Ẹ̀kọ́ 5 nínú 5
Kí ni Hajj?
Láti inú Al-Qur'ān
إِنَّ أَوَّلَ بَيۡتٖ وُضِعَ لِلنَّاسِ لَلَّذِي بِبَكَّةَ مُبَارَكٗا وَهُدٗى لِّلۡعَٰلَمِينَ ﴿٩٦﴾ فِيهِ ءَايَٰتُۢ بَيِّنَٰتٞ مَّقَامُ إِبۡرَٰهِيمَۖ وَمَن دَخَلَهُۥ كَانَ ءَامِنٗاۗ وَلِلَّهِ عَلَى ٱلنَّاسِ حِجُّ ٱلۡبَيۡتِ مَنِ ٱسۡتَطَاعَ إِلَيۡهِ سَبِيلٗاۚ وَمَن كَفَرَ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَنِيٌّ عَنِ ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿٩٧﴾
Dájúdájú ilé àkọ́kọ́ tí A fi lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn ni èyí tí ó wà ní Bakkah. (Ó jẹ́ ilé) ìbùkún àti ìmọ̀nà fún gbogbo ẹ̀dá. Àwọn àmì tó yanjú wà nínú rẹ̀; ibùdúró (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ inú rẹ̀ ti di ẹni ìfàyàbalẹ̀. Allāhu ṣe àbẹ̀wò sí Ilé náà ní dandan fún àwọn ènìyàn, tó lágbára ọ̀nà tí ó máa gbà débẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì gbàgbọ́, dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀ tí kò bùkátà sí gbogbo ẹ̀dá.
وَأَذِّن فِي ٱلنَّاسِ بِٱلۡحَجِّ يَأۡتُوكَ رِجَالٗا وَعَلَىٰ كُلِّ ضَامِرٖ يَأۡتِينَ مِن كُلِّ فَجٍّ عَمِيقٖ ﴿٢٧﴾
Kí o sì pe ìpè fún àwọn ènìyàn fún iṣẹ́ Hajj. Wọn yóò wá bá ọ pẹ̀lú ìrìn ẹsẹ̀ àti lórí gbogbo n̄ǹkan ìgùn, wọn yóò máa wá láti àwọn ọ̀nà jíjìn
Láti inú Sunnah
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Mo gbọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, ti n sọ pe: "Ẹnikẹni ti o ba ṣe Hajj nitori ti Ọlọhun, tí kò ba obinrin lopọ, tí kò sì rú ofin Ọlọhun, onitọhun yoo pada sile gẹgẹ bi ọjọ ti iya rẹ̀ bi i."
Àlàyé
Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, n ṣe alaye pé ẹnikẹni ti o ba ṣe Hajj nitori ti Ọlọhun Ọba Aleke ọla, tí kò sì bá obinrin lopọ, itumọ ibalopọ ni ibasun ati awọn ohun ti o ṣiwaju rẹ̀ gẹgẹ bii ifẹnukonu ati ifarakanra, wọn si maa n túmọ̀ rẹ̀ si ọrọ buruku, tí kò sì rú ofin Ọlọhun, nípa dídá ẹ̀ṣẹ̀ àti ṣíṣe aburú. Ninu rírú ofin Ọlọhun ni ṣiṣe awọn èèwọ̀ gbígbé harami, yoo pada sile lati Hajji rẹ̀ ní ẹniti Ọlọhun ti darijin, gẹgẹ bi wọn ti n bi ọmọde lai ni ẹṣẹ kankan lọrun.
Ìrìn-àjò ti parí
Ẹ kú iṣẹ́!
Òpó márùn-ún Ìsìlámù
Ìrìn-àjò 1 nínú 6 ti parí
Bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò tó kànOhun tí àwọn Mùsùlùmí gbàgbọ́