Suratu Al-An'am, aaya 52

6:52

وَلَا تَطۡرُدِ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ رَبَّهُم بِٱلۡغَدَوٰةِ وَٱلۡعَشِيِّ يُرِيدُونَ وَجۡهَهُۥۖ مَا عَلَيۡكَ مِنۡ حِسَابِهِم مِّن شَيۡءٖ وَمَا مِنۡ حِسَابِكَ عَلَيۡهِم مِّن شَيۡءٖ فَتَطۡرُدَهُمۡ فَتَكُونَ مِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ ٥٢

Walā tatrudil-ladhīna yad'ūna rabbahum bil-ghadawāti wal-'ashiyyi yurīdūna wajhahū mā 'alayka min hisābihim min shay'in wamā min hisābika 'alayhim min shay'in fatatrudahum fatakūna minaz-zālimīn

Má ṣe lé àwọn tó ń pe Olúwa wọn ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́ dànù; wọ́n ń fẹ́ Ojú rere Rẹ̀ ni. Ìṣirò-iṣẹ́ wọn kò sí ní ọrùn rẹ ní ọ̀nà kan kan. Kò sì sí ìṣirò-iṣẹ́ tìrẹ náà ní ọrùn wọn ní ọ̀nà kan kan. Tí o bá lé wọn dànù, o sì máa wà nínú àwọn alábòsí.1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Āyah yìí ń sọ nípa àwọn Sọhābah tí wọ́n jẹ́ tálíkà pọ́nńbélé, gẹ́gẹ́ bí āyah 53 tí ó tẹ̀lé āyah yìí ṣe fi hàn, wọn kì í ṣe sūfī gẹ́gẹ́ bí àwọn òpùrọ́ kan ṣe lérò.