Suratu Al-'Alaq العلق

Ìtumọ̀: Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

ٱقۡرَأۡ بِٱسۡمِ رَبِّكَ ٱلَّذِي خَلَقَ ١

Iqra' bismi rabbikal-ladhī khalaq

Ké (al-Ƙur’ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá.

خَلَقَ ٱلۡإِنسَٰنَ مِنۡ عَلَقٍ ٢

Khalaqal-insāna min 'alaq

Ó ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì.

ٱقۡرَأۡ وَرَبُّكَ ٱلۡأَكۡرَمُ ٣

Iqra' warabbukal-akram

Ké e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ.

ٱلَّذِي عَلَّمَ بِٱلۡقَلَمِ ٤

Alladhī 'allama bil-qalam

Ẹni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn.

عَلَّمَ ٱلۡإِنسَٰنَ مَا لَمۡ يَعۡلَمۡ ٥

'Allamal-insāna mā lam ya'lam

Ó fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n.

كَلَّآ إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لَيَطۡغَىٰٓ ٦

Kallā innal-insāna layatghā

Ní ti òdodo, dájúdájú ènìyàn kúkú ń tayọ ẹnu-ààlà

أَن رَّءَاهُ ٱسۡتَغۡنَىٰٓ ٧

Ar ra'āhustaghnā

nítorí pé ó rí ara rẹ̀ ní ọlọ́rọ̀.

إِنَّ إِلَىٰ رَبِّكَ ٱلرُّجۡعَىٰٓ ٨

Inna ilā rabbikar-ruj'ā

Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni àbọ̀ ẹ̀dá.

أَرَءَيۡتَ ٱلَّذِي يَنۡهَىٰ ٩

Ara'aytal-ladhī yanhā

Sọ fún mi nípa ẹni tó ń kọ̀

عَبۡدًا إِذَا صَلَّىٰٓ ١٠

'Abdan idhā sallā

fún ẹrúsìn kan nígbà tí (ẹrúsìn náà) kírun!

أَرَءَيۡتَ إِن كَانَ عَلَى ٱلۡهُدَىٰٓ ١١

Ara'ayta in kāna 'alal-hudā

Sọ fún mi (nípa ẹ̀san rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó wà lórí ìmọ̀nà (’Islām)

أَوۡ أَمَرَ بِٱلتَّقۡوَىٰٓ ١٢

Aw amara bit-taqwā

tàbí pé ó pàṣẹ ìbẹ̀rù (Allāhu)!

أَرَءَيۡتَ إِن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰٓ ١٣

Ara'ayta in kaddhaba watawallā

Sọ fún mi (nípa ìyà rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i?

أَلَمۡ يَعۡلَم بِأَنَّ ٱللَّهَ يَرَىٰ ١٤

Alam ya'lam bi annallāha yarā

Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń rí (òun ni?)

كَلَّا لَئِن لَّمۡ يَنتَهِ لَنَسۡفَعَۢا بِٱلنَّاصِيَةِ ١٥

Kallā la il lam yantahi lanasfa'ā bin-nāsiyah

Rárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ọ̀tá Allāhu ṣe rò ó sí.1) Dájúdájú tí kò bá jáwọ́ (níbi dídí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lọ́wọ́), dájúdájú A máa fi àásó orí2 rẹ̀ wọ́ ọ (sínú Iná);

نَاصِيَةٖ كَٰذِبَةٍ خَاطِئَةٖ ١٦

Nāsiyatin kādhibatin khāti'ah

àásó orí òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.

فَلۡيَدۡعُ نَادِيَهُۥ ١٧

Falyad'u nādiyah

Nítorí náà, kí ó pe àwọn olùbájókòó rẹ̀.

سَنَدۡعُ ٱلزَّبَانِيَةَ ١٨

Sanad'uz-zabāniyah

Àwa máa pe àwọn mọlāika ẹ̀ṣọ́ Iná.

كَلَّا لَا تُطِعۡهُ وَٱسۡجُدۡۤ وَٱقۡتَرِب۩ ١٩

Kallā lā tuti'hu wasjud waqtarib

Rárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ó ṣe ń sọ nípa Wa). Má ṣe tẹ̀lé tirẹ̀. Forí kanlẹ̀ (kí o kírun), kí o sì súnmọ́ (Allāhu).

Àwọn nọ́mbà àlàyé ìsàlẹ̀ máa ń mú ọ lọ sí ojú-ewé aaya náà, níbi tí àlàyé olùtúmọ̀ wà.

Kíkà ní lẹ́tà Látìn jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkà tí Qabas kọ láti inú èdè Lárúbáwá. Kọ́ àwọn lẹ́tà Lárúbáwá àti tajwīd fún ìpè tó péye.

Àwọn aaya olókìkí

Àwọn ìbéèrè

Aaya mélòó ló wà nínú Suratu Al-'Alaq?

Suratu Al-'Alaq ní aaya 19. Òun ni sura nọ́mbà 96 nínú Al-Kurani.

Ṣé Suratu Al-'Alaq jẹ́ Makkiyya tàbí Madaniyya?

Suratu Al-'Alaq jẹ́ sura Makkiyya.

Juz wo ni Suratu Al-'Alaq wà?

Suratu Al-'Alaq wà nínú Juz 30.

Ṣé mo lè gbọ́ Suratu Al-'Alaq?

Bẹ́ẹ̀ni. Tẹ Bẹ̀rẹ̀ ní òkè ojú-ewé yìí, tàbí bẹ̀rẹ̀ láti aaya èyíkéyìí. Àpù Qabas tún jẹ́ kí o gbà á sílẹ̀ láti gbọ́ ọ láìsí ayélujára.