Adua lẹ́yìn ìpè ìrun (adhan)

Ohun tí a ń sọ nígbà tí wọ́n bá ń pe ìrun àti adua lẹ́yìn tí ìpè náà bá parí.

1 Ẹ̀ẹ̀kan

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Abu Sa‘ēd Al-khudriyy - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Tí ẹ ba ti gbọ ipe irun, ki ẹ yaa maa sọ iru nkan ti oluperun ba n sọ».

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣeni lojukokoro lori jijẹ ipe oluperun nigba ti a ba n gbọ ọ, ati pe ìyẹn ni ki a maa sọ nkan ti o n sọ, ni gbolohun gbolohun. Nigba ti o ba wa sọ gbolohun Allāh Akbar àwa naa o wi i lẹyin rẹ, ati pe nigba ti o ba mu gbolohun ijẹrii mejeeji wa, awa naa o mu un wa lẹ́yìn rẹ, Ati pe wọn ṣe ayaafi gbolohun: (Hayya ‘alas sọlāt, Hayya ‘alal falāh) wọn maa sọ lẹyin awọn mejeeji pe: lā haola walā quwwata illā biLlāh.

Àwọn àǹfààní

  • Yio maa tẹle oluperun keji lẹyin ti alakọkọọ ba pari, koda ki awọn oluperun o pọ! Latari kikari hadīth yii.
  • Yio maa jẹ ipe oluperun (yio maa sọ nkan ti o ba n sọ) ni gbogbo iṣesi rẹ, ti ko ba ti si ni ile ẹgbin tabi lori bukaata rẹ (itọ tabi igbẹ).

Kà á lórí HadeethEnc.com

2 Ẹ̀ẹ̀kan

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: «Ti oluperun ba sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, ti ẹnikẹni ninu yin naa wa sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Ash'adu an laa ilaaha illa Allāhu, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Ash'adu an laa ilaaha illa Allāhu, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Ash'adu anna Muhammadan rọsuuluLlaah, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Ash'adu anna Muhammadan rọsuuluLlaah, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Hayya‘ala sọlaah, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Laa haola walā quwwata illā biLlāh, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Hayya‘alal falaah, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Laa haola walā quwwata illā biLlāh, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Laa illaha illā Allāhu, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Laa illaha illā Allāhu lati inu ọkan rẹ wa yio wọ aljanna».

Muslim gba a wa Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Irun pipe ni fifi mọ awọn eeyan wiwọle asiko irun, ati pe awọn gbolohun irun pipe jẹ awọn gbolohun ti wọn ko adisọkan igbagbọ sinu.

Ati pe ninu hadīth yii Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye nkan ti wọn ṣe ni ofin nigba ti a ba n gbọ ipe irun, oun naa ni ki ẹni ti n gbọ o maa sọ gẹgẹ bi oluperun ṣe n sọ, nigba ti o ba sọ pe "Allāhu Akbar" ẹni ti o n gbọ naa maa sọ pe: "Allāhu Akbar", bayii ni yio ṣe maa lọ; ayaafi nigba ti oluperun ba sọ pe "ayya‘ala sọlaah", "ayya‘alal falaah", nigba naa ẹni ti n gbọ maa sọ pe: "Laa haola walā quwwata illā biLlāh".

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - si tun ṣe alaye pe dajudaju ẹni ti o ba paara nkan ti oluperun n wi ni ti imọkanga lati inu ọkan rẹ yio wọ alujanna.

Itumọ awọn gbolohun irun pipe ni: "Allāhu Akbar": Itumọ rẹ ni pe dajudaju Oun mimọ fun Un ni O tobi julọ, Oun ni o si tun gbọnngbọn ju gbogbo nkan lọ.

"Ash'adu an laa ilaaha illa Allāhu ": Itumọ rẹ ni pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu.

"Ash'adu anna Muhammadan rọsuuluLlaah": Itumọ rẹ ni pe mo n fi rinlẹ mo si tun n jẹrii pẹlu ahọn mi ati ọkan mi pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ti Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn ran an ni'ṣẹ, ti itẹle e si jẹ dandan.

"Hayya‘ala sọlaah", itumọ rẹ ni pe ẹ wa lọ ki irun, ati pe gbogbo olugbọ yio sọ pe: "Laa haola walā quwwata illā biLlāh", itumọ rẹ ni pe ko si ète kankan lati la kuro nibi awọn nkan ti maa n dena titẹle aṣẹ, kò sì tun si agbara lati ṣe e, bẹẹ ni ko si ikapa lori ikankan ninu awọn nkan wọnyii ayaafi pẹlu kongẹ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.

"Hayya‘alal falaah", itumọ rẹ ni pe ẹ wa sibi okunfa ọla, oun naa ni jijere pẹlu alujanna ati lila kuro nibi ina.

Àwọn àǹfààní

  • Ọla ti o wa fun imaa fesi fun oluperun pẹlu sisọ iru nkan ti o n sọ, ayaafi nibi hayya‘ala mejeeji (hayya‘ala solaah ati hayya‘alal falaah), nigba naa yio sọ pe: "Laa haola walā quwwata illā biLlāh".

Kà á lórí HadeethEnc.com

3 Ẹ̀ẹ̀kan

أَشْهَدُ أَنْ لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ وَحْدَهُ لَا شَرِيكَ لَهُ، وَأَنَّ مُحَمَّدًا عَبْدُهُ وَرَسُولُهُ، رَضِيتُ بِاللهِ رَبًّا وَبِمُحَمَّدٍ رَسُولًا، وَبِالْإِسْلَامِ دِينًا

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Sadu ọmọ Abi waqqoosi, ki Ọlọhun yọnu si i, lati ọdọ ojisẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Ẹni ti o ba sọ nigba ti o n gbọ oluperun pe ash-hadu an laa ilaaha illa Allāhu wahdahu laa sharika laHu, wa anna muhammadan ‘abduHu wa rosuuluhu, rodiitu bil Laahi robban wa bi muhammadin rosuulan wa bil Isilaami diina, wọn a fi ori ẹṣẹ rẹ jin in.

Muslim gba a wa Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo pe dajudaju ẹni ti o ba sọ nigba ti o n gbọ oluperun pe Ash-hadu an laa illaha illā Allāhu wahdahu laa sharika laHu" itumọ rẹ ni: Mo n fi rinlẹ wipe dajudaju ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Ọlọhun, ati pe gbogbo nkan ti wọn n sìn yatọ si i ibajẹ ni in. Wa anna muhammadan ‘abduHu wa rosuuluhu" ìtumọ rẹ ni: Dajudaju ẹru ni wọn o ki n jọsin fun un, ati pe ojiṣẹ ni ti ko ki n parọ, Rodiitu bil Laahi Robban" itumọ rẹ ni: Pẹ̀lú ijẹ Oluwa Rẹ, ati ijẹ Ọlọhun Rẹ, ati awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ, Wa bi muhammadin rosuula" itumọ rẹ ni: Pẹlu gbogbo nkan ti wọn fi ran an, ti o si mu un de etiigbọ wa, wa bil Islam" itumọ rẹ ni: Pẹlu gbogbo awọn ìdájọ́ Isilaamu bii awọn aṣẹ ati awọn nnkan ti wọn kọ̀, "Diinan” itumọ rẹ ni: Ni ti adisọkan ati itẹle, "Gufiro lahu dhanbuhu" itumọ rẹ ni: Awọn ẹṣẹ kekere.

Àwọn àǹfààní

  • Pipaara adua yii nigba ti a ba n gbọ irun pipe wa ninu awọn nkan ti maa n pa ẹṣẹ rẹ.

Kà á lórí HadeethEnc.com

4 Ẹ̀ẹ̀kan

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amru ọmọ al-‘Aas – ki Ọlọhun yọnu si i – dajudaju o gbọ ti Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n sọ pe: «Ti ẹ ba ti gbọ oluperun ki ẹ yaa maa sọ gẹgẹ bi o ṣe n sọ, lẹyin naa ki ẹ wa ṣe asalaatu fun mi, torí pé dajudaju ẹni ti o ba ṣe asalaatu kan fun mi Ọlọhun a fi ṣe mewaa fun un, lẹyin naa ki ẹ beere al-Wasiilah fun mi lọdọ Ọlọhun, ati pe dajudaju oun ni ipo kan ninu al-jannah, ti ko si lẹtọọ ayaafi fun ẹru kan ninu awọn ẹru Ọlọhun, mo si fẹ ki o jẹ emi, nitori naa ẹni ti o ba beere al-Wasiilah fun mi iṣipẹ ti di ẹtọ fun un».

Muslim gba a wa Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – juwe ẹni ti o ba gbọ oluperun lọ sibi pe ki o maa sọ tẹle e nǹkan ti o ba n wi, nitori naa yio maa sọ iru ọrọ rẹ (oluperun), yatọ si Hayya‘ala mejeeji (Hayya‘alas sọlaah ati Hayya‘alal falaah), yio sọ lẹyin mejeeji pe: Laa haola walā quwwata illā biLlāh, lẹyin naa yio ṣe asalaatu fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – lẹyin ti o ba pari irun pipe, torí pé dajudaju ẹni ti o ba ṣe asalaatu kan Ọlọhun a titori rẹ ṣe asalaatu mẹwaa fun un, ati pe itumọ asalaatu Ọlọhun fun ẹru Rẹ ni: Ẹyin Rẹ fun ẹru Rẹ lọdọ awọn malaaika.

Lẹyin naa ni o wa paṣẹ pẹlu bibi Ọlọhun leere al-Wasiilah fun oun– ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ati pe oun (al-Wasiilah) naa ni ipo kan ninu al-jannah, ati pe oun lo ga jùlọ ninu rẹ, ko si lẹtọọ bẹẹ ni ko rọrun ayaafi fun ọkan ninu gbogbo awọn ẹru Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, ti mo si n tanmọọn ki n jẹ ẹni naa, ati pe o sọ iyẹn – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ni ti itẹriba; torí pé dajudaju ti ipo giga yẹn o ba nii wa ayaafi fun ẹnikan, ko wa si ẹni ti o lẹ jẹ ẹnikan yẹn ayaafi oun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -; torí pé oun ni o lọla julọ ninu awọn ẹda.

Lẹyin naa o – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ṣe alaye pe dajudaju ẹni ti o ba ṣe adua al-Wasiilah fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – iṣipẹ rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – a jẹ tiẹ.

Àwọn àǹfààní

  • Ṣiṣenilojukokoro lori ijẹpe oluperun (sisọ gẹgẹ bi oluperun ṣe sọ).
  • Ọla ti n bẹ fun ṣiṣe asalaatu fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – lẹyin ijẹpe oluperun (sisọ gẹgẹ bi oluperun ṣe sọ).
  • Ṣiṣenilojukokoro lori bibeere al-Wasiilah fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – lẹyin ṣiṣe asalaatu fun un.
  • Alaye itumọ al-Wasiilah, ati giga ipo rẹ, latari pe ko lẹtọọ ayaafi fun ẹru kan.
  • Alaye ọla Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – latari pe wọn ṣe ipo ti o ga yẹn ni ẹsa fun un.
  • Ẹni ti o ba beere al-Wasiilah ni ọwọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- fún Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – iṣipẹ rẹ (Anabi) ti di ẹtọ fun un.
  • Alaye itẹriba rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – latari pe o wa lati ọdọ awọn ijọ rẹ ki wọn ṣe adua fun un pẹlu ipo yẹn, toun ti pe dajudaju ti ẹ naa ni yio jẹ.
  • Gbigbaaye ọla Ọlọhun ati ikẹ Rẹ, nitori naa iṣẹ rere kan ilọpo mẹwaa iru rẹ ni ẹsan rẹ.

Kà á lórí HadeethEnc.com

Àwọn ìbéèrè

Kí ló wà lórí ojú-ìwé yìí?

Adua lẹ́yìn ìpè ìrun: ọ̀kọ̀ọ̀kan ní èdè Lárúbáwá, pẹ̀lú ìtumọ̀ rẹ̀, hadiisi tí ó ti wá, ipò rẹ̀ àti àlàyé.

Níbo ni àwọn ìtumọ̀ ti wá?

Láti HadeethEnc.com, Ìwé Ìmọ̀ Àwọn Hadiisi Ànábì Tí A Túmọ̀. A ń fi hadiisi kọ̀ọ̀kan hàn gẹ́lẹ́ bí wọ́n ṣe tẹ̀ ẹ́ jáde, pẹ̀lú orísun àti ipò rẹ̀, àti ìjápọ̀ sí ojúlówó rẹ̀.

Ṣé mo lè gba ìrántí ojoojúmọ́?

Bẹ́ẹ̀ni. Ohun èlò Qabas ọ̀fẹ́ fún Android máa ń rán ọ létí zikiri òwúrọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ lójoojúmọ́, ó sì ní ẹ̀rọ ìkà kan náà.