Ohun tí a ó ṣe lẹ́yìn àlá rere tàbí àlá burúkú

Ohun tí a ó ṣe àti tí a ó sọ lẹ́yìn àlá rere, àti lẹ́yìn àlá tí ó ń bani lẹ́rù.

1 Ẹ̀ẹ̀kan

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Abu Qatada - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pé: Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a - sọ pé: Lati ọdọ Ọlọhun ni ala daada ti nwa, bẹẹ ni láti ọdọ èṣù (Satani) ni ala burúkú ti nwa, ti ẹnikan nínú yín bá lá ala tí o se idẹruba fun un, ki o yáa fẹ atẹgun itọ ẹnu rẹ sí apá òsì, ki o si wa isọra pẹlu Ọlọhun nibi aburú ala náà, ti o ba se bẹẹ dájúdájú ala náà kòní kó ìnira ba a".

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) fún wa niro pé ala daada ti o dun ni ninu láti ojú orun lati ọdọ Ọlọhun ni ti nwa, bẹẹ ni alakala ti ko da ti o si nbani nínú jẹ, lati ọdọ èṣù ni ti nwa.

Ẹni k'ẹni ti o bá lala ri nkan ti kò wu u, ki o ya tutọ sí apá òsì rẹ, ki o si wa isọra pẹlu Ọlọhun nibi aburu ala naa, ala náà ko nii ko aburú ba nitoripe Ọlọhun ti fi gbolohun ti o sọ yẹn se okunfa àkóyọ nibi nkan ti kò fẹ ti o le t'ara ala tí o la ṣẹlẹ.

Àwọn àǹfààní

  • Ala ni ohun ti eni t'osun ri loju orun rẹ, ṣugbọn o wọ pọ ki wọn lo gbólóhùn (Arruyah) fún daada ti eni náà ri àti nkan rere, bẹẹni o wọ pọ ki wọn lo gbólóhùn (Al-hulum) fún aburú ati awọn nkan ti ko da ti ẹni náà ba ri, wọn si ma nlo mejeeji sí ààyè ara wọn.
  • Ipin àlá: 1. Ala daada, ohun ni ala òtítọ àti iro ìdùnnú lati ọdọ Ọlọhun wa, ẹni tó sún aa ri fún raa rẹ tabi ki wọn la ala náà si, 2. Ọrọ ti ẹmi ba araarẹ sọ, ohun naa ni ọrọ ti eniyan ba araarẹ sọ ni feteete, 3. Ibani ninujẹ ati idẹrubani esu (satani) ati awọn idunkoko lati ọdọ rẹ ki o le ba ọmọ anabi Adamọ ninujẹ
  • Nkan mẹta ti o jẹ abayori nkan ti wọn sọ nipa ala daada: ki o fi ẹyin fún Ọlọhun fún ala náà, ki o si funni ni iro idunu nipa rẹ, ki o si sọ ọ jade, sugbọn ki o sọ ọ fún ẹni tí nfẹran rẹ nikan, ki o ma se sọ ọ fún ẹniti ko fẹran rẹ.
  • Nkan máàrún ni àkòrí nkán ti wọn ṣọ nipa ẹkọ tó wà fún ala burúkú: ki ẹni naa wa isora pẹlu Ọlọhun nibi aburú ala náà, ati nibi aburú èṣù (satani), ki o si tutọ alátẹgun sí apá òsì rẹ ni ẹẹmẹta ti o ba ti ji, kò si gbọdọ sọ fún ẹnikankan rárá, ti o ba ti fẹ sùn padà ki o yi ẹgbẹ ti o fi sun siwaju pada, ti o ba se eleyi ala náà kò ní ko ìnira ba.

Kà á lórí HadeethEnc.com

2 Ẹ̀ẹ̀kan

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ baba Sa'eed Al-khudiriy - Ki Ọlọhun bá wa yọnu si i - Ó ní oun gbọ́ tí Òjíṣẹ Ọlọhun - Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ̀ máa ba - tí ńsọ bayii pé: "Nígbàtí ẹnikan nínú yín bá lá àlá tí ó nifẹ sí, dajudaju ala naa lati ọdọ Ọlọhun ni ó ti wá, nitori naa ki ó fi ọpẹ fún Allah (Ọlọhun) lori rẹ, kó sì sọ ọ́ fún ẹniti ó bá fẹ́, ṣugbọn tí ó bá lá àlá tí ó yàtọ̀ sí eleyii, ti kò sì wuu, dajudaju lati ọdọ èṣù ni o ti wá, ki iru ẹni bẹẹ yaa bẹ Ọlọhun fún ààbò àti iṣọ nibi aburu àlá naa, bẹẹ ni ki ó má rọ́ àlá náà fún ẹnikankan, ti kò bati rọ ọ fún ẹnikankan àlá náà kò ní kó ìnira ba a".

Bukhaariy gba a wa Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa bá a - fún wa ní ìró pé dajudaju àlá daada tí ó ń múnú ẹni dùn lójú orun wá lati ọdọ Ọlọhun, Anọbi sì tọ wa sọna pe kí a fi ọpẹ fún Allah (Ọlọhun) lori rẹ, ẹni naa sì lè sọ jade, ṣugbọn ti ó bá lálàá rí nkan tí kò fẹ́, tabi nkan tó ba a nínú jẹ́, lati ọdọ eṣu ni ó tiwa, ki o yáa wá iṣọra lọdọ Ọlọhun kuro nibi aburu rẹ, kí ó má ṣe rọ́ àlá náà tabi sọfún ẹnikankan, dájúdájú kò nii kó ìnira bá a nígbàtí o jẹ wipe Ọlọhun ti fi nkan táa sọ yii ṣe okunfa ọlà ati akoyọ kuro nibi nkan ti a kò fẹ, eyi ti ó lè fẹ ṣẹlẹ latara àlá náà.

Àwọn àǹfààní

  • Awọn ipin àlá: 1. Àlá tí ó dáa, ohun ni àlá òtitọ ati ifunni ní iro idunu lati ọdọ Ọlọhun, eniyan lè la a funra rẹ tabi ki wọ́n la a si i. 2. Ọ̀rọ̀ tẹmi banusọ, ohun ni ọrọ ti ènìyàn ba ara rẹ sọ ní feteete (ni oju aiye) 3. Ibani nínú jẹ ati iṣẹru bani lati ọdọ èṣù (satani), ati ikoni laya jẹ lati ọdọ rẹ; lati fí kó ìbànújẹ́ bá eniyan.
  • Kókó nkan ti wọ́n sọ nípa àlá dáada mẹta ni: Kí o dupẹ fún Allah (Ọlọhun) lori rẹ, ki o dunnu nipa rẹ, kí o sí sọ ọ fun àwọn eniyan, ṣugbọn awọn tí o nifẹ nikan nio laiṣe awọn ti o korira.
  • Àpapọ̀ nkan ti wọ́n sọ nípa àlá buruku tí kò daa marun ni: ki a bere iṣọra lọdọ Ọlọhun kuro nibi aburu rẹ, ati nibi aburu èṣù, ki a sì fẹ atẹgun ẹnu wa sí apá òsì wa lẹẹmẹta nigba ti a bá jí, bẹẹ a kò gbọdọ bá ẹnikankan sọrọ nipa rẹ, ti ènìyàn náà bá fẹ sùn pada, kí ó yí ẹgbẹ ti o fi sun pada, àlá buruku naa kò nii kó ìnira ba a.
  • Ibn Hajar sọ pe: Òye tabi idi pataki tí ó wà nibẹ ni pe tí ó bá rọ́ àlá dáada fún ẹnití kò nifẹ rẹ, irufẹ ẹni bẹẹ lè tumọ àlá náà fún-un sí nkan tí kò fẹ́, yálà nítorí pé o n binu si daada ti o rí, tabi ni ti keeta ati ẹ̀gàn, o ṣeeṣe kí àlá náà ṣẹlẹ gẹgẹ bí wọn ṣe tumọ rẹ, tabi ki ẹni ti ó lálàá máa kánjú fúnrara rẹ fún ìbànújẹ ati aidunnu ọkan, nítorí rẹ ni wọn fi paá laṣẹ pe kí ó má ṣe sọ àlá náà fún ẹniti kò nifẹ sii.
  • Kí a máa dúpẹ́ fún Ọlọhun nigbati awọn idẹra bá n dé sinu aiye wa, ti awọn aanu sì nwá lọ́tun lọ́tun; eleyii ni òkùnfà tí idẹra náà máa fi pẹ́.

Kà á lórí HadeethEnc.com

Àwọn ìbéèrè

Kí ló wà lórí ojú-ìwé yìí?

Adua lẹ́yìn àlá burúkú: ọ̀kọ̀ọ̀kan ní èdè Lárúbáwá, pẹ̀lú ìtumọ̀ rẹ̀, hadiisi tí ó ti wá, ipò rẹ̀ àti àlàyé.

Níbo ni àwọn ìtumọ̀ ti wá?

Láti HadeethEnc.com, Ìwé Ìmọ̀ Àwọn Hadiisi Ànábì Tí A Túmọ̀. A ń fi hadiisi kọ̀ọ̀kan hàn gẹ́lẹ́ bí wọ́n ṣe tẹ̀ ẹ́ jáde, pẹ̀lú orísun àti ipò rẹ̀, àti ìjápọ̀ sí ojúlówó rẹ̀.

Ṣé mo lè gba ìrántí ojoojúmọ́?

Bẹ́ẹ̀ni. Ohun èlò Qabas ọ̀fẹ́ fún Android máa ń rán ọ létí zikiri òwúrọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ lójoojúmọ́, ó sì ní ẹ̀rọ ìkà kan náà.