Suratu Al-Infitar الإنفطار

Ìtumọ̀: Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ

إِذَا ٱلسَّمَآءُ ٱنفَطَرَتۡ ١

Idhas-samā'unfatarat

Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,1

وَإِذَا ٱلۡكَوَاكِبُ ٱنتَثَرَتۡ ٢

Wa idhal-kawākibuntatharat

àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,

وَإِذَا ٱلۡبِحَارُ فُجِّرَتۡ ٣

Wa idhal-bihāru fujjirat

àti nígbà tí àwọn ibúdò bá ṣàn jára wọn,

وَإِذَا ٱلۡقُبُورُ بُعۡثِرَتۡ ٤

Wa idhal-qubūru bu'thirat

àti (nígbà tí A bá ta ilẹ̀ sókè), tí A sì mú àwọn òkú jáde (láàyè) láti inú àwọn sàréè,

عَلِمَتۡ نَفۡسٞ مَّا قَدَّمَتۡ وَأَخَّرَتۡ ٥

'Alimat nafsum mā qaddamat wa akkharat

(nígbà náà ni) ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò mọ ohun tí ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tí ó fi sẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).

يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡإِنسَٰنُ مَا غَرَّكَ بِرَبِّكَ ٱلۡكَرِيمِ ٦

Yā'ayyuhal-insānu mā gharraka birabbikal-karīm

Ìwọ ènìyàn, kí ni ó tàn ọ́ jẹ nípa Olúwa rẹ, Alápọ̀n-ọ́nlé,

ٱلَّذِي خَلَقَكَ فَسَوَّىٰكَ فَعَدَلَكَ ٧

Alladhī khalaqaka fasawwāka fa'adalak

Ẹni t’Ó ṣẹ̀dá rẹ? Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ní pípé. Ó sì mú ọ dọ́gba jalẹ̀ léèyàn.

فِيٓ أَيِّ صُورَةٖ مَّا شَآءَ رَكَّبَكَ ٨

Fī ayyi sūratim mā shā'a rakkabak

Ó to ẹ̀yà ara rẹ papọ̀ sínú èyíkéyìí àwòrán tí Ó fẹ́.

كَلَّا بَلۡ تُكَذِّبُونَ بِٱلدِّينِ ٩

Kallā bal tukaddhibūna bid-dīn

Rárá! Bí kò ṣe pé ẹ̀ ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́.

وَإِنَّ عَلَيۡكُمۡ لَحَٰفِظِينَ ١٠

Wa inna 'alaykum lahāfizīn

Dájúdájú àwọn ẹ̀ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ yín.

كِرَامٗا كَٰتِبِينَ ١١

Kirāman kātibīn

(Wọ́n jẹ́) alápọ̀n-ọ́nlé, òǹkọ̀wé-iṣẹ́ ẹ̀dá.

يَعۡلَمُونَ مَا تَفۡعَلُونَ ١٢

Ya'lamūna mā taf'alūn

Wọ́n mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

إِنَّ ٱلۡأَبۡرَارَ لَفِي نَعِيمٖ ١٣

Innal-abrāra lafī na'īm

Dájúdájú àwọn ẹni rere yóò kúkú wà nínú ìgbádùn.

وَإِنَّ ٱلۡفُجَّارَ لَفِي جَحِيمٖ ١٤

Wa innal-fujjāra lafī jahīm

Dájúdájú àwọn ẹni ibi yó sì kúkú wà nínú iná Jẹhīm.

يَصۡلَوۡنَهَا يَوۡمَ ٱلدِّينِ ١٥

Yaslawnahā yawmad-dīn

Wọn yóò wọ inú rẹ̀ ní Ọjọ́ ẹ̀san.

وَمَا هُمۡ عَنۡهَا بِغَآئِبِينَ ١٦

Wamā hum 'anhā bighā'ibīn

Wọn kò sì níí kúrò nínú rẹ̀.

وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا يَوۡمُ ٱلدِّينِ ١٧

Wamā adrāka mā yawmud-dīn

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?

ثُمَّ مَآ أَدۡرَىٰكَ مَا يَوۡمُ ٱلدِّينِ ١٨

Thumma mā adrāka mā yawmud-dīn

Lẹ́yìn náà, kí ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?

يَوۡمَ لَا تَمۡلِكُ نَفۡسٞ لِّنَفۡسٖ شَيۡـٔٗاۖ وَٱلۡأَمۡرُ يَوۡمَئِذٖ لِّلَّهِ ١٩

Yawma lā tamliku nafsul linafsin shay'an wal-amru yawma'idhi lillāh

(Ọjọ́ ẹ̀san ni) ọjọ́ tí ẹ̀mí kan kò níí kápá kiní kan fún ẹ̀mí kan. Gbogbo àṣẹ ọjọ́ yẹn sì ń jẹ́ ti Allāhu.

Àwọn nọ́mbà àlàyé ìsàlẹ̀ máa ń mú ọ lọ sí ojú-ewé aaya náà, níbi tí àlàyé olùtúmọ̀ wà.

Kíkà ní lẹ́tà Látìn jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkà tí Qabas kọ láti inú èdè Lárúbáwá. Kọ́ àwọn lẹ́tà Lárúbáwá àti tajwīd fún ìpè tó péye.

Àwọn ìbéèrè

Aaya mélòó ló wà nínú Suratu Al-Infitar?

Suratu Al-Infitar ní aaya 19. Òun ni sura nọ́mbà 82 nínú Al-Kurani.

Ṣé Suratu Al-Infitar jẹ́ Makkiyya tàbí Madaniyya?

Suratu Al-Infitar jẹ́ sura Makkiyya.

Juz wo ni Suratu Al-Infitar wà?

Suratu Al-Infitar wà nínú Juz 30.

Ṣé mo lè gbọ́ Suratu Al-Infitar?

Bẹ́ẹ̀ni. Tẹ Bẹ̀rẹ̀ ní òkè ojú-ewé yìí, tàbí bẹ̀rẹ̀ láti aaya èyíkéyìí. Àpù Qabas tún jẹ́ kí o gbà á sílẹ̀ láti gbọ́ ọ láìsí ayélujára.