Adua kí a tó jẹun (Bismillah)

Ohun tí a ń sọ kí a tó jẹun, àti ìdí tí a fi ń dárúkọ Ọlọ́hun lórí oúnjẹ.

1 Ẹ̀ẹ̀kan

بِسْمِ اللَّهِ

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Umar ọmọ Abu Salama- ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo jẹ ọmọdekunrin ni abẹ itọju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ati pe ọwọ mi o si duro si oju kan ninu abọ, ni Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ fun mi pé: «Irẹ ọmọdekunrin yii, darukọ Ọlọhun, ki o si jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ, ki o si tun jẹ ninu nkan ti o sunmọ ọ»

Ìyẹn o wa yẹ ni ìṣesí ounjẹ mii lẹyin igba naa.

Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Umar ọmọ Abu Salamah- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji -, ọmọ iyawo anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti n ṣe ummu salamah - ki Ọlọhun yọnu si i - o si wa ni abẹ itọju rẹ ati amojuto rẹ -, n sọ pé òun jẹ ẹni ti o maa n gbe ọwọ rẹ kaakiri ẹgbẹẹgbẹ abọ ni asiko ounjẹ, nitori naa Anabi - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa kọ ọ ni awọn ẹkọ mẹta ninu awọn ẹkọ jijẹ:

Alakọkọọ rẹ ni: Gbólóhùn "BismilLah" ni ibẹrẹ ounjẹ.

Ati pe ẹlẹẹkeji ni: jíjẹ ounjẹ pẹlu ọwọ ọtun.

Ati pe ẹlẹẹkẹta rẹ ni: Jijẹ nibi ẹgbẹ ti o ba sunmọ ọn ninu oúnjẹ.

Àwọn àǹfààní

  • Ninu awọn ẹkọ jíjẹ ati mimu ni didarukọ Ọlọhun ni ibẹrẹ rẹ.
  • Kikọ awọn ọmọde ni awọn ẹkọ, agaga julọ ẹni ti o ba wa ni abẹ itọju eeyan.
  • Ṣiṣe idẹkun Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ati gbigba aaye igbaaya rẹ nibi fifi imọ mọ awọn ọmọde ati kikọ wọn ni ẹkọ.
  • Ninu awọn ẹkọ ounjẹ jíjẹ ni imaa jẹ ninu nkan ti o ba sunmọ eeyan, ayaafi ti o ba jẹ awọn iran orisirisi, nigba naa o le mu ninu rẹ.
  • Idunnimọ awọn saabe pẹlu nkan ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ba fi kọ wọn, wọn mu iyẹn jade lati ibi ọ̀rọ̀ Umar ti o sọ pe: Ìṣesí mi o wa yẹ lori ìyẹn lẹyin igba naa.

Kà á lórí HadeethEnc.com

2 Ẹ̀ẹ̀kan

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Jabir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- pe o gbọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n sọ pé: "Ti ọkùnrin ba wọ inu ile rẹ, ti o wa ranti Ọlọhun nigba ìwọlé rẹ ati nibi oúnjẹ rẹ, Shaitan maa sọ pé: Ko si ibusun fun yin ko si si oúnjẹ alẹ naa, ti o ba wa wọle, ti ko ṣe iranti Ọlọhun nigba ìwọlé rẹ, Shaitan maa sọ pé: Ẹ ti ri ibùsùn, ti ko ba ti dárúkọ Ọlọhun nibi oúnjẹ rẹ, o maa sọ pe: Ẹ ti ri ibusun ati oúnjẹ alẹ".

Muslim gba a wa Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pàṣẹ pẹlu riranti Ọlọhun nigba wiwọ inu ile ati ṣíwájú jijẹ oúnjẹ, ti o ba ranti Ọlọhun pẹlu sisọ pe: (Bismillah) nigba ti o ba wọ inu ile rẹ ati ìbẹ̀rẹ̀ jijẹ oúnjẹ rẹ, Shaitan maa sọ fun awọn oluranlọwọ rẹ pé: Ko si ipin fun yin lati sun tabi lati jẹun alẹ ninu ile yii ti ẹni ti o ni i ti wa iṣọra kuro lọdọ yin pẹlu riranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-. Ṣugbọn ti ọkùnrin ba wọ ile rẹ ti ko ranti Ọlọhun nigba ìwọlé rẹ tabi nigba jijẹ oúnjẹ rẹ, Shaitan maa sọ fun awọn oluranlọwọ rẹ pe wọn ti ri ibusun ati oúnjẹ alẹ ninu ile yii.

Àwọn àǹfààní

  • Ṣíṣe iranti Ọlọhun nigba wiwọ inu ile ati oúnjẹ ni nnkan ti a fẹ, nitori pe Shaitan maa n gbe inu awọn ile, ti o si maa n jẹ oúnjẹ awọn ara ile ti wọn ko ba dárúkọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.
  • Shaitan maa n ṣọ ọmọ Adam nibi iṣẹ rẹ ati ìwà rẹ ati nibi awọn àlámọ̀rí rẹ pata, ti o ba gbagbe lati ranti Ọlọhun, ọwọ rẹ maa tẹ erongba rẹ lọdọ rẹ.
  • Iranti maa n le Shaitan dànù.
  • Gbogbo èṣù kọọkan lo ni awọn ọmọlẹyin rẹ ati awọn ààyò rẹ ti wọn maa n dunnu pẹlu ọrọ rẹ ti wọn si n tẹle àṣẹ rẹ.

Kà á lórí HadeethEnc.com

Àwọn ìbéèrè

Kí ló wà lórí ojú-ìwé yìí?

Adua kí a tó jẹun: ọ̀kọ̀ọ̀kan ní èdè Lárúbáwá, pẹ̀lú ìtumọ̀ rẹ̀, hadiisi tí ó ti wá, ipò rẹ̀ àti àlàyé.

Níbo ni àwọn ìtumọ̀ ti wá?

Láti HadeethEnc.com, Ìwé Ìmọ̀ Àwọn Hadiisi Ànábì Tí A Túmọ̀. A ń fi hadiisi kọ̀ọ̀kan hàn gẹ́lẹ́ bí wọ́n ṣe tẹ̀ ẹ́ jáde, pẹ̀lú orísun àti ipò rẹ̀, àti ìjápọ̀ sí ojúlówó rẹ̀.

Ṣé mo lè gba ìrántí ojoojúmọ́?

Bẹ́ẹ̀ni. Ohun èlò Qabas ọ̀fẹ́ fún Android máa ń rán ọ létí zikiri òwúrọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ lójoojúmọ́, ó sì ní ẹ̀rọ ìkà kan náà.