Suratu Ad-Duha الضحى

Ìtumọ̀: Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

وَٱلضُّحَىٰ ١

Wad-duhā

Allāhu fi ìyálẹ̀ta búra.

وَٱلَّيۡلِ إِذَا سَجَىٰ ٢

Wallayli idhā sajā

Ó tún fi alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú búra.

مَا وَدَّعَكَ رَبُّكَ وَمَا قَلَىٰ ٣

Mā wadda'aka rabbuka wamā qalā

Olúwa rẹ kò pa ọ́ tì, kò sì bínú sí ọ.

وَلَلۡأٓخِرَةُ خَيۡرٞ لَّكَ مِنَ ٱلۡأُولَىٰ ٤

Walal'ākhiratu khayrul laka minal-ūlā

Dájúdájú ọ̀run lóore fún ọ ju ayé.

وَلَسَوۡفَ يُعۡطِيكَ رَبُّكَ فَتَرۡضَىٰٓ ٥

Walasawfa yu'tīka rabbuka fatardā

Dájúdájú láìpẹ́ Olúwa rẹ máa fún ọ ní (oore púpọ̀ ní ọ̀run). Nítorí náà, o sì máa yọ́nú sí i.

أَلَمۡ يَجِدۡكَ يَتِيمٗا فَـَٔاوَىٰ ٦

Alam yajidka yatīman fa'āwā

Ṣé (Allāhu) kò rí ọ ní ọmọ-òrukàn ni? Ó sì fún ọ ní ibùgbé.

وَوَجَدَكَ ضَآلّٗا فَهَدَىٰ ٧

Wawajadaka dāllan fahadā

Ó sì rí ọ ní aláìmọ̀nà (ìyẹn ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ ìmísí). Ó sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́.1

وَوَجَدَكَ عَآئِلٗا فَأَغۡنَىٰ ٨

Wawajadaka 'ā'ilan fa aghnā

Ó tún rí ọ ní aláìní, Ó sì rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀.

فَأَمَّا ٱلۡيَتِيمَ فَلَا تَقۡهَرۡ ٩

Fa ammal-yatīma falā taqhar

Nítorí náà, ní ti ọmọ-òrukàn, má ṣe jẹ gàba (lé e lórí).

وَأَمَّا ٱلسَّآئِلَ فَلَا تَنۡهَرۡ ١٠

Wa ammas-sā'ila falā tanhar

Ní ti alágbe, má sì ṣe jágbe (mọ́ ọn).

وَأَمَّا بِنِعۡمَةِ رَبِّكَ فَحَدِّثۡ ١١

Wa ammā bini'mati rabbika fahaddith

Ní ti ìdẹ̀ra Olúwa rẹ, sọ ọ́ jáde.

Àwọn nọ́mbà àlàyé ìsàlẹ̀ máa ń mú ọ lọ sí ojú-ewé aaya náà, níbi tí àlàyé olùtúmọ̀ wà.

Kíkà ní lẹ́tà Látìn jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkà tí Qabas kọ láti inú èdè Lárúbáwá. Kọ́ àwọn lẹ́tà Lárúbáwá àti tajwīd fún ìpè tó péye.

Àwọn ìbéèrè

Aaya mélòó ló wà nínú Suratu Ad-Duha?

Suratu Ad-Duha ní aaya 11. Òun ni sura nọ́mbà 93 nínú Al-Kurani.

Ṣé Suratu Ad-Duha jẹ́ Makkiyya tàbí Madaniyya?

Suratu Ad-Duha jẹ́ sura Makkiyya.

Juz wo ni Suratu Ad-Duha wà?

Suratu Ad-Duha wà nínú Juz 30.

Ṣé mo lè gbọ́ Suratu Ad-Duha?

Bẹ́ẹ̀ni. Tẹ Bẹ̀rẹ̀ ní òkè ojú-ewé yìí, tàbí bẹ̀rẹ̀ láti aaya èyíkéyìí. Àpù Qabas tún jẹ́ kí o gbà á sílẹ̀ láti gbọ́ ọ láìsí ayélujára.