Adua nígbà tí a bá sín àti èsì rẹ̀

Ohun tí ẹni tí ó sín máa ń sọ, àti ohun tí ẹni tí ó gbọ́ máa ń fèsì.

1 Ẹ̀ẹ̀kan

Ìtumọ̀ àti orísun

Lati ọdọ Abu Hurayra– ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba sin, o maa n gbe ọwọ rẹ- tabi aṣọ rẹ- si ẹnu rẹ, ti o maa fi rẹ ohun rẹ nilẹ.

Abu Daud ati Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa Ipò: O ni alaafia

Àlàyé

Ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba sin, o maa n:

Akọkọ: O maa gbe ọwọ rẹ, tabi aṣọ rẹ sori ẹnu rẹ; ki nnkan kan ma baa jade lati ẹnu rẹ tabi imu rẹ ti o le ko suta ba alabajokoo rẹ.

Ikeji: O maa n rẹ ohun rẹ nilẹ, ko si nii gbe e soke.

Àwọn àǹfààní

  • Alaye ilana rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi sinsin ati iwo awokọṣe rẹ nibi ìyẹn.
  • Ṣíṣe gbigbe aṣọ tabi inuju ati nnkan ti o jọ ọ sori ẹnu rẹ ni nnkan ti a fẹ ati sori imu rẹ ki nnkan kan ti o le ko suta ba alabajokoo rẹ ma baa jade lati ọdọ rẹ nigba ti o ba sin.
  • Irẹ ohun sinsin silẹ jẹ nnkan ti a fẹ, ó wa ninu pipe ẹkọ, ninu awọn iwa ti o daa si ni.

Kà á lórí HadeethEnc.com

Àwọn ìbéèrè

Kí ló wà lórí ojú-ìwé yìí?

Adua sísín: ọ̀kọ̀ọ̀kan ní èdè Lárúbáwá, pẹ̀lú ìtumọ̀ rẹ̀, hadiisi tí ó ti wá, ipò rẹ̀ àti àlàyé.

Níbo ni àwọn ìtumọ̀ ti wá?

Láti HadeethEnc.com, Ìwé Ìmọ̀ Àwọn Hadiisi Ànábì Tí A Túmọ̀. A ń fi hadiisi kọ̀ọ̀kan hàn gẹ́lẹ́ bí wọ́n ṣe tẹ̀ ẹ́ jáde, pẹ̀lú orísun àti ipò rẹ̀, àti ìjápọ̀ sí ojúlówó rẹ̀.

Ṣé mo lè gba ìrántí ojoojúmọ́?

Bẹ́ẹ̀ni. Ohun èlò Qabas ọ̀fẹ́ fún Android máa ń rán ọ létí zikiri òwúrọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ lójoojúmọ́, ó sì ní ẹ̀rọ ìkà kan náà.