إِنَّ أَوَّلَ بَيۡتٖ وُضِعَ لِلنَّاسِ لَلَّذِي بِبَكَّةَ مُبَارَكٗا وَهُدٗى لِّلۡعَٰلَمِينَ ٩٦
Inna awwala baytin wudi'a lin-nāsi lalladhī bibakkata mubārakan wahudal lil-'ālamīn
Dájúdájú ilé àkọ́kọ́ tí A fi lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn ni èyí tí ó wà ní Bakkah.1 (Ó jẹ́ ilé) ìbùkún àti ìmọ̀nà fún gbogbo ẹ̀dá.
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Bakkah jẹ́ orúkọ mìíràn fún Mọkkah. Ìtúmọ̀ Bakkah ni ìdìfúnǹfún. Ìdìfúnǹfún yìí kò sì lè má ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣe tawāf lọ́wọ́ nínú Haram Mọkkah.