Suratu Al-Kafirun الكافرون

Ìtumọ̀: Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

قُلۡ يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡكَٰفِرُونَ ١

Qul yā'ayyuhal-kāfirūn

Sọ pé: “Ẹ̀yin aláìgbàgbọ́,

لَآ أَعۡبُدُ مَا تَعۡبُدُونَ ٢

Lā a'budu mā ta'budūn

Èmi kò níí jọ́sìn fún ohun tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún.

وَلَآ أَنتُمۡ عَٰبِدُونَ مَآ أَعۡبُدُ ٣

Walā antum 'ābidūna mā a'bud

Ẹ̀yin náà kò jọ́sìn fún Ẹni tí mò ń jọ́sìn fún.

وَلَآ أَنَا۠ عَابِدٞ مَّا عَبَدتُّمۡ ٤

Walā ana 'ābidum mā 'abattum

Èmi kò níí jọ́sìn fún ohun tí ẹ jọ́sìn fún sẹ́.

وَلَآ أَنتُمۡ عَٰبِدُونَ مَآ أَعۡبُدُ ٥

Walā antum 'ābidūna mā a'bud

Ẹ̀yin náà kò kú jọ́sìn fún Ẹni tí mò ń jọ́sìn fún.

لَكُمۡ دِينُكُمۡ وَلِيَ دِينِ ٦

Lakum dīnukum waliya dīn

Tiyín ni ẹ̀sìn yín, tèmi sì ni ẹ̀sìn mi.”

Kíkà ní lẹ́tà Látìn jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkà tí Qabas kọ láti inú èdè Lárúbáwá. Kọ́ àwọn lẹ́tà Lárúbáwá àti tajwīd fún ìpè tó péye.

Àwọn ìbéèrè

Aaya mélòó ló wà nínú Suratu Al-Kafirun?

Suratu Al-Kafirun ní aaya 6. Òun ni sura nọ́mbà 109 nínú Al-Kurani.

Ṣé Suratu Al-Kafirun jẹ́ Makkiyya tàbí Madaniyya?

Suratu Al-Kafirun jẹ́ sura Makkiyya.

Juz wo ni Suratu Al-Kafirun wà?

Suratu Al-Kafirun wà nínú Juz 30.

Ṣé mo lè gbọ́ Suratu Al-Kafirun?

Bẹ́ẹ̀ni. Tẹ Bẹ̀rẹ̀ ní òkè ojú-ewé yìí, tàbí bẹ̀rẹ̀ láti aaya èyíkéyìí. Àpù Qabas tún jẹ́ kí o gbà á sílẹ̀ láti gbọ́ ọ láìsí ayélujára.