Ẹ̀kọ́ 3 nínú 3
Kí ni Mùsùlùmí tuntun gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe?
Láti inú Al-Qur'ān
لَا يُكَلِّفُ ٱللَّهُ نَفۡسًا إِلَّا وُسۡعَهَاۚ لَهَا مَا كَسَبَتۡ وَعَلَيۡهَا مَا ٱكۡتَسَبَتۡۗ رَبَّنَا لَا تُؤَاخِذۡنَآ إِن نَّسِينَآ أَوۡ أَخۡطَأۡنَاۚ رَبَّنَا وَلَا تَحۡمِلۡ عَلَيۡنَآ إِصۡرٗا كَمَا حَمَلۡتَهُۥ عَلَى ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِنَاۚ رَبَّنَا وَلَا تُحَمِّلۡنَا مَا لَا طَاقَةَ لَنَا بِهِۦۖ وَٱعۡفُ عَنَّا وَٱغۡفِرۡ لَنَا وَٱرۡحَمۡنَآۚ أَنتَ مَوۡلَىٰنَا فَٱنصُرۡنَا عَلَى ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡكَٰفِرِينَ ﴿٢٨٦﴾
Allāhu kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. (Ẹ̀san) ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (rere) ń bẹ fún un. (Ìyà) ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (ibi) ń bẹ fún un pẹ̀lú. Olúwa wa, má ṣe mú wa tí a bá gbàgbéra tàbí (tí) a bá ṣàṣìṣe. Olúwa wa, má ṣe di ẹrù tó wúwo lé wa lórí, gẹ́gẹ́ bí O ṣe dì í ru àwọn tó ṣíwájú wa. Olúwa wa, má ṣe dìrù wá ohun tí kò sí agbára rẹ̀ fún wa. Ṣàmójú kúrò fún wa, foríjìn wá, kí O sì ṣàánú wa. Ìwọ ni Aláfẹ̀yìntì wa. Nítorí náà, ràn wá lọ́wọ́ lórí ìjọ aláìgbàgbọ́.
وَجَٰهِدُواْ فِي ٱللَّهِ حَقَّ جِهَادِهِۦۚ هُوَ ٱجۡتَبَىٰكُمۡ وَمَا جَعَلَ عَلَيۡكُمۡ فِي ٱلدِّينِ مِنۡ حَرَجٖۚ مِّلَّةَ أَبِيكُمۡ إِبۡرَٰهِيمَۚ هُوَ سَمَّىٰكُمُ ٱلۡمُسۡلِمِينَ مِن قَبۡلُ وَفِي هَٰذَا لِيَكُونَ ٱلرَّسُولُ شَهِيدًا عَلَيۡكُمۡ وَتَكُونُواْ شُهَدَآءَ عَلَى ٱلنَّاسِۚ فَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُواْ ٱلزَّكَوٰةَ وَٱعۡتَصِمُواْ بِٱللَّهِ هُوَ مَوۡلَىٰكُمۡۖ فَنِعۡمَ ٱلۡمَوۡلَىٰ وَنِعۡمَ ٱلنَّصِيرُ ﴿٧٨﴾
Ẹ jagun fún ẹ̀sìn Allāhu ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ tí ẹ lè gbà jagun fún Un. Òun l’Ó ṣà yín lẹ́ṣà, kò sì kó ìdààmú kan kan ba yín nínú ẹ̀sìn. (Ẹ tẹ̀lé) ẹ̀sìn bàbá yín (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. (Allāhu) l’Ó sọ yín ní mùsùlùmí ṣíwájú (àsìkò yìí) àti nínú (al-Ƙur’ān) yìí nítorí kí Òjíṣẹ́ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún yín àti nítorí kí ẹ̀yin náà lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn. Nítorí náà, ẹ kírun, ẹ yọ Zakāh, kí ẹ sì bá Allāhu dúró. Òun ni Aláàbò yín. Ó dára ni Aláàbò. Ó sì dára ní Alárànṣe.
Láti inú Sunnah
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju larubawa oko kan wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ pe: Tọ mi sọ́nà lori iṣẹ kan ti mo ba ṣe e maa wọ alujanna, o sọ pe: "Maa jọsin fun Ọlọhun ki o si ma da nnkan kan pọ mọ Ọn, ki o maa gbe irun ti a ṣe ni dandan duro, ki o maa yọ saka ti a ṣe ni ọran-anyan, ki o maa gba awẹ Ramadan" O sọ pe: Mo fi ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura mi ko nii lekun lori eyi, nigba ti o pa ẹyin da, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: "Ẹni ti o ba dun mọ ọn lati wo arakunrin kan ninu awọn ara alujanna, ki o yaa wo eyi".
Àlàyé
Arakunrin kan ninu awọn ara oko wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lati tọ ọ sọ́nà lori iṣẹ ti o maa mu u wọ alujanna, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- da a lohun pe dajudaju wiwọ alujanna ati lila kuro nibi ina, méjèèjì duro lori pipe awọn origun Isilaamu, bii ijọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo, ati ki o si ma da nnkan kan pọ mọ Ọn. Ki o maa gbe irun maraarun-un ti Ọlọhun ṣe wọn ni dandan lori awọn ẹru Rẹ duro ni gbogbo ọsan ati oru. Ki o maa yọ saka owo ti Ọlọhun ṣe ni dandan lori rẹ, ki o si fun ẹni ti o lẹtọọ si i. Ki o maa ṣọ awẹ Ramadan ni asiko rẹ. Arakunrin naa sọ pe mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura pe mi ko nii lekun nnkan kan lori iṣẹ ti a ṣe ni ọran-anyan ti mo gbọ́ lọdọ rẹ ninu awọn itẹle, mi ko si nii dinkun ninu rẹ. Nigba ti o pẹyin da, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ẹni ti o ba dun mọ ọn ninu lati wo arakunrin kan ninu awọn ara alujanna, ki o yaa wo larubawa oko yii.
Lati ọdọ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹ maa ṣe idẹkun fun awọn èèyàn, ẹ ma ṣe fi ara ni wọn, ẹ maa fun awọn èèyàn ni ìró ìdùnnú, ẹ ma ṣe lé wọn sá”.
Àlàyé
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n pàṣẹ ki a maa ṣe idẹkun fun awọn èèyàn, ki a si ma fi ara ni wọn nibi gbogbo àlámọ̀rí ẹsin ati ayé, ìyẹn nibi ààlà nǹkan ti Ọlọhun ṣe ni ẹtọ ti O si ṣe ni ofin.
O n ṣeni lojukokoro lati maa fun wọn ni iro ìdùnnú nipa oore, ki a si ma le wọn sa kuro nibẹ.
Ìrìn-àjò ti parí
Ẹ kú iṣẹ́!
Dídi Mùsùlùmí
Ìrìn-àjò 1 nínú 6 ti parí
Bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò tó kànÒpó márùn-ún Ìsìlámù