Adua nínú ìrun: ìbẹ̀rẹ̀, rukuu, sujuud àti tashahhud

Àwọn adua tí Ànábì ﷺ máa ń ṣe nínú ìrun, láti kábíírà ìbẹ̀rẹ̀ títí dé sálámà.

1 Ẹ̀ẹ̀kan

اللهُمَّ بَاعِدْ بَيْنِي وَبَيْنَ خَطَايَايَ كَمَا بَاعَدْتَ بَيْنَ الْمَشْرِقِ وَالْمَغْرِبِ، اللهُمَّ نَقِّنِي مِنْ خَطَايَايَ كَمَا يُنَقَّى الثَّوْبُ الْأَبْيَضُ مِنَ الدَّنَسِ، اللهُمَّ اغْسِلْنِي مِنْ خَطَايَايَ بِالثَّلْجِ وَالْمَاءِ وَالْبَرَدِ

Ìtumọ̀ àti orísun

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jẹ ẹni ti o ṣe pe, ti o ba ti kabara nibi irun, o maa n dakẹ fun igba díẹ̀ ṣíwájú ki o to ka Fatiha, mo wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun mo fi baba mi ati iya mi ṣe ìràpadà fún ọ, njẹ o ri idakẹ rẹ laaarin kikabara ati kika Fatiha, ki ni nnkan ti o maa n sọ? O sọ pe "mo maa n sọ pe: Al-Lahumma Bā`id Baynī Wa Bayna Khaţāyāya Kamā Bā`adta Bayna Al-Mashriqi Wa Al-Maghribi Al-Lahumma Naqqinī Min Khaţāyāya Kamā Yunaqqá Ath-Thawbu 'Illābyađu Mina Ad-Danasi Al-Lahumma Aghsilnī Min Khaţāyāya Bith-Thalji Wa Al-Mā'i Wa Al-Barad".

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba ti kabara, o maa n dakẹ ni idakẹ díẹ̀ ṣíwájú ki o to ka Fatiha, o maa n bẹ̀rẹ̀ irun rẹ nibẹ pẹlu awọn adura kan, ninu eyi ti o wa ninu awọn adura yii ni ọrọ rẹ pé: "Al-Lahumma Bā`id Baynī Wa Bayna Khaţāyāya Kamā Bā`adta Bayna Al-Mashriqi Wa Al-Maghribi Al-Lahumma Naqqinī Min Khaţāyāya Kamā Yunaqqá Ath-Thawbu 'Illābyađu Mina Ad-Danasi Al-Lahumma Aghsilnī Min Khaţāyāya Bith-Thalji Wa Al-Mā'i Wa Al-Barad", O maa n bẹ Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- lati gbe awọn àṣìṣe jìnnà si oun ki oun ma ko si i, ni igbejinna kan ti ipadepọ ko lee ṣẹlẹ pẹlu rẹ, gẹgẹ bi ko ṣe le si ìpàdépọ̀ laaarin ibuyọ oorun ati ibuwọ oorun láéláé, ti oun ba wa ko si i, ki O fọ oun mọ kuro nibẹ ki O mu u kúrò bi wọn ṣe maa n mu ìdọ̀tí kuro lara aṣọ funfun, pe ki O fọ oun mọ kuro nibi awọn àṣìṣe rẹ ki O bu tutu si eyi ti o n jo ti o si gbóná nibẹ, pẹlu awọn nǹkan ti n mọ́ nǹkan ti o tutu yìí; omi ati yinyin.

Àwọn àǹfààní

  • Kika adura ìṣírun ni jẹẹjẹ koda ki irun jẹ eyi ti a maa n ki soke.
  • Ojúkòkòrò awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- lori mimọ awọn isẹsi ojiṣẹ - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi awọn lílọ bibọ rẹ ati iwalojukan rẹ.
  • Awọn agbekalẹ miiran wa fun adura iṣirun, ati pe eyi ti o daa julọ ni pe ki ọmọniyan tọ ipasẹ awọn adura iṣirun ti o wa ti o si fi ẹsẹ rinlẹ lati ọdọ rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ki o si mu eyi wa ni ẹẹkan, ki o mu òmíràn wa nigba mii.

Kà á lórí HadeethEnc.com

2 Ẹ̀ẹ̀kan

سَمِعَ اللهُ لِمَنْ حَمِدَهُ، اللَّهُمَّ رَبَّنَا لَكَ الْحَمْدُ، مِلْءَ السَّمَاوَاتِ وَمِلْءَ الْأَرْضِ وَمِلْءَ مَا شِئْتَ مِنْ شَيْءٍ بَعْدُ

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ ọmọ Abu Aofaa- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba gbe ẹyin rẹ dide lati rukuu, o maa sọ pé: “Sami’alloohu liman hamidaHu, Allahumo Robbanaa wa laKal hamdu, milhas samoowaati wa milhal ardi wa milha maa shi-ita min shaihin bahdu”.

Muslim gba a wa Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti gbe ẹyin rẹ dide lati rukuu ninu irun, o maa n sọ pe: “Sami’alloohu liman hamidaHu”, o n túmọ̀ si: Dajudaju ẹni ti o ba dupẹ fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa da a lohun, yio si gba ọpẹ rẹ ati ẹyin rẹ, yio si san lẹsan, lẹyin naa, o maa dupẹ fun Ọlọhun pẹlu sisọ pe: “Allahumo Robbanaa wa laKal hamdu, milhas samoowaati wa milhal ardi wa milha maa shi-ita min shaihin bahdu”, ni ọpẹ kan ti o maa kun awọn sanmọ ati awọn ilẹ ati nnkan ti o n bẹ laaarin mejeeji, ti o si n kun nnkan ti Ọlọhun ba fẹ ninu nnkan kan.

Àwọn àǹfààní

  • Ṣíṣe alaye nnkan ti a fẹ fun olukirun lati maa sọ ti o ba gbe ori rẹ dide lati rukuu.
  • Ṣíṣe nínà tọ̀ọ̀ ati ifarabalẹ lofin lẹyin gbigbe ori kuro ni rukuu; nitori pe ko rọrun lati maa sọ iranti yii afi ti o ba nà tọ̀ọ̀ ti o si fi ara balẹ.
  • Wọn ṣe asikiri yii ni nǹkan ti o ba ṣẹria mu ninu gbogbo ìrun, bóyá o jẹ ọranyan ni tabi naafila.

Kà á lórí HadeethEnc.com

3 Ẹ̀ẹ̀kan

اللَّهمَّ اغْفِرْ لي، وارْحَمْنِي، وعافِني، واهْدِني، وارزقْنِي

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ ọmọ Abbās – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- pé: Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n sọ laarin iforikanlẹ mejeeji pe: «Allāhummọ igfir li, warhamnī, wa ‘āfinī, wahdinī, warzuqnī».

Abu Daud ati Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa Ipò: O daa pẹlu awọn ẹri rẹ

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ṣe adua laarin iforikanlẹ mejeeji nibi irun rẹ pẹlu awọn adua máàrún yii ti Musulumi ni bukaata ti o tobi si i, ti o si tun ko oore ayé àti ti ọjọ ikẹhin sinu, bii wiwa aforijin ati idaabobo awọn ẹṣẹ ati ṣiṣe amojukuro nibẹ, ati pípé ikẹ, ati lila kuro nibi awọn iruju ati awọn adun ati awọn aisan ati idakọlẹ, ati ibeere imọna lọdọ Ọlọhun sibi ododo pẹlu ifẹsẹmulẹ lori rẹ, ati níní ìgbàgbọ́ àti imọ àti iṣẹ oloore, ati níní dukia halaali ti o mọ.

Àwọn àǹfààní

  • Ṣiṣe adua yii lofin nibi ijokoo ti o wa laarin iforikanlẹ mejeeji.
  • Ọla ti n bẹ fun àwọn adua yii latari nkan ti o ko sinu ni oore ayé àti ọjọ ìkẹhìn.

Kà á lórí HadeethEnc.com

4 Ẹ̀ẹ̀kan

اللهُمَّ أَعُوذُ بِرِضَاكَ مِنْ سَخَطِكَ، وَبِمُعَافَاتِكَ مِنْ عُقُوبَتِكَ، وَأَعُوذُ بِكَ مِنْكَ لَا أُحْصِي ثَنَاءً عَلَيْكَ أَنْتَ كَمَا أَثْنَيْتَ عَلَى نَفْسِكَ

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Aishah - ki Ọlọhun bá wa yọnu si i - o sọ bayi pe: Mo ṣafẹku ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) lori ibusun loru ọjọ kan, mo wa nfi ọwọ wa a kiri bẹẹni ọwọ mi kan inu atẹlẹsẹ rẹ nigbati o wa ni iforikanlẹ, ti o gbe gigisẹ rẹ mejeeji sí oke, ti nsọ bayi ninu adura rẹ pe: "irẹ Ọlọhun mo sa di ìyọnu Rẹ kuro nibi ibinu Rẹ, mo si sa di amojukuro Rẹ kuro ni bi ijẹ níyà Rẹ". Mo tun sa di irẹ Ọlọhun pẹlu araarẹ, mi o le yin ọ tán gẹlẹ bi o ṣe yin ara Rẹ.

Muslim gba a wa Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Aishah - ki Ọlọhun bá wa yọnu si i - o sọ bayi pe: mo sun lẹgbẹ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a), mo ṣe afẹku rẹ ni oru (mi o ri), mo wa fi ọwọ mi woo ni ààyè ti o ma ti nkirun ninu yàrá, bayi ni mo kan lojiji pe o nkirun lọwọ ti gigisẹ rẹ mejeeji si wa ni iduro, bẹẹ sì ni o nsọ bayi pe:

(mo nwa isọ) mo nṣe atẹgun sọdọ Rẹ (pẹlu ìyọnu Rẹ kuro nibi ibinu Rẹ) sí mi tabi sí awọn ijọ mi, (ati) pe mo nwa isọra (pẹlu amojukuro Rẹ) ati amojukuro re ti o pọ (kuro nibi ijẹniya Rẹ), (mo wa idaabobo lọdọ Rẹ pẹlu araarẹ) ati pẹlu awọn iroyin rirẹwa Rẹ lọdọ awọn iroyin titobi Rẹ, nigbati o jasipe ẹnikan ò lee ṣọ ni lọdọ Rẹ àyaàfi ìwọ fún rara Rẹ, kò sibi aa salọ fún akoyọ, bẹẹ sì ni kò sibi ti a le sadi lati sa fún Ọlọhun ayaafi ki a sadi Ọlọhun, (Mi o le ṣe onka ẹyin fún irẹ Ọlọhun), mi o nikapa, mi o sì lè dé òpin ati onka lati ka gbogbo idẹra Rẹ tan nitori ikagara mi, bẹẹ ni mi o le ka daada Rẹ tan gẹgẹbi O ṣe lẹtọ si i, koda bi mo ba ṣe igbiyanju ati akitiyan láti ṣe bẹẹ, (gẹgẹ bí Irẹ Ọlọhun ṣe ṣe ẹyìn fún ara Rẹ) Iwọ ni O ṣe ẹyìn fún Pàápàá ara Rẹ, ẹyin ti o ba ọ mu, taani ẹni náà tí o ni ikapa lati mu ẹyin Rẹ wá ní bo ṣe yẹ?!

Àwọn àǹfààní

  • Fifẹ ki a se awọn adua yii nibi iforikanlẹ
  • Meirak sọ bayi pe: ninu ọkan ninu awọn ẹgbawa An-Nasaaiy: Anọbi a maa ṣe adua yi ti o ba pari irun rẹ, ti o si fi ẹgbẹ le lẹ láti sun.
  • Fifẹ ki a se ẹyìn fún Ọlọhun pẹlu awọn iroyin Rẹ ati imáa pe pẹlu awọn orukọ Rẹ ti o f'ẹsẹ rinlẹ nínú Al-kurani ati Sunnah Anọbi.
  • Igbe Ọlọhun Adẹda ga wà nibẹ nibi itẹriba ati ni iforikanlẹ.
  • O lẹtọ lati wá isọra (ìdáàbòbò) pẹlu awọn iroyin Ọlọhun, bẹẹ ni o lẹtọ lati wá isọra pẹlu pàápàá Rẹ, mimọ fún Ọlọhun ti O gaju lọ.
  • Al-Khọtọọbi sọ bayi pe: itumọ ti o lẹ̀ wa ninu ọrọ yii, ohun náà ni pe dájúdájú o ti wá isọra lọdọ Ọlọhun pe ko ṣọ ohun pẹlu ìyọnu Rẹ nibi ibinu Rẹ ati pẹlu amojukuro Rẹ nibi ijẹni-niya Rẹ, ìyọnu ati ibinu ọrọ ati ida keji niwọn (orogun meji niwọn), bẹẹ náà ni amojukuro ati ifi ọwọ iya muni, nigbati o de ibi idarukọ nkan ti ko ni idakeji Oun náà ni Allah (Ọlọhun) mimọ ni fun Ọba ti O ga jù, O wa isọra pẹlu Rẹ lọdọ ara Rẹ, ti kii se ọdọ ẹlòmíràn, ìtumọ eléyun nipe: iwa aforijin nibi aseeto ojúṣe ọranyan o wa ninu ẹto ìjọsìn fun Un ati ifi ẹyìn fun Un. Gbólóhùn rẹ to sọ pe: "mi o lẹ se onka ẹyin fún Ẹ: ìtumọ rẹ ni pé: mi o ni ikapa lati mu dé ogongo ẹyin Rẹ.

Kà á lórí HadeethEnc.com

5 Ẹ̀ẹ̀kan

اللَّهُمَّ صَلِّ عَلَى مُحَمَّدٍ وَعَلَى آلِ مُحَمَّدٍ، كَمَا صَلَّيْتَ عَلَى آلِ إِبْرَاهِيمَ، إِنَّكَ حَمِيدٌ مَجِيدٌ، اللَّهُمَّ بَارِكْ عَلَى مُحَمَّدٍ وَعَلَى آلِ مُحَمَّدٍ، كَمَا بَارَكْتَ عَلَى آلِ إِبْرَاهِيمَ، إِنَّكَ حَمِيدٌ مَجِيدٌ

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Abdur Rahman ọmọ Abu Laila, o sọ pe: Ka'b ọmọ 'Ujrah pade mi, o sọ pe: Njẹ mi ko nii ta ẹ lọrẹ ọrẹ kan? Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jade si wa, a sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a ti kọ bi a ṣe maa salamọ si ẹ, bawo ni a ṣe maa ṣe asalatu fun ẹ? o sọ pe: "Ẹ maa sọ pe: Allahumo solli 'alaa Muhammadin wa 'alaa aali Muhammadin, ka maa sollaita 'alaa aali Ibrahim, innaka Hamiidun Majeedun, Allahumo baarik 'alaa Muhammadin wa 'alaa aali Muhammadin, ka maa baarokta 'alaa aali Ibrahim, innaka Hamiidun Majeedun".

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Àwọn saabe beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa bi wọn ṣe maa ṣe asalatu fun un? Lẹyin mimọ bi wọn ṣe maa salamọ fun un nibi ataya: "As salaamu alayka ayyuhan nabiyyu wa rahmatullah wa barokaatuhu...."? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun wọn bi wọn ṣe maa ṣe asalatu fun un, ìtumọ̀ rẹ ni pe: "Allahumo solli 'alaa Muhammadin wa 'alaa aali Muhammadin" O túmọ̀ si pe: Ṣe ẹyin fun un pẹlu iranti ti o rẹwa ni ọdọ àwọn malaika, ati fun awọn olutẹle rẹ ninu ẹsin rẹ, ati awọn olugbagbọ ninu awọn alasunmọ rẹ. "ka maa sollaita 'alaa aali Ibrahim" Gẹgẹ bi o ṣe da ọla lori awọn ara ile Ibrahim- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- awọn ni Ibrahim ati Isma'il ati Ishaq ati awọn arọmọdọmọ wọn ati awọn olutẹle wọn ti wọn jẹ olugbagbọ, nitori naa, so ọla Rẹ mọ Muhammad- kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-. "Innaka Hamiidun Majeedun" O n túmọ̀ si pe: Ọba ti a n gbe ẹyin fun nibi paapaa Rẹ ati awọn iroyin Rẹ ati awọn iṣẹ Rẹ, Ọba ti O gbòòrò nibi titobi Rẹ ati àṣẹ Rẹ ati ọrẹ Rẹ. "Allahumo baarik 'alaa Muhammadin wa 'alaa aali Muhammadin, ka maa baarokta 'alaa aali Ibrahim" O n túmọ̀ si pe: Fun un ninu oore ati apọn-ọnle eyi ti o tobi julọ ninu rẹ, ki o si ṣe alekun rẹ ki o si fi i rinlẹ.

Àwọn àǹfààní

  • Awọn ẹni ìṣáájú wọn maa n fun ara wọn ni ẹbun àwọn ọ̀rọ̀ imọ.
  • Jijẹ dandan ṣiṣe asalatu fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi ataya igbẹyin nibi irun.
  • Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi titọrọ ikẹ ati ọla fun un mọ awọn saabe rẹ.
  • Ọna yii ni o pe julọ ninu awọn ọna ti o wa nibi ṣíṣe asalatu fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-.

Kà á lórí HadeethEnc.com

6 Ẹ̀ẹ̀kan

اللَّهُمَّ إِنِّي أَعُوذُ بِكَ مِنْ عَذَابِ القَبْرِ، وَمِنْ عَذَابِ النَّارِ، وَمِنْ فِتْنَةِ المَحْيَا وَالمَمَاتِ، وَمِنْ فِتْنَةِ المَسِيحِ الدَّجَّالِ

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti maa n ṣe adua ti o si maa n sọ pe: «Irẹ Ọlọhun dajudaju emi wa iṣọra pẹlu Rẹ kuro nibi iya saare, ati nibi iya ina, ati nibi fitina iṣẹmi ati iku, ati nibi fitina al-Masiihu ad-Dajjāl». Nibi ti gbolohun ti Muslim: «Ti ẹnikẹni ninu yin ba ti pari ataaya igbẹyin, ki o yaa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi awọn nkan mẹẹrin: Nibi iya jahannamọ, ati nibi iya saare, ati nini fitina iṣẹmi ati iku, ati nibi aburu al-Masiihu ad-Dajjāl».

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti maa n wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi nkan mẹẹrin, lẹyin ataaya igbẹyin ati siwaju salamọ ninu irun, o si tun pa wa laṣẹ ki a maa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibẹ,

Ikinni: Nibi iya saare.

Ẹẹkeji: Nibi iya ina ati pe ìyẹn ni ọjọ igbedide.

Ẹẹkẹta: Nibi fitina iṣẹmi bi awọn adun aye ti o jẹ eewọ ati awọn iruju ti maa n sọni nu, ati nibi fitina iku, ìyẹn ni àsìkò pipọka iku, bii yiyẹ kuro ninu Isilaamu tabi Sunnah, tabi fitina saare gẹgẹ bii ibeere awọn malaika mejeeji.

Ẹẹkẹrin: Fitina al-Masiihu ad-Dajjāl eleyii ti yio jade ni igbẹyin aye, Ọlọhun yio fi i dan awọn ẹru Rẹ wo; o wa darukọ rẹ lọ́tọ̀ latari titobi fitina rẹ ati isọninu rẹ.

Àwọn àǹfààní

  • Iwa iṣọra yii ninu awọn adua ti o pataki ti o si kun fọfọ ni, latari pe o ko iwa iṣọra kuro nibi awọn aburu aye ati alukiyaamọ sinu.
  • Ririnlẹ iya saare ati pe dajudaju ododo ni i.
  • Ewu awọn fitina ati pataki wiwa iranlọwọ pẹlu Ọlọhun ati ṣiṣe adua fun lila kuro ninu rẹ (fitina).
  • Fifi jijade dajjāl ati titobi fitina rẹ rinlẹ.
  • Ṣiṣe adua yii ni sunnah lẹyin ataaya igbẹyin.
  • Ṣiṣe adua ṣiṣe ni sunnah lẹyin iṣẹ oloore.

Kà á lórí HadeethEnc.com

7 Ẹ̀ẹ̀kan

Ìtumọ̀ àti orísun

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Iṣesi ti ẹrú maa n sunmọ Oluwa rẹ ju nibẹ ni ìgbà ti o ba wa ni iforikanlẹ, ki ẹ yaa maa ṣe adua ni ọ̀pọ̀lọpọ̀”.

Muslim gba a wa Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe iṣesi ti ẹrú maa n sunmọ Oluwa rẹ ju nibẹ ni ìgbà ti o ba wa ni iforikanlẹ; ìyẹn ni pe ẹni ti n kirun maa fi ibi ti o ga ju ti o si niyi ju ninu ara rẹ lé ilẹ̀ ni ti ìtẹríba ati irẹlẹ fun Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn, ti o si wa ni iforikanlẹ.

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti wa pàṣẹ ṣíṣe adua ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni iforikanlẹ, o maa wa kójọ ninu ìyẹn irẹlẹ fun Ọlọhun pẹlu ọ̀rọ̀ ati ìṣe.

Àwọn àǹfààní

  • Itẹle àṣẹ Ọlọhun maa n le ẹrú kún ni isunmọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.
  • A fẹ́ ki a maa ṣe adua ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni iforikanlẹ; torí pé ó wa ninu awọn ààyè gbigba adua.

Kà á lórí HadeethEnc.com

Àwọn ìbéèrè

Kí ló wà lórí ojú-ìwé yìí?

Adua nínú ìrun: ọ̀kọ̀ọ̀kan ní èdè Lárúbáwá, pẹ̀lú ìtumọ̀ rẹ̀, hadiisi tí ó ti wá, ipò rẹ̀ àti àlàyé.

Níbo ni àwọn ìtumọ̀ ti wá?

Láti HadeethEnc.com, Ìwé Ìmọ̀ Àwọn Hadiisi Ànábì Tí A Túmọ̀. A ń fi hadiisi kọ̀ọ̀kan hàn gẹ́lẹ́ bí wọ́n ṣe tẹ̀ ẹ́ jáde, pẹ̀lú orísun àti ipò rẹ̀, àti ìjápọ̀ sí ojúlówó rẹ̀.

Ṣé mo lè gba ìrántí ojoojúmọ́?

Bẹ́ẹ̀ni. Ohun èlò Qabas ọ̀fẹ́ fún Android máa ń rán ọ létí zikiri òwúrọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ lójoojúmọ́, ó sì ní ẹ̀rọ ìkà kan náà.