Ṣàwárí Ìsìlámù

Ẹ̀kọ́ 5 nínú 8

Ta ni Ànábì Muhammad?

Láti inú Al-Qur'ān

مَّا كَانَ مُحَمَّدٌ أَبَآ أَحَدٖ مِّن رِّجَالِكُمۡ وَلَٰكِن رَّسُولَ ٱللَّهِ وَخَاتَمَ ٱلنَّبِيِّـۧنَۗ وَكَانَ ٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٗا ﴿٤٠﴾

(Ànábì) Muhammad kì í ṣe bàbá ẹnì kan kan nínú àwọn ọkùnrin yín, ṣùgbọ́n (ó jẹ́) Òjíṣẹ́ Allāhu àti òpin àwọn Ànábì. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

Al-Ahzab 33:40Kà á nínú Al-Qur'ān

وَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ إِلَّا رَحۡمَةٗ لِّلۡعَٰلَمِينَ ﴿١٠٧﴾

A kò sì fi iṣẹ́ ìmísí rán ọ bí kò ṣe pé kí o lè jẹ́ ìkẹ́ fún gbogbo ẹ̀dá.

Al-Anbiya 21:107Kà á nínú Al-Qur'ān

وَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ إِلَّا كَآفَّةٗ لِّلنَّاسِ بَشِيرٗا وَنَذِيرٗا وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ ﴿٢٨﴾

A kò rán ọ níṣẹ́ àfi sí gbogbo ènìyàn pátápátá; (o jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀ ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.

Saba 34:28Kà á nínú Al-Qur'ān

وَإِنَّكَ لَعَلَىٰ خُلُقٍ عَظِيمٖ ﴿٤﴾

Dájúdájú ìwọ sì wà lórí ìwà ńlá (ìwà alápọ̀n-ọ́nlé).

Al-Qalam 68:4Kà á nínú Al-Qur'ān

Láti inú Sunnah

Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattab - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Mo gbọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí ń ṣo pé: "Ẹ má ṣe yìn mi jù gẹgẹ bi awọn Kristẹni ṣe yin ọmọ Maria jù; ẹrú Ọlọhun ni ẹmi n ṣe, nitori naa, ẹ wi pe: Ẹru Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ̀".

Bukhaariy gba a wa O ni alaafia HadeethEnc.com
Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n kọ̀ fun wa kuro nibi ìyinnijù ati ikọja aala ofin sharia nibi yiyin-in ati riroyin rẹ̀ pẹlu awọn iroyin Ọlọhun Ọba ati awọn iṣẹ tó jẹ́ ti Ọlọhun nikan ṣoṣo, tabi kí a sọ pé Anabi ní imọ kọ̀kọ̀, tabi ki a maa pe e papọ mọ Ọlọhun, gẹgẹ bi awọn Kristẹni ṣe ṣe pẹlu Isa ọmọ Maria - ki alaafia Ọlọhun maa ba a. Lẹyin naa, Anabi ṣalaye pé ẹru kan ninu awọn ẹru Ọlọhun ni oun, ó sì paṣẹ pé ki a maa sọ nipa oun bayii pé: Ẹru Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ̀.

Gbogbo ẹ̀kọ́