Adua wíwọ àti jíjáde ní mọ́ṣáláṣí

Àwọn ọ̀rọ̀ tí a ń sọ ní ẹnu ọ̀nà mọ́ṣáláṣí, nígbà tí a bá ń wọlé àti nígbà tí a bá ń jáde.

1 Ẹ̀ẹ̀kan

اللَّهُمَّ افْتَحْ لِي أَبْوَابَ رَحْمَتِكَ
اللَّهُمَّ إِنِّي أَسْأَلُكَ مِنْ فَضْلِكَ

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Abu Humayd tabi lati ọdọ Abu Usayd, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ti ẹnikẹni ninu yin ba fẹ wọ masalaasi ki o yaa sọ pe: Allāhummo iftah li abwaaba rahmotika, ti o ba si tun jade ki o sọ pe: Allāhummo inni as’aluka min fadlika».

Muslim gba a wa Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – tọka awọn ijọ rẹ sibi adua ti wọn maa ṣe nigba ti wọn ba fẹ wọ masalaasi: (Allāhummo iftah li abwaaba rahmotika), nigba naa ni yio beere lọwọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ki O ṣe ni irọrun fun un awọn okunfa ikẹ Rẹ, ati pe ti o ba fẹ jade ki o sọ pe: (Allāhummo inni as’aluka min fadlika), nigba naa yio waa bẹ Ọlọhun ninu ọla Rẹ ati alekun daadaa Rẹ ninu jijẹ-mimu halaali.

Àwọn àǹfààní

  • A fẹ ki a ṣe adua yii nigba ti a ba fẹ wọ masalaasi ati nigba ti a ba fẹ jade kuro nibẹ.
  • Sisẹsa didarukọ ikẹ nigba ti a ba fẹ wọle, ati ọla nigba ti a ba fẹ jade: Dajudaju ẹni ti o n wọle ko airoju pẹlu nkan ti yio sun un mọ Ọlọhun ati alujanna, nitori naa o ṣe deedee ki o darukọ ikẹ, ati pe nigba ti o ba jade yio kaakiri ori ilẹ lati wa ọla Ọlọhun ninu jijẹ-mimu lọ, nitori naa o ṣe deedee ki o darukọ ọla.
  • Awọn asikiri yii a maa n sọ wọn nigba ti a ba gbero lati wọ masalaasi, ati nigba ti a ba gbero lati jade kúrò nibẹ.

Kà á lórí HadeethEnc.com

Àwọn ìbéèrè

Kí ló wà lórí ojú-ìwé yìí?

Adua mọ́ṣáláṣí: ọ̀kọ̀ọ̀kan ní èdè Lárúbáwá, pẹ̀lú ìtumọ̀ rẹ̀, hadiisi tí ó ti wá, ipò rẹ̀ àti àlàyé.

Níbo ni àwọn ìtumọ̀ ti wá?

Láti HadeethEnc.com, Ìwé Ìmọ̀ Àwọn Hadiisi Ànábì Tí A Túmọ̀. A ń fi hadiisi kọ̀ọ̀kan hàn gẹ́lẹ́ bí wọ́n ṣe tẹ̀ ẹ́ jáde, pẹ̀lú orísun àti ipò rẹ̀, àti ìjápọ̀ sí ojúlówó rẹ̀.

Ṣé mo lè gba ìrántí ojoojúmọ́?

Bẹ́ẹ̀ni. Ohun èlò Qabas ọ̀fẹ́ fún Android máa ń rán ọ létí zikiri òwúrọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ lójoojúmọ́, ó sì ní ẹ̀rọ ìkà kan náà.