Suratu Al-Ma'un الماعون

Ìtumọ̀: Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

أَرَءَيۡتَ ٱلَّذِي يُكَذِّبُ بِٱلدِّينِ ١

Ara'aytal-ladhī yukaddhibu bid-dīn

Sọ fún mi nípa ẹni tó ń pe Ọjọ́ Ẹ̀san ní irọ́!

فَذَٰلِكَ ٱلَّذِي يَدُعُّ ٱلۡيَتِيمَ ٢

Fadhālikal-ladhī yadu''ul-yatīm

Ìyẹn ni ẹni tó ń lé ọmọ-òrukàn dànù.

وَلَا يَحُضُّ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلۡمِسۡكِينِ ٣

Walā yahuddu 'alā ta'āmil-miskīn

Kò sì níí gbìyànjú láti bọ́ mẹ̀kúnnù.

فَوَيۡلٞ لِّلۡمُصَلِّينَ ٤

Fawaylul lil-musallīn

Ègbé ni fún àwọn (mùnááfìkí) tó ń kírun;1

ٱلَّذِينَ هُمۡ عَن صَلَاتِهِمۡ سَاهُونَ ٥

Alladhīna hum 'an salātihim sāhūn

àwọn tó ń gbàgbé láti kírun wọn ní àsìkò rẹ̀;

ٱلَّذِينَ هُمۡ يُرَآءُونَ ٦

Alladhīna hum yurā'ūn

àwọn tó ń ṣe ṣekárími;

وَيَمۡنَعُونَ ٱلۡمَاعُونَ ٧

Wayamna'ūnal-mā'ūn

àti pé wọ́n ń hánnà ohun èlò (fún àwọn ènìyàn).

Àwọn nọ́mbà àlàyé ìsàlẹ̀ máa ń mú ọ lọ sí ojú-ewé aaya náà, níbi tí àlàyé olùtúmọ̀ wà.

Kíkà ní lẹ́tà Látìn jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkà tí Qabas kọ láti inú èdè Lárúbáwá. Kọ́ àwọn lẹ́tà Lárúbáwá àti tajwīd fún ìpè tó péye.

Àwọn ìbéèrè

Aaya mélòó ló wà nínú Suratu Al-Ma'un?

Suratu Al-Ma'un ní aaya 7. Òun ni sura nọ́mbà 107 nínú Al-Kurani.

Ṣé Suratu Al-Ma'un jẹ́ Makkiyya tàbí Madaniyya?

Suratu Al-Ma'un jẹ́ sura Makkiyya.

Juz wo ni Suratu Al-Ma'un wà?

Suratu Al-Ma'un wà nínú Juz 30.

Ṣé mo lè gbọ́ Suratu Al-Ma'un?

Bẹ́ẹ̀ni. Tẹ Bẹ̀rẹ̀ ní òkè ojú-ewé yìí, tàbí bẹ̀rẹ̀ láti aaya èyíkéyìí. Àpù Qabas tún jẹ́ kí o gbà á sílẹ̀ láti gbọ́ ọ láìsí ayélujára.