Adua kí a tó sùn àti zikiri oorun

Ohun tí Ànábì ﷺ máa ń sọ àti ohun tí ó máa ń kà nígbà tí ó bá fẹ́ sùn.

1 Ẹ̀ẹ̀kan

قُلْ هُوَ اللَّهُ أَحَدٌ ﴿١﴾ اللَّهُ الصَّمَدُ ﴿٢﴾ لَمْ يَلِدْ وَلَمْ يُولَدْ ﴿٣﴾ وَلَمْ يَكُن لَّهُ كُفُوًا أَحَدٌ ﴿٤﴾
قُلْ أَعُوذُ بِرَبِّ الْفَلَقِ ﴿١﴾ مِن شَرِّ مَا خَلَقَ ﴿٢﴾ وَمِن شَرِّ غَاسِقٍ إِذَا وَقَبَ ﴿٣﴾ وَمِن شَرِّ النَّفَّاثَاتِ فِي الْعُقَدِ ﴿٤﴾ وَمِن شَرِّ حَاسِدٍ إِذَا حَسَدَ ﴿٥﴾
قُلْ أَعُوذُ بِرَبِّ النَّاسِ ﴿١﴾ مَلِكِ النَّاسِ ﴿٢﴾ إِلَهِ النَّاسِ ﴿٣﴾ مِن شَرِّ الْوَسْوَاسِ الْخَنَّاسِ ﴿٤﴾ الَّذِي يُوَسْوِسُ فِي صُدُورِ النَّاسِ ﴿٥﴾ مِنَ الْجِنَّةِ وَالنَّاسِ ﴿٦﴾

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i-: Pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti fẹ sùn ni gbogbo alẹ́, o maa pa atẹlẹwọ rẹ méjèèjì pọ̀, lẹyin naa o maa fẹnu fẹ atẹ́gùn túẹ́túẹ́ sinu méjèèjì, o maa wa ka sínú méjèèjì: {Qul Uwal Loohu Ahad}, ati {Qul Ahuuzu bi Robbil falaq}, ati {Qul Ahuuzu bi Robbin naas}, lẹyin naa o maa fi méjèèjì pa ibi ti o ba ṣeé pa ni ara rẹ, o maa bẹ̀rẹ̀ lati orí rẹ ati oju rẹ, ati ẹ̀yà ti iwájú ninu ara rẹ, o maa ṣe bẹ́ẹ̀ ni ẹẹmẹta.

Bukhaariy gba a wa Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Nínú ìtọ́sọ́nà Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti fẹ sùn ni pe o maa pa atẹlẹwọ rẹ méjèèjì pọ̀, o si maa gbe wọn sókè- gẹgẹ bi ẹni tí n ṣe adua- o maa wa rọra fẹnu fẹ́ atẹ́gùn si i pẹ̀lú itọ́ díẹ̀, o maa ka àwọn suura mẹtẹẹta naa: {Qul Uwal Loohu Ahad} ati {Qul Ahuuzu bi Robbil falaq} ati {Qul Ahuuzu bi Robbin naas}, lẹ́yìn náà ni o maa fi atẹlẹwọ rẹ méjèèjì pa ibi ti o ba ṣee pa ni ara rẹ; o maa bẹ̀rẹ̀ lati orí rẹ, ati ojú rẹ, ati ẹya iwaju ara rẹ, o maa pààrà rẹ ni ẹẹmẹta.

Àwọn àǹfààní

  • Fifẹ kika suuratul Ikhlaas ati Qul Ahuuzu kìíní-kejì ṣiwaju oorun, ati fifi wọn fẹnu fẹ atẹgun túẹ́túẹ́, ati fifi wọn pa ohun ti o ba ṣee pa ninu ara rẹ.

Kà á lórí HadeethEnc.com

2 Ẹ̀ẹ̀kan

آمَنَ الرَّسُولُ بِمَا أُنْزِلَ إِلَيْهِ مِنْ رَبِّهِ وَالْمُؤْمِنُونَ كُلٌّ آمَنَ بِاللَّهِ وَمَلَائِكَتِهِ وَكُتُبِهِ وَرُسُلِهِ لَا نُفَرِّقُ بَيْنَ أَحَدٍ مِنْ رُسُلِهِ وَقَالُوا سَمِعْنَا وَأَطَعْنَا غُفْرَانَكَ رَبَّنَا وَإِلَيْكَ الْمَصِيرُ ﴿٢٨٥﴾ لَا يُكَلِّفُ اللَّهُ نَفْسًا إِلَّا وُسْعَهَا لَهَا مَا كَسَبَتْ وَعَلَيْهَا مَا اكْتَسَبَتْ رَبَّنَا لَا تُؤَاخِذْنَا إِنْ نَسِينَا أَوْ أَخْطَأْنَا رَبَّنَا وَلَا تَحْمِلْ عَلَيْنَا إِصْرًا كَمَا حَمَلْتَهُ عَلَى الَّذِينَ مِنْ قَبْلِنَا رَبَّنَا وَلَا تُحَمِّلْنَا مَا لَا طَاقَةَ لَنَا بِهِ وَاعْفُ عَنَّا وَاغْفِرْ لَنَا وَارْحَمْنَا أَنْتَ مَوْلَانَا فَانْصُرْنَا عَلَى الْقَوْمِ الْكَافِرِينَ ﴿٢٨٦﴾

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Abu Mas‘ūd – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ẹni ti o ba ka aayah meji ti o gbẹyin Sūratul Bakọra ni oru kan, wọn ti to fún un».

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ wipe dajudaju ẹni tí o ba ka aayah meji ti o gbẹyin Sūratul Bakọra ni alẹ, dajudaju Ọlọhun a to o kuro nibi aburu ati nkan ti ko dáa, wọn tun sọ pe: Yio gbe e nibi didide loru (irun oru), wọn tun sọ pe: Yio gbe e nibi awọn iranti yòókù, wọn tun sọ pe: Dajudaju mejeji ni odiwọn ti o kere ju ti o le to ninu kika Kuraani nibi idide oru (irun oru), wọn si tun sọ nkan ti o yatọ si ìyẹn, ati pe o sunmọ pe gbogbo nkan ti wọn sọ yẹn naa ni o daa ti gbolohun yẹn naa si ko o sinu.

Àwọn àǹfààní

  • Alaye ọla ti o wa fun awọn aayah igbẹyin Sūratul Bakọra, ti o bẹrẹ lati ibi gbolohun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ti o wi pe: (Āmana rosūlu…) titi de ipari Sūrah naa.
  • Awọn igbẹyin Sūratul Bakọra maa n ti aidara ati aburu ati èṣù dànù fún ẹni tí o ba n ka a ti o ba ka a ni alẹ.
  • Oru bẹrẹ pẹlu wiwọ oorun, o si pari pẹlu yiyọ alufajari.

Kà á lórí HadeethEnc.com

Àwọn ìbéèrè

Kí ló wà lórí ojú-ìwé yìí?

Adua kí a tó sùn: ọ̀kọ̀ọ̀kan ní èdè Lárúbáwá, pẹ̀lú ìtumọ̀ rẹ̀, hadiisi tí ó ti wá, ipò rẹ̀ àti àlàyé.

Níbo ni àwọn ìtumọ̀ ti wá?

Láti HadeethEnc.com, Ìwé Ìmọ̀ Àwọn Hadiisi Ànábì Tí A Túmọ̀. A ń fi hadiisi kọ̀ọ̀kan hàn gẹ́lẹ́ bí wọ́n ṣe tẹ̀ ẹ́ jáde, pẹ̀lú orísun àti ipò rẹ̀, àti ìjápọ̀ sí ojúlówó rẹ̀.

Ṣé mo lè gba ìrántí ojoojúmọ́?

Bẹ́ẹ̀ni. Ohun èlò Qabas ọ̀fẹ́ fún Android máa ń rán ọ létí zikiri òwúrọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ lójoojúmọ́, ó sì ní ẹ̀rọ ìkà kan náà.