Zikiri lẹ́yìn ìrun (lẹ́yìn gbogbo ìrun)

Ìrántí Ọlọ́hun tí a ń ṣe lẹ́yìn àwọn ìrun ọ̀ranyàn, lẹ́yìn tí a bá ti sálámà.

1 Ẹ̀ẹ̀kan

أَسْتَغْفِرُ اللَّهَ (٣)، اللَّهُمَّ أَنْتَ السَّلَامُ وَمِنْكَ السَّلَامُ، تَبَارَكْتَ يَا ذَا الْجَلَالِ وَالْإِكْرَامِ

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Thaoban- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti pari irun o maa n wa aforijin lẹẹmẹta, o maa sọ pé: “Allahumo Anta-s- Salaam wa minka-s- Salaam, Tabaarakta Zal Jalaali wal Ikroom”, Al-Waleed sọ pé: Mo sọ fun Al-‘Aozaa’iy: Bawo ni a ṣe maa n wa àforíjìn? O sọ pe: Waa sọ pe: Astagfirullah, Astagfirullah.

Muslim gba a wa Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti pari irun o maa n sọ pe: Astagfirullah, Astagfirullah, Astagfirullah.

Lẹyin naa o maa gbe Oluwa rẹ tobi pẹlu sisọ pé: “Allahumo Anta-s- Salaam wa minka-s- Salaam, Tabaarakta Zal Jalaali wal Ikrọọm” Ọlọhun ni Ọba Àlàáfíà ti O pe nibi awọn iroyin Rẹ, ti a fọmọ kuro nibi gbogbo aleebu ati adinku, ti o si n wa lílà lọdọ Rẹ kuro nibi awọn aburu aye ati ọrun ti ko ki n ṣe lọdọ ẹni ti o yatọ si I, Oun- mimọ ni fun Un- ni daadaa Rẹ pọ ni aye ati ọrun, Ẹni ti O ni titobi ati daadaa.

Àwọn àǹfààní

  • Ṣíṣe wiwa àforíjìn ni nnkan ti a fẹ lẹyin irun ati didunni mọ ọn.
  • Ṣíṣe wiwa àforíjìn ni nnkan ti a fẹ lati wa pipe adinku to wa nibi ijọsin ati lati dí àáyẹ fun itẹle ati aṣeeto to wa nibẹ.

Kà á lórí HadeethEnc.com

2 Ẹ̀ẹ̀kan

لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ وَحْدَهُ لَا شَرِيكَ لَهُ، لَهُ الْمُلْكُ وَلَهُ الْحَمْدُ، وَهُوَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Warrood olukọwe Al-Mugiiroh ọmọ Shu’bah, o sọ pe: Al-Mugiiroh ọmọ Shu’bah pe àpèkọ fun mi ninu iwe kan si Mu’aawiyah pe: Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-

maa n sọ lẹyin gbogbo irun ọran-anyan pe: “Laa ilaaha illallohu wahdaHu laa shariika laHu, laHul mulku wa laHul hamdu, waHuha ‘ala qulli shai’in Qodeer, Allahumo laa maania limaa ‘atoita, wa laa mu’tiya limaa mana’ta, wa laa yanfa’u dhal jaddi minKal jaddu”.

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ lẹyin gbogbo irun ọran-anyan pe: “Laa ilaaha illallohu wahdaHu laa shariika laHu, laHul mulku wa laHul hamdu, waHuha ‘ala qulli shai’in Qodeer, Allahumo laa maania limaa ‘ah'toita, wa laa mu’tiya limaa mana’ta, wa laa yanfa’u dhal jaddi minKal jaddu”.

O n túmọ̀ si pe: Mo n fi rinlẹ mo si n gba gbolohun imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo “Laa ilaaha illallohu” wọlé, ati pe ijọsin ododo mo n fi i rinlẹ fun Ọlọhun, mo si n kọ ọ fun ẹni ti o yatọ si i, ati pe ko si ẹni ti a le maa jọsin fun pẹlu ẹtọ afi Allahu, mo si n fi ọla gangan ti o pe rinlẹ fun Ọlọhun, ati gbogbo ọpẹ awọn ara inu sanmọ ati ilẹ jẹ ẹtọ fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- nigba ti O ṣe pe Onikapa ni lori gbogbo nnkan, ati pe nnkan ti Ọlọhun ba kadara rẹ ninu fifun ati kikọ, ko si oludapada kankan fun un, lọdọ Rẹ, ọrọ ko lee ṣe ọlọrọ ni anfaani, bi ko ṣe pe iṣẹ rere ni yoo ṣe e ni anfaani.

Àwọn àǹfààní

  • Ṣíṣe iranti yii ni nnkan ti a fẹ lẹyin awọn irun fun nnkan ti o ko sinu ninu awọn gbolohun imu Ọlọhun lọkan ṣoṣo ati ọpẹ.
  • Yiyara si ṣíṣe àwọn sunnah, ati fifọn wọn ka.

Kà á lórí HadeethEnc.com

3 Ẹ̀ẹ̀kan

لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ وَحْدَهُ لَا شَرِيكَ لَهُ، لَهُ الْمُلْكُ وَلَهُ الْحَمْدُ وَهُوَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ، لَا حَوْلَ وَلَا قُوَّةَ إِلَّا بِاللهِ، لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ، ‌وَلَا ‌نَعْبُدُ ‌إِلَّا إِيَّاهُ، لَهُ النِّعْمَةُ وَلَهُ الْفَضْلُ وَلَهُ الثَّنَاءُ الْحَسَنُ، لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ وَلَوْ كَرِهَ الْكَافِرُونَ

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Abu Zubayr, o sọ pe: Ibnu Zubayr jẹ ẹniti o maa n sọ ni ẹyin ìrun kọọkan nigba ti o ba salamọ pe: “Laa ilaaha illa Allāhu wahdahu laa sharīka lahu, lahul mulku wa lahul hamdu wa huwa ala kulli shay’in qodīr, laa haola walā quwwata illā biLlāh, lā ilāha illā Allāhu, wa lā na‘budu illā iyyāhu, lahu ni‘matu wa lahul fadlu wa lahuu thanāhul hasan, lā ilāha illā Allāhu mukhlisiina lahuu dīna wa lao karihal kāfirūna”, o wa sọ pe: «Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹniti maa n fi wọn ṣe gbólóhùn ìmú-Ọlọ́hun-lọ́kan ni ẹyin gbogbo irun kọọkan».

Muslim gba a wa Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹniti maa n fi asikiri nla yii ṣe gbólóhùn ìmú-Ọlọ́hun-lọ́kan ni ẹyin ti o ba salamọ ni gbogbo irun ọran-anyan, itumọ rẹ si ni pe:

“Lā ilāha illā Allāhu”: Ìyẹn ni pé ko si ẹni ti a maa jọ́sìn fun pẹ̀lú ẹ̀tọ́ ayaafi Allāhu.

“Wahdahu lā sharīka lahu” ìyẹn ni pé: Dajudaju ko si akẹgbẹ fun un nibi ìní-ẹ̀tọ́ si ijọsin Rẹ, ati ijẹ Oluwa Rẹ, ati awọn orukọ Rẹ, ati awọn iroyin Rẹ.

“Lahul mulku” ìyẹn ni pé: TiRẹ ni ìjọba ti ko ni ààlà ti o kárí, ti o gbòòrò, ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ati ohun ti n bẹ ni àárín méjèèjì.

“Wa lahul hamdu” ìyẹn ni pé: Oun ni Ẹnití a n royin pẹlu pipe ti ko ni ààlà, Ẹni tí a n yin pẹlu pipe ni ti ifẹ ati gbigbe tobi lori gbogbo ìṣesí, nigba idunnu, ati nigba inira.

“Wa huwa ‘alā kulli shay’in qodīr”: Ikapa Rẹ pe ni gbogbo ọna, nnkankan o si da A ni agara ri, alamọri kankan o si soro lati ṣe fun Un ninu awọn alamọri.

“Lā haola walā quwwata illā biLlāh” ìyẹn ni pé: Ko si iyipada kuro nibi ìṣesí kan sí iṣesi miiran, ati kuro nibi ṣiṣẹ Ọlọhun lọ sí titẹle àṣẹ Rẹ, ko si si agbara kankan ayaafi pẹlu Allāhu, Oun ni Olùrànlọ́wọ́, Oun si ni a maa n gbára lé.

“Lā ilāha illā Allāhu, wa lā na‘budu illā iyyāhu”: O jẹ ìkànnípá fun itumọ ìní-ẹ̀tọ́ si ijọsin ati íhánnà ẹbọ (mimu orogun mọ Ọlọhun), ati pe ko si ẹnití o lẹtọọ si ijọsin ayaafi Oun.

“Lahu ni‘motu wa lahul fadlu”: Oun ni O n ṣẹda awọn idẹkun ti O ni ikapa rẹ, ti O si maa n fi i da ọla lori ẹnití o ba wu U ninu awọn ẹru Rẹ.

“Wa lahu thanāhul hasan”: Lórí pàápàá Rẹ ati awọn iroyin Rẹ ati awọn iṣẹ Rẹ ati awọn idẹra Rẹ, ati lori gbogbo ìṣesí.

“Lā ilāha illā Allāhu, mukhlisiina lahu dīna”: Ìyẹn ni pe ni ẹni ti wọn a maa mu Un ni Ọkan ṣoṣo laisi ṣekarini ati ṣekagbọni nibi titẹle Ọlọhun.

“Wa lao karihal kāfirūna”, ìyẹn ni pe: Ni ẹni tí wọn fi ẹsẹ rinlẹ lori mimu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo ati jijọsin fun Un, koda ki awọn alaigbagbọ korira rẹ.

Àwọn àǹfààní

  • A fẹ́ ki a maa dunni mọ iranti yii lẹyin gbogbo irun ọranyan kọọkan.
  • Musulumi a maa ṣe iyanran pẹlu ẹsin rẹ yio si tun maa fi awọn arisami rẹ han koda ki awọn alaigbagbọ korira rẹ.
  • Ti gbolohun: “Duburu Sọlaat” ba wa nínú hadiisi, ti nkan ti o wa ninu hadīth yẹn ba jẹ àsíkìrí, ipilẹ rẹ ni ki o jẹ ẹyin salamọ, ti o ba wa jẹ adua, iwaju salamọ ni yio jẹ.

Kà á lórí HadeethEnc.com

4 Ẹ̀ẹ̀kan

سُبْحَانَ اللَّهِ (٣٣)، الْحَمْدُ لِلَّهِ (٣٣)، اللَّهُ أَكْبَرُ (٣٣)، لَا إِلَهَ إِلَّا اللَّهُ وَحْدَهُ لَا شَرِيكَ لَهُ، لَهُ الْمُلْكُ وَلَهُ الْحَمْدُ وَهُوَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Abu Hurayra- ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-: «Ẹni ti o ba ṣe afọmọ fun Ọlọhun (Subhānallāh) ni ẹyin gbogbo irun kọọkan ni igba mẹtalelọgbọn, ti o si tun dupẹ fun Ọlọhun (AlhamduliLlāhi) ni igba mẹtalelọgbọn, ti o tun wa gbe titobi fun Ọlọhun (Allāhu akbar) ni igba mẹtalelọgbọn, ìyẹn jẹ ọgọrun din ẹyọkan, ti o wa sọ ni ipari ọgọ́rùn-ún pe: Lā ilaha illā Allāhu wahdahu lā sharīka laHu, laHul mulku, wa laHul hamdu, wa Huwa alā kulli shayhin qadīr, wọn o fi ori gbogbo ẹṣẹ rẹ jin in kódà ki o to deede fóòmù ori omi okun».

Muslim gba a wa Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju ẹni ti o ba sọ lẹyin ti o ba pari awọn irun ọranyan:

Ni igba mẹtalelọgbọn pe: “Subhaanollooh”, oun naa ni mimọ Ọlọhun kuro nibi àléébù.

Ati ni igba mẹtalelọgbọn: "AlhamduliLlāhi" oun naa ni yiyin In pẹlu awọn iroyin pipe pẹlu inifẹẹ Rẹ ati gbigbe E tobi.

Ati ni igba mẹtalelọgbọn: "Allāhu akbar” oun ni pe Ọlọhun ni O tobi ju Oun si ni O gbọnngbọn ju gbogbo nkan lọ.

ki o mu onka naa pe ọgọ́rùn-ún pẹlu gbolohun: "Lā ilaha illā Allāhu wahdahu lā sharīka laHu, laHul mulku, wa laHul hamdu, wa Huwa ala kulli shayhin qadeer" itumọ rẹ si ni pe: Ko si ẹni ti ijọsin tọ si pẹ̀lú ẹtọ ayaafi Ọlọhun ni Oun nikan ṣoṣo ko si orogun fun Un, ati pe Oun- mimọ n bẹ fun Un- nìkan ni O ni ìjọba ti o pe, ti O si lẹtọọ si ẹyin pẹlu ifẹ ati igbetobi yatọ si ẹlòmíràn tí ó yatọ si I, ati pe Oun ni Olukapa ti nkankan o si le da A ni agara.

Ẹni ti o ba wa sọ ìyẹn wọn yio pa aṣiṣe rẹ rẹ wọn o si ṣe aforijin rẹ, koda ki o pọ bi foomu funfun ti maa n leke omi okun nígbà tí o ba n ru soke.

Àwọn àǹfààní

  • Fifẹ ṣiṣe iranti yii lẹyin awọn irun ọranyan.
  • Iranti yii okunfa aforijin ẹṣẹ ni o jẹ.
  • Titobi ọla Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ati ikẹ Rẹ ati aforijin Rẹ.
  • Dajudaju iranti yii okunfa aforijin ẹṣẹ ni, ati pe nkan ti wọn gbero ni: Pipa awọn ẹṣẹ kekere rẹ, ṣugbọn awọn ẹṣẹ nla ko si nkan ti o le pa a rẹ ayaafi ituuba.

Kà á lórí HadeethEnc.com

5 Ẹ̀ẹ̀kan

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Ka‘bu ọmọ ‘Ujroh - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Awọn gbolohun ẹyin irun kan n bẹ ti o ṣe pe ẹni ti o ba sọ wọn - tabi ti o ṣe wọn - ni ẹyin gbogbo irun ọranyan, ko ni mofo, subhānallāh ọgbọn ati mẹta, ati alhamduliLlāhi ọgbọn ati mẹta, ati Allāhu akbar ọgbọn ati mẹẹrin».

Muslim gba a wa Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo nipa awọn iranti ti ẹni ti o ba n sọ ọ o le mofo ti ko si le kabamọ, bi ko ṣe pe ẹsan awọn gbolohun yii a maa bẹ fun un, wọn o si maa wa lẹyin ara wọn, ti wọn o si tun maa sọ wọn lẹyin irun ọranyan, oun naa ni:

"Subhānallāh" ọgbọn ati mẹta, iyẹn ni fifọ Ọ mọ kuro nibi adinku.

Ati "AlhamduliLlāhi" ni igba ọgbọn ati mẹta, ati pe oun ni ìròyìn Ọlọhun pẹlu pipe papọ mọ ninifẹẹ Rẹ ati gbigbe titobi fun Un.

Ati "Allāhu akbar" ni igba ọgbọn ati mẹẹrin, nitori pe Ọlọhun tobi O si gbọnngbọn ju gbogbo nkan lọ.

Àwọn àǹfààní

  • Ọla ti n bẹ fun ṣiṣe subhānallāh ati alhamduliLlāhi ati Allāhu Akbar, ati pe awọn ni awọn iṣẹ rere to maa wa titi láéláé.

Kà á lórí HadeethEnc.com

6 Ẹ̀ẹ̀kan

اللَّهُ لَا إِلَهَ إِلَّا هُوَ الْحَيُّ الْقَيُّومُ لَا تَأْخُذُهُ سِنَةٌ وَلَا نَوْمٌ لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ مَنْ ذَا الَّذِي يَشْفَعُ عِنْدَهُ إِلَّا بِإِذْنِهِ يَعْلَمُ مَا بَيْنَ أَيْدِيهِمْ وَمَا خَلْفَهُمْ وَلَا يُحِيطُونَ بِشَيْءٍ مِنْ عِلْمِهِ إِلَّا بِمَا شَاءَ وَسِعَ كُرْسِيُّهُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَلَا يَئُودُهُ حِفْظُهُمَا وَهُوَ الْعَلِيُّ الْعَظِيمُ

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Abu Umāmah - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ẹni ti o ba ka āyatul kursiyyu ni ẹyin irun ọranyan kọọkan, ko si nkan ti yio di i lọwọ wiwọ al-jannah ayaafi ki o ku.

رواه النسائي في الكبرى Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe dajudaju ẹni ti o ba ka āyatul kursiyyu lẹyin ipari irun ọranyan, ko si nkankan ti o le ma jẹ ki o wọ alujanna ayaafi iku; o si wa ninu sūratul Baqorah, gbolohun Ọlọhun ti ọla rẹ ti o sọ pe: {Allahu la ilaha illa Huwa al-Hayyu al-Qayyoomu la ta‘khuthuHu sinatun wala nawmun laHu ma fis samāwāti wama fil ardi man dha ladhī yashfa‘u indaHu illa bi-idhniHi ya‘lamu mā bayna aydīhim wamā khalfahum wala yuhītūna bishayin min ‘ilmiHi illa bimā shaa'a wasi‘a kursiyyuHus samāwāti wal-arda wala ya’ūduHu hifdhuhumā waHuwal ‘aliyyu alAadhīm} [Al-Baqorah: 255]

Àwọn àǹfààní

  • Ọla ti o n bẹ fun aayah ti o tobi yii; latari nkan ti o ko sinu ninu awọn orukọ to rẹwa ati awọn iroyin ti o ga.
  • Ṣiṣe lẹtọọ kika aayah ti o tobi yẹn lẹyin gbogbo irun ọranyan.
  • Awọn iṣẹ oloore jẹ okunfa wiwọ al-jannah.

Kà á lórí HadeethEnc.com

Àwọn ìbéèrè

Kí ló wà lórí ojú-ìwé yìí?

Zikiri lẹ́yìn ìrun: ọ̀kọ̀ọ̀kan ní èdè Lárúbáwá, pẹ̀lú ìtumọ̀ rẹ̀, hadiisi tí ó ti wá, ipò rẹ̀ àti àlàyé.

Níbo ni àwọn ìtumọ̀ ti wá?

Láti HadeethEnc.com, Ìwé Ìmọ̀ Àwọn Hadiisi Ànábì Tí A Túmọ̀. A ń fi hadiisi kọ̀ọ̀kan hàn gẹ́lẹ́ bí wọ́n ṣe tẹ̀ ẹ́ jáde, pẹ̀lú orísun àti ipò rẹ̀, àti ìjápọ̀ sí ojúlówó rẹ̀.

Ṣé mo lè gba ìrántí ojoojúmọ́?

Bẹ́ẹ̀ni. Ohun èlò Qabas ọ̀fẹ́ fún Android máa ń rán ọ létí zikiri òwúrọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ lójoojúmọ́, ó sì ní ẹ̀rọ ìkà kan náà.