musulumi la nibi ahọn rẹ ati ọwọ rẹ, ati pe Al-muhaajiru ni ẹni ti o yan nkan ti Ọlọhun kọ lodi».

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni O ni alaafia HadeethEnc.com
Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe dajudaju musulumi ti Isilaamu rẹ pe oun ni ẹni ti awọn musulumi la nibi ahọn rẹ, ko nii bu wọn, ko si nii ṣepe fun wọn, ko si nii sọ ọrọ wọn lẹyin, ko si nii maa fi ahọn rẹ tan èyíkéyìí ninu awọn iran ṣuta ka laarin wọn, Ti wọn si tun la ni ọwọ rẹ, ko si nii tayọ ẹnu-ala si wọn, ko si nii gba awọn dukia wọn ni ọna aitọ, ati nkan ti o jọ ìyẹn, Ati pe Al-muhaajiru ni ẹni ti o gbe nkan ti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe leewọ jusilẹ.

Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Jibril kò yẹ̀ kò gbò ni ẹni tí n sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun mi nipa aládùúgbò, titi ti mo fi lérò pé yoo mu u jogún”.

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni O ni alaafia HadeethEnc.com
Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe Jibril ko yẹ ni ẹni tí n pààrà fun un ti o si n pa a láṣẹ láti ni akolekan aládùúgbò ti ilé rẹ sunmọ, Mùsùlùmí ni tabi Kèfèrí, mọlẹbi ni tabi ẹni tí kii ṣe mọ̀lẹ́bí, pẹlu ṣiṣọ iwọ̀ rẹ, ki eeyan ma si fi suta kan an, ki èèyàn si maa ṣe daadaa si i, ki èèyàn si maa ṣe suuru lori suta rẹ, titi ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi lérò pe imisi maa sọ̀kalẹ̀ pé ki a maa fun un ninu dúkìá aládùúgbò rẹ ti o ba fi silẹ lẹ́yìn iku rẹ latara bi o ṣe bàbàrà iwọ̀ rẹ, ati bi Jibril ṣe n pààrà rẹ.

Gbogbo ẹ̀kọ́