Suratu Al-Falaq الفلق

Ìtumọ̀: Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

قُلۡ أَعُوذُ بِرَبِّ ٱلۡفَلَقِ ١

Qul a'ūdhu birabbil-falaq

Sọ pé: “Mo sá di Olúwa òwúrọ̀ kùtùkùtù

مِن شَرِّ مَا خَلَقَ ٢

Min sharri mā khalaq

níbi aburú ohun tí Ó dá,1

وَمِن شَرِّ غَاسِقٍ إِذَا وَقَبَ ٣

Wamin sharri ghāsiqin idhā waqab

àti níbi aburú òru nígbà tí ó bá ṣóòkùn,

وَمِن شَرِّ ٱلنَّفَّٰثَٰتِ فِي ٱلۡعُقَدِ ٤

Wamin sharrin-naffāthāti fil-'uqad

àti níbi aburú àwọn (òpìdán) tó ń fẹnu fátẹ́gùn túẹ́túẹ́ sínú àwọn ońdè,

وَمِن شَرِّ حَاسِدٍ إِذَا حَسَدَ ٥

Wamin sharri hāsidin idhā hasad

àti níbi aburú onílara nígbà tí ó bá ṣe ìlara.”

Àwọn nọ́mbà àlàyé ìsàlẹ̀ máa ń mú ọ lọ sí ojú-ewé aaya náà, níbi tí àlàyé olùtúmọ̀ wà.

Kíkà ní lẹ́tà Látìn jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkà tí Qabas kọ láti inú èdè Lárúbáwá. Kọ́ àwọn lẹ́tà Lárúbáwá àti tajwīd fún ìpè tó péye.

Àwọn ìbéèrè

Aaya mélòó ló wà nínú Suratu Al-Falaq?

Suratu Al-Falaq ní aaya 5. Òun ni sura nọ́mbà 113 nínú Al-Kurani.

Ṣé Suratu Al-Falaq jẹ́ Makkiyya tàbí Madaniyya?

Suratu Al-Falaq jẹ́ sura Makkiyya.

Juz wo ni Suratu Al-Falaq wà?

Suratu Al-Falaq wà nínú Juz 30.

Ṣé mo lè gbọ́ Suratu Al-Falaq?

Bẹ́ẹ̀ni. Tẹ Bẹ̀rẹ̀ ní òkè ojú-ewé yìí, tàbí bẹ̀rẹ̀ láti aaya èyíkéyìí. Àpù Qabas tún jẹ́ kí o gbà á sílẹ̀ láti gbọ́ ọ láìsí ayélujára.