Suratu Al-Fil الفيل

Ìtumọ̀: Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

أَلَمۡ تَرَ كَيۡفَ فَعَلَ رَبُّكَ بِأَصۡحَٰبِ ٱلۡفِيلِ ١

Alam tara kayfa fa'ala rabbuka bi ashābil-fīl

Ṣé o kò wòye sí bí Olúwa rẹ ti ṣe ọ̀rọ̀ ìjọ elérin ni?

أَلَمۡ يَجۡعَلۡ كَيۡدَهُمۡ فِي تَضۡلِيلٖ ٢

Alam yaj'al kaydahum fī tadlīl

Ṣé kò sọ ète wọn di òfo àti anù bí?

وَأَرۡسَلَ عَلَيۡهِمۡ طَيۡرًا أَبَابِيلَ ٣

Wa arsala 'alayhim tayran abābīl

Ó sì rán àwọn ẹyẹ níkọ̀níkọ̀ sí wọn.

تَرۡمِيهِم بِحِجَارَةٖ مِّن سِجِّيلٖ ٤

Tarmīhim bihijāratim min sijjīl

Wọ́n ń jù wọ́n ní òkúta amọ̀ (tó ti gbaná sára).

فَجَعَلَهُمۡ كَعَصۡفٖ مَّأۡكُولِۭ ٥

Faja'alahum ka'asfim ma'kūl

Ó sì sọ wọ́n di bíi pòpórò gbígbẹ tí ẹranko jẹ lájẹdàsílẹ̀.

Kíkà ní lẹ́tà Látìn jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkà tí Qabas kọ láti inú èdè Lárúbáwá. Kọ́ àwọn lẹ́tà Lárúbáwá àti tajwīd fún ìpè tó péye.

Àwọn ìbéèrè

Aaya mélòó ló wà nínú Suratu Al-Fil?

Suratu Al-Fil ní aaya 5. Òun ni sura nọ́mbà 105 nínú Al-Kurani.

Ṣé Suratu Al-Fil jẹ́ Makkiyya tàbí Madaniyya?

Suratu Al-Fil jẹ́ sura Makkiyya.

Juz wo ni Suratu Al-Fil wà?

Suratu Al-Fil wà nínú Juz 30.

Ṣé mo lè gbọ́ Suratu Al-Fil?

Bẹ́ẹ̀ni. Tẹ Bẹ̀rẹ̀ ní òkè ojú-ewé yìí, tàbí bẹ̀rẹ̀ láti aaya èyíkéyìí. Àpù Qabas tún jẹ́ kí o gbà á sílẹ̀ láti gbọ́ ọ láìsí ayélujára.