Suratu An-Nas الناس

Ìtumọ̀: Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

قُلۡ أَعُوذُ بِرَبِّ ٱلنَّاسِ ١

Qul a'ūdhu birabbin-nās

Sọ pé: “Mo sá di Olúwa àwọn ènìyàn,

مَلِكِ ٱلنَّاسِ ٢

Malikin-nās

Ọba àwọn ènìyàn,

إِلَٰهِ ٱلنَّاسِ ٣

Ilāhin-nās

Ọlọ́hun àwọn ènìyàn,1

مِن شَرِّ ٱلۡوَسۡوَاسِ ٱلۡخَنَّاسِ ٤

Min sharril-waswāsil-khannās

níbi aburú (aṣ-Ṣaetọ̄n) oníròyíròyí, olùsásẹ́yìn (fún ẹni tó bá ń dárúkọ Allāhu1).

ٱلَّذِي يُوَسۡوِسُ فِي صُدُورِ ٱلنَّاسِ ٥

Alladhī yuwaswisu fī sudūrin-nās

(aṣ-Ṣaetọ̄n ni) ẹni tí ó ń kó ròyíròyí sínú àwọn ọkàn ènìyàn.

مِنَ ٱلۡجِنَّةِ وَٱلنَّاسِ ٦

Minal-jinnati wan-nās

(Ṣaetọ̄n náà) wà nínú àwọn àlùjànnú àti àwọn ènìyàn.”

Àwọn nọ́mbà àlàyé ìsàlẹ̀ máa ń mú ọ lọ sí ojú-ewé aaya náà, níbi tí àlàyé olùtúmọ̀ wà.

Kíkà ní lẹ́tà Látìn jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkà tí Qabas kọ láti inú èdè Lárúbáwá. Kọ́ àwọn lẹ́tà Lárúbáwá àti tajwīd fún ìpè tó péye.

Àwọn ìbéèrè

Aaya mélòó ló wà nínú Suratu An-Nas?

Suratu An-Nas ní aaya 6. Òun ni sura nọ́mbà 114 nínú Al-Kurani.

Ṣé Suratu An-Nas jẹ́ Makkiyya tàbí Madaniyya?

Suratu An-Nas jẹ́ sura Makkiyya.

Juz wo ni Suratu An-Nas wà?

Suratu An-Nas wà nínú Juz 30.

Ṣé mo lè gbọ́ Suratu An-Nas?

Bẹ́ẹ̀ni. Tẹ Bẹ̀rẹ̀ ní òkè ojú-ewé yìí, tàbí bẹ̀rẹ̀ láti aaya èyíkéyìí. Àpù Qabas tún jẹ́ kí o gbà á sílẹ̀ láti gbọ́ ọ láìsí ayélujára.