Suratu At-Takathur التكاثر

Ìtumọ̀: Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

أَلۡهَىٰكُمُ ٱلتَّكَاثُرُ ١

Alhākumut-takāthur

Wíwá oore ayé ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ fún ìyanràn ṣíṣe ti kó àìrójú fẹ́sìn ba yín

حَتَّىٰ زُرۡتُمُ ٱلۡمَقَابِرَ ٢

Hattā zurtumul-maqābir

títí ẹ fi wọ inú sàréè.

كَلَّا سَوۡفَ تَعۡلَمُونَ ٣

Kallā sawfa ta'lamūn

Rárá (kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, àmọ́) láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.

ثُمَّ كَلَّا سَوۡفَ تَعۡلَمُونَ ٤

Thumma kallā sawfa ta'lamūn

Lẹ́yìn náà, ní ti òdodo, láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.

كَلَّا لَوۡ تَعۡلَمُونَ عِلۡمَ ٱلۡيَقِينِ ٥

Kallā law ta'lamūna 'ilmal-yaqīn

Ní ti òdodo, tí ó bá jẹ́ pé ẹ ni ìmọ̀ àmọ̀dájú ni (ẹ̀yin ìbá tí ṣe bẹ́ẹ̀).

لَتَرَوُنَّ ٱلۡجَحِيمَ ٦

Latarawunnal-jahīm

Dájúdájú ẹ máa rí iná Jẹhīm.

ثُمَّ لَتَرَوُنَّهَا عَيۡنَ ٱلۡيَقِينِ ٧

Thumma latarawunnahā 'aynal-yaqīn

Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ máa fi ojú rí i ní àrídájú.

ثُمَّ لَتُسۡـَٔلُنَّ يَوۡمَئِذٍ عَنِ ٱلنَّعِيمِ ٨

Thumma latus'alunna yawma'idhin 'anin-na'īm

Lẹ́yìn náà, dájúdájú ní ọjọ́ yẹn wọ́n máa bi yín léèrè nípa ìgbádùn (ayé yìí).

Kíkà ní lẹ́tà Látìn jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkà tí Qabas kọ láti inú èdè Lárúbáwá. Kọ́ àwọn lẹ́tà Lárúbáwá àti tajwīd fún ìpè tó péye.

Àwọn ìbéèrè

Aaya mélòó ló wà nínú Suratu At-Takathur?

Suratu At-Takathur ní aaya 8. Òun ni sura nọ́mbà 102 nínú Al-Kurani.

Ṣé Suratu At-Takathur jẹ́ Makkiyya tàbí Madaniyya?

Suratu At-Takathur jẹ́ sura Makkiyya.

Juz wo ni Suratu At-Takathur wà?

Suratu At-Takathur wà nínú Juz 30.

Ṣé mo lè gbọ́ Suratu At-Takathur?

Bẹ́ẹ̀ni. Tẹ Bẹ̀rẹ̀ ní òkè ojú-ewé yìí, tàbí bẹ̀rẹ̀ láti aaya èyíkéyìí. Àpù Qabas tún jẹ́ kí o gbà á sílẹ̀ láti gbọ́ ọ láìsí ayélujára.