Ṣàwárí Ìsìlámù

Ẹ̀kọ́ 7 nínú 8

Kí ló ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú?

Láti inú Al-Qur'ān

كُلُّ نَفۡسٖ ذَآئِقَةُ ٱلۡمَوۡتِۗ وَإِنَّمَا تُوَفَّوۡنَ أُجُورَكُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۖ فَمَن زُحۡزِحَ عَنِ ٱلنَّارِ وَأُدۡخِلَ ٱلۡجَنَّةَ فَقَدۡ فَازَۗ وَمَا ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَآ إِلَّا مَتَٰعُ ٱلۡغُرُورِ ﴿١٨٥﴾

Gbogbo ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ló máa tọ́ ikú wò. A ó sì san yín ní ẹ̀san yín ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí A bá mú jìnnà tefé sí Iná, tí A sì mú wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ó kúkú ti jèrè. Kí sì ni ìgbésí ayé bí kò ṣe ìgbádùn ẹ̀tàn.

Al-Imran 3:185Kà á nínú Al-Qur'ān

يَوۡمَئِذٖ يَصۡدُرُ ٱلنَّاسُ أَشۡتَاتٗا لِّيُرَوۡاْ أَعۡمَٰلَهُمۡ ﴿٦﴾ فَمَن يَعۡمَلۡ مِثۡقَالَ ذَرَّةٍ خَيۡرٗا يَرَهُۥ ﴿٧﴾ وَمَن يَعۡمَلۡ مِثۡقَالَ ذَرَّةٖ شَرّٗا يَرَهُۥ ﴿٨﴾

Ní ọjọ́ yẹn, àwọn ènìyàn yóò máa gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ nítorí kí wọ́n lè fi àwọn iṣẹ́ wọn hàn wọ́n. Nítorí náà, ẹni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i. Ẹni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ aburú ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i.

Az-Zalzalah 99:6-8Kà á nínú Al-Qur'ān

وَٱتَّقُواْ يَوۡمٗا تُرۡجَعُونَ فِيهِ إِلَى ٱللَّهِۖ ثُمَّ تُوَفَّىٰ كُلُّ نَفۡسٖ مَّا كَسَبَتۡ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ ﴿٢٨١﴾

Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí wọ́n máa da yín padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, wọ́n máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ (nípa) ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.

Al-Baqarah 2:281Kà á nínú Al-Qur'ān

Láti inú Sunnah

Lati ọdọ Jabir- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Arakunrin kan wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, ki ni nnkan meji naa ti wọn maa n sọ nǹkan di dandan? O sọ pe: “Ẹni ti o ba ku ti ko da ẹbọ kankan pọ mọ Ọlọhun yoo wọ alujanna, ẹni ti o ba si ku ti o da ẹbọ pọ mọ Ọlọhun yoo wọ ina".

Muslim gba a wa O ni alaafia HadeethEnc.com
Àlàyé

Arakunrin kan beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa pe iroyin meji naa wo ni yoo sọ wiwọ alujanna di dandan, ati ti yoo sọ wiwọ ina di dandan? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- da a lohun pe: Dajudaju ìròyìn ti yoo sọ wiwọ alujanna di dandan ni ki ọmọniyan ku ti o si n jọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo ti ko da ẹbọ kankan pọ mọ Ọn, Ati pe iroyin ti yoo sọ wiwọ ina di dandan ni ki ọmọniyan ku ti o si n da ẹbọ pọ mọ Ọlọhun ti yoo wa orogun ati olubakẹgbẹ fun Ọlọhun nibi ìní ẹtọ si ìjọsìn Rẹ tabi nibi jijẹ Oluwa Rẹ tabi nibi awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ.

Gbogbo ẹ̀kọ́