Suratu An-Nasr النصر

Ìtumọ̀: Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

إِذَا جَآءَ نَصۡرُ ٱللَّهِ وَٱلۡفَتۡحُ ١

Idhā jā'a nasrullāhi wal-fath

Nígbà tí àrànṣe Allāhu (lórí ọ̀tá ẹ̀sìn) àti ṣíṣí ìlú (Mọ́kkah) bá ṣẹlẹ̀,

وَرَأَيۡتَ ٱلنَّاسَ يَدۡخُلُونَ فِي دِينِ ٱللَّهِ أَفۡوَاجٗا ٢

Wara'aytan-nāsa yadkhulūna fī dīnillāhi afwājā

tí o sì rí àwọn ènìyàn tí wọ́n wọnú ẹ̀sìn Allāhu níjọníjọ,

فَسَبِّحۡ بِحَمۡدِ رَبِّكَ وَٱسۡتَغۡفِرۡهُۚ إِنَّهُۥ كَانَ تَوَّابَۢا ٣

Fasabbih bihamdi rabbika wastaghfirhu innahū kāna tawwābā

nítorí náà, ṣe àfọ̀mọ́ àti ẹyìn fún Olúwa rẹ. Kí o sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀.1 Dájúdájú Ó ń jẹ́ Olùgba-ìronúpìwàdà.

Àwọn nọ́mbà àlàyé ìsàlẹ̀ máa ń mú ọ lọ sí ojú-ewé aaya náà, níbi tí àlàyé olùtúmọ̀ wà.

Kíkà ní lẹ́tà Látìn jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkà tí Qabas kọ láti inú èdè Lárúbáwá. Kọ́ àwọn lẹ́tà Lárúbáwá àti tajwīd fún ìpè tó péye.

Àwọn ìbéèrè

Aaya mélòó ló wà nínú Suratu An-Nasr?

Suratu An-Nasr ní aaya 3. Òun ni sura nọ́mbà 110 nínú Al-Kurani.

Ṣé Suratu An-Nasr jẹ́ Makkiyya tàbí Madaniyya?

Suratu An-Nasr jẹ́ sura Madaniyya.

Juz wo ni Suratu An-Nasr wà?

Suratu An-Nasr wà nínú Juz 30.

Ṣé mo lè gbọ́ Suratu An-Nasr?

Bẹ́ẹ̀ni. Tẹ Bẹ̀rẹ̀ ní òkè ojú-ewé yìí, tàbí bẹ̀rẹ̀ láti aaya èyíkéyìí. Àpù Qabas tún jẹ́ kí o gbà á sílẹ̀ láti gbọ́ ọ láìsí ayélujára.