Suratu Al-Ikhlas الإخلاص

Ìtumọ̀: Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

قُلۡ هُوَ ٱللَّهُ أَحَدٌ ١

Qul huwallāhu ahad

Sọ pé: “Òun ni Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo.

ٱللَّهُ ٱلصَّمَدُ ٢

Allāhus-samad

Allāhu ni Aṣíwájú tí ẹ̀dá ní bùkátà sí níbi jíjọ́sìn fún Un àti títọrọ oore ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀, tí Òun kò sì ní bùkátà sí wọn ní ọ̀nà kan kan.

لَمۡ يَلِدۡ وَلَمۡ يُولَدۡ ٣

Lam yalid walam yūlad

Kò bímọ. Wọn kò sì bí I.

وَلَمۡ يَكُن لَّهُۥ كُفُوًا أَحَدُۢ ٤

Walam yakul lahū kufuwan ahad

Kò sì sí ẹnì kan kan tí ó jọ Ọ́.”1

Àwọn nọ́mbà àlàyé ìsàlẹ̀ máa ń mú ọ lọ sí ojú-ewé aaya náà, níbi tí àlàyé olùtúmọ̀ wà.

Kíkà ní lẹ́tà Látìn jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkà tí Qabas kọ láti inú èdè Lárúbáwá. Kọ́ àwọn lẹ́tà Lárúbáwá àti tajwīd fún ìpè tó péye.

Àwọn ìbéèrè

Aaya mélòó ló wà nínú Suratu Al-Ikhlas?

Suratu Al-Ikhlas ní aaya 4. Òun ni sura nọ́mbà 112 nínú Al-Kurani.

Ṣé Suratu Al-Ikhlas jẹ́ Makkiyya tàbí Madaniyya?

Suratu Al-Ikhlas jẹ́ sura Makkiyya.

Juz wo ni Suratu Al-Ikhlas wà?

Suratu Al-Ikhlas wà nínú Juz 30.

Ṣé mo lè gbọ́ Suratu Al-Ikhlas?

Bẹ́ẹ̀ni. Tẹ Bẹ̀rẹ̀ ní òkè ojú-ewé yìí, tàbí bẹ̀rẹ̀ láti aaya èyíkéyìí. Àpù Qabas tún jẹ́ kí o gbà á sílẹ̀ láti gbọ́ ọ láìsí ayélujára.