Ẹ̀kọ́ 10 nínú 11
Kí nìdí tí Allāhu fi ń jẹ́ kí ìnira àti ìyà ṣẹlẹ̀?
Ìdáhùn ní ṣókí
Ìgbésí ayé yìí jẹ́ àdánwò. Allāhu máa ń dán àwọn ènìyàn wò pẹ̀lú ìnira àti ìrọ̀rùn láti fi hàn ẹni tó ní sùúrù àti ẹni tó ń ṣe rere. Fún onígbàgbọ́, kò sí ìrora kan tó ń lọ lásán: kódà ẹ̀gún tó gún un máa ń pa díẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ rẹ́, Allāhu sì ṣèlérí ẹ̀san ńlá àti àánú fún àwọn tó ní sùúrù tí wọ́n sì ń padà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Al-Qur'ān tún ṣèlérí pé ìrọ̀rùn ń bẹ pẹ̀lú ìnira, òdodo pípé sì ń dúró de ènìyàn ní ayé tó ń bọ̀.
Qabas ló kọ ọ́, a sì ṣàyẹ̀wò rẹ̀ pẹ̀lú Al-Mukhtasar fī Tafsīr al-Qur'ān al-Karīm, Tafsīr Ibn Kathīr àti àwọn àlàyé HadeethEnc.com.
Láti inú Al-Qur'ān
وَلَنَبۡلُوَنَّكُم بِشَيۡءٖ مِّنَ ٱلۡخَوۡفِ وَٱلۡجُوعِ وَنَقۡصٖ مِّنَ ٱلۡأَمۡوَٰلِ وَٱلۡأَنفُسِ وَٱلثَّمَرَٰتِۗ وَبَشِّرِ ٱلصَّٰبِرِينَ ﴿١٥٥﴾ ٱلَّذِينَ إِذَآ أَصَٰبَتۡهُم مُّصِيبَةٞ قَالُوٓاْ إِنَّا لِلَّهِ وَإِنَّآ إِلَيۡهِ رَٰجِعُونَ ﴿١٥٦﴾ أُوْلَٰٓئِكَ عَلَيۡهِمۡ صَلَوَٰتٞ مِّن رَّبِّهِمۡ وَرَحۡمَةٞۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُهۡتَدُونَ ﴿١٥٧﴾
Dájúdájú A ó máa dán-an yín wò pẹ̀lú kiní kan látara ẹ̀rù, ebi, àdínkù nínú àwọn dúkìá, àwọn ẹ̀mí àti àwọn èso. Kí o sì fún àwọn onísùúrù ní ìró ìdùnnú. Àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí àdánwò kan bá kàn wọ́n, wọ́n á sọ pé: “Dájúdájú Allāhu l’Ó ni àwa; dájúdájú ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àwa yóò padà sí.” Àwọn wọ̀nyẹn ni àforíjìn àti ìkẹ́ yó máa bẹ fún láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùmọ̀nà.
أَحَسِبَ ٱلنَّاسُ أَن يُتۡرَكُوٓاْ أَن يَقُولُوٓاْ ءَامَنَّا وَهُمۡ لَا يُفۡتَنُونَ ﴿٢﴾ وَلَقَدۡ فَتَنَّا ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۖ فَلَيَعۡلَمَنَّ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ صَدَقُواْ وَلَيَعۡلَمَنَّ ٱلۡكَٰذِبِينَ ﴿٣﴾
Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn lérò pé A óò fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ pé: “A gbàgbọ́”, tí A ò sì níí dán wọn wò? A kúkú ti dán àwọn tó ṣíwájú wọn wò. Nítorí náà, dájúdájú Allāhu máa ṣàfi hàn àwọn tó sọ òdodo. Dájúdájú Ó sì máa ṣàfi hàn àwọn òpùrọ́.
فَإِنَّ مَعَ ٱلۡعُسۡرِ يُسۡرًا ﴿٥﴾ إِنَّ مَعَ ٱلۡعُسۡرِ يُسۡرٗا ﴿٦﴾
Nítorí náà, dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira. Dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira sẹ́.
Láti inú Sunnah
Lati ọdọ Abu Sa'eed Al-Khudriy ati lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Nnkan kan ko nii ṣẹlẹ̀ si Musulumi ninu wahala ati aisan ati ironu ati ibanujẹ ati suta ati ironu ati ki ẹgun gun un afi ki Ọlọhun ba a fi pa awọn aṣiṣe rẹ rẹ".
Àlàyé
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju ohunkóhun tí ó bá ṣẹlẹ̀ sí Mùsùlùmí, bii aisan ati ironu ati ibanujẹ ati ajalu ati ile koko ati ipaya ati ebi- koda ki o jẹ ẹgun ni o gun un ti o wa n ko inira ba a-, ìyẹn maa jẹ ipa ẹṣẹ rẹ fun awọn ẹṣẹ rẹ ati awọn aṣiṣe rẹ.