Ẹ̀kọ́ 2 nínú 4
Kí ni Ìsìlámù sọ nípa àwọn òbí?
Láti inú Al-Qur'ān
۞ وَقَضَىٰ رَبُّكَ أَلَّا تَعۡبُدُوٓاْ إِلَّآ إِيَّاهُ وَبِٱلۡوَٰلِدَيۡنِ إِحۡسَٰنًاۚ إِمَّا يَبۡلُغَنَّ عِندَكَ ٱلۡكِبَرَ أَحَدُهُمَآ أَوۡ كِلَاهُمَا فَلَا تَقُل لَّهُمَآ أُفّٖ وَلَا تَنۡهَرۡهُمَا وَقُل لَّهُمَا قَوۡلٗا كَرِيمٗا ﴿٢٣﴾ وَٱخۡفِضۡ لَهُمَا جَنَاحَ ٱلذُّلِّ مِنَ ٱلرَّحۡمَةِ وَقُل رَّبِّ ٱرۡحَمۡهُمَا كَمَا رَبَّيَانِي صَغِيرٗا ﴿٢٤﴾
Olúwa rẹ pàṣẹ pé: “Ẹ má ṣe jọ́sìn fún ẹnì kan àyàfi Òun. Kí ẹ sì ṣe dáadáa sí àwọn òbí (yín) méjèèjì. Tí ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì tàbí ìkíní kejì wọn bá dàgbà sí ọ lọ́dọ̀, má ṣe ṣíọ̀ sí wọn, má ṣe jágbe mọ́ wọn. Máa bá àwọn méjèèjì sọ ọ̀rọ̀ àpọ́nlé. Rẹ apá rẹ nílẹ̀ dáadáa (bọ̀wọ̀) fún àwọn méjèèjì nípa ṣíṣe àánú wọn. Kí o sì sọ pé: “Olúwa Ẹlẹ́dàá mi, kẹ́ àwọn méjèèjì nítorí pé, àwọn méjèèjì náà tọ́ mi ní kékeré.”
وَوَصَّيۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ بِوَٰلِدَيۡهِ حَمَلَتۡهُ أُمُّهُۥ وَهۡنًا عَلَىٰ وَهۡنٖ وَفِصَٰلُهُۥ فِي عَامَيۡنِ أَنِ ٱشۡكُرۡ لِي وَلِوَٰلِدَيۡكَ إِلَيَّ ٱلۡمَصِيرُ ﴿١٤﴾
Àti pé A pa á ní àṣẹ fún ènìyàn nípa àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì - ìyá rẹ̀ gbé e ká (nínú oyún) pẹ̀lú àìlera lórí àìlera, ó sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀ láààrin ọdún méjì - (A sọ) pé: “Dúpẹ́ fún Èmi àti àwọn òbí rẹ méjèèjì.” Ọ̀dọ̀ Mi sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.