قُلۡ مَن كَانَ عَدُوّٗا لِّـجِبۡرِيلَ فَإِنَّهُۥ نَزَّلَهُۥ عَلَىٰ قَلۡبِكَ بِإِذۡنِ ٱللَّهِ مُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِ وَهُدٗى وَبُشۡرَىٰ لِلۡمُؤۡمِنِينَ ٩٧
Qul man kāna 'aduwwal lijibrīla fa innahū nazzalahū 'alā qalbika bi idhnillāhi musaddiqal limā bayna yadayhi wahudan wabushrā lil-mu'minīn
Sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọ̀tá fún (mọlāika) Jibrīl,1 (ó ti di ọ̀tá Allāhu) nítorí pé, dájúdájú (mọlāika) Jibrīl ló sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ sínú ọkàn rẹ pẹ̀lú àṣẹ Allāhu. Al-Ƙur’ān sì ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wá ṣíwájú rẹ̀. Ó jẹ́ ìmọ̀nà àti ìdùnnú fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Mọlaika Jibrīl tún ní àwọn orúkọ mìíràn nínú al-Ƙur’ān. Nínú àwọn orúkọ rẹ̀ ni “ar-Rūh” - Ẹ̀mí - (sūrah al-Mọ‘ārij; 70:4), “rūhul-ƙudus” - Ẹ̀mí Mímọ́ - (sūrah an-Nahl; 16:102) àti “rūhul-’Amīn” - Ẹ̀mí Ìfàyàbalẹ̀, Ẹ̀mí tí kì í jàǹbá iṣẹ́ tí Allāhu fi rán an. - (sūrah aṣ-Ṣu‘arọ̄’; 26:193).