Suratu Al-Masad المسد

Ìtumọ̀: Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

تَبَّتۡ يَدَآ أَبِي لَهَبٖ وَتَبَّ ١

Tabbat yadā abī lahabin watabb

Ọwọ́ Abu-Lahab méjèèjì ti ṣòfò. Òun náà sì ṣòfò.

مَآ أَغۡنَىٰ عَنۡهُ مَالُهُۥ وَمَا كَسَبَ ٢

Mā aghnā 'anhu māluhū wamā kasab

Àwọn dúkìá rẹ̀ àti ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (ìyẹn, àwọn ọmọ rẹ̀) kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ (níbi ìyà).

سَيَصۡلَىٰ نَارٗا ذَاتَ لَهَبٖ ٣

Sayaslā nāran dhāta lahab

Ó sì máa wọ inú Iná eléjò fòfò.

وَٱمۡرَأَتُهُۥ حَمَّالَةَ ٱلۡحَطَبِ ٤

Wamra'atuhū hammālatal-hatab

Àti ìyàwó rẹ̀, aláàárù-igi-ìṣẹ́pẹ́ ẹlẹ́gùn-ún, (ó máa wọná).

فِي جِيدِهَا حَبۡلٞ مِّن مَّسَدِۭ ٥

Fī jīdihā hablum mim masad

Igbà-ọ̀pẹ pọ̀npọ̀nràn máa wà ní ọrùn rẹ̀ (nínú Iná).

Kíkà ní lẹ́tà Látìn jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkà tí Qabas kọ láti inú èdè Lárúbáwá. Kọ́ àwọn lẹ́tà Lárúbáwá àti tajwīd fún ìpè tó péye.

Àwọn ìbéèrè

Aaya mélòó ló wà nínú Suratu Al-Masad?

Suratu Al-Masad ní aaya 5. Òun ni sura nọ́mbà 111 nínú Al-Kurani.

Ṣé Suratu Al-Masad jẹ́ Makkiyya tàbí Madaniyya?

Suratu Al-Masad jẹ́ sura Makkiyya.

Juz wo ni Suratu Al-Masad wà?

Suratu Al-Masad wà nínú Juz 30.

Ṣé mo lè gbọ́ Suratu Al-Masad?

Bẹ́ẹ̀ni. Tẹ Bẹ̀rẹ̀ ní òkè ojú-ewé yìí, tàbí bẹ̀rẹ̀ láti aaya èyíkéyìí. Àpù Qabas tún jẹ́ kí o gbà á sílẹ̀ láti gbọ́ ọ láìsí ayélujára.