Suratu Al-Qari'ah القارعة

Ìtumọ̀: Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

ٱلۡقَارِعَةُ ١

Al-qāri'ah

Àkókò ìjáyà.

مَا ٱلۡقَارِعَةُ ٢

Mal-qāri'ah

Kí ni Àkókò ìjáyà?

وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡقَارِعَةُ ٣

Wamā adrāka mal-qāri'ah

Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Àkókò ìjáyà?

يَوۡمَ يَكُونُ ٱلنَّاسُ كَٱلۡفَرَاشِ ٱلۡمَبۡثُوثِ ٤

Yawma yakūnun-nāsu kal-farāshil-mabthūth

(Òhun ni) ọjọ́ tí ènìyàn yó dà bí àfòpiná tí wọ́n fọ́nká síta,

وَتَكُونُ ٱلۡجِبَالُ كَٱلۡعِهۡنِ ٱلۡمَنفُوشِ ٥

Watakūnul-jibālu kal-'ihnil-manfūsh

àwọn àpáta yó sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú tí wọ́n gbọ̀n dànù.

فَأَمَّا مَن ثَقُلَتۡ مَوَٰزِينُهُۥ ٦

Fa ammā man thaqulat mawāzīnuh

Nítorí náà, ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀wọ̀n,

فَهُوَ فِي عِيشَةٖ رَّاضِيَةٖ ٧

Fahuwa fī 'īshatir rādiyah

ó sì máa wà nínú ìṣẹ̀mí tó máa yọ́nú sí.

وَأَمَّا مَنۡ خَفَّتۡ مَوَٰزِينُهُۥ ٨

Wa ammā man khaffat mawāzīnuh

Ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá sì fúyẹ́,

فَأُمُّهُۥ هَاوِيَةٞ ٩

Fa ummuhū hāwiyah

Hāwiyah sì ni ibùgbé rẹ̀.

وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا هِيَهۡ ١٠

Wamā adrāka mā hiyah

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀?

نَارٌ حَامِيَةُۢ ١١

Nārun hāmiyah

(Òhun ni) Iná gbígbóná tó ń jó gan-an.

Kíkà ní lẹ́tà Látìn jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkà tí Qabas kọ láti inú èdè Lárúbáwá. Kọ́ àwọn lẹ́tà Lárúbáwá àti tajwīd fún ìpè tó péye.

Àwọn ìbéèrè

Aaya mélòó ló wà nínú Suratu Al-Qari'ah?

Suratu Al-Qari'ah ní aaya 11. Òun ni sura nọ́mbà 101 nínú Al-Kurani.

Ṣé Suratu Al-Qari'ah jẹ́ Makkiyya tàbí Madaniyya?

Suratu Al-Qari'ah jẹ́ sura Makkiyya.

Juz wo ni Suratu Al-Qari'ah wà?

Suratu Al-Qari'ah wà nínú Juz 30.

Ṣé mo lè gbọ́ Suratu Al-Qari'ah?

Bẹ́ẹ̀ni. Tẹ Bẹ̀rẹ̀ ní òkè ojú-ewé yìí, tàbí bẹ̀rẹ̀ láti aaya èyíkéyìí. Àpù Qabas tún jẹ́ kí o gbà á sílẹ̀ láti gbọ́ ọ láìsí ayélujára.