Ẹ̀kọ́ 5 nínú 11
Ẹ̀tọ́ wo ni àwọn obìnrin ní nínú Ìsìlámù?
Ìdáhùn ní ṣókí
Nínú Ìsìlámù, ẹ̀mí kan ṣoṣo ni ọkùnrin àti obìnrin ti wá, wọ́n sì dọ́gba lọ́dọ̀ Allāhu: ọkùnrin tàbí obìnrin èyíkéyìí tó bá gbàgbọ́ tó sì ṣe rere ni a ó fún ní ìgbésí ayé dáadáa àti ẹ̀san tó pé. Ìsìlámù fún àwọn obìnrin ní ẹ̀tọ́ láti ní dúkìá, láti pawó, láti jogún, láti gba sọ̀daàkí (mahr) àti kí a béèrè ìfọwọ́sí wọn ṣáájú ìgbéyàwó, ó sì pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin láti máa ṣe dáadáa sí àwọn obìnrin. Ànábì kò lu obìnrin kankan rí.
Qabas ló kọ ọ́, a sì ṣàyẹ̀wò rẹ̀ pẹ̀lú Al-Mukhtasar fī Tafsīr al-Qur'ān al-Karīm, Tafsīr Ibn Kathīr àti àwọn àlàyé HadeethEnc.com.
Láti inú Al-Qur'ān
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱتَّقُواْ رَبَّكُمُ ٱلَّذِي خَلَقَكُم مِّن نَّفۡسٖ وَٰحِدَةٖ وَخَلَقَ مِنۡهَا زَوۡجَهَا وَبَثَّ مِنۡهُمَا رِجَالٗا كَثِيرٗا وَنِسَآءٗۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ ٱلَّذِي تَسَآءَلُونَ بِهِۦ وَٱلۡأَرۡحَامَۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلَيۡكُمۡ رَقِيبٗا ﴿١﴾
Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan (ìyẹn, Ànábì Ādam). Ó sì ṣẹ̀dá aya rẹ̀ (Hawā’) láti ara rẹ̀. Ó fọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin jáde láti ara àwọn méjèèjì. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí ẹ̀ ń fi bẹ ara yín. (Ẹ ṣọ́) okùn-ìbí. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Olùṣọ́ lórí yín.
مَنۡ عَمِلَ صَٰلِحٗا مِّن ذَكَرٍ أَوۡ أُنثَىٰ وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَلَنُحۡيِيَنَّهُۥ حَيَوٰةٗ طَيِّبَةٗۖ وَلَنَجۡزِيَنَّهُمۡ أَجۡرَهُم بِأَحۡسَنِ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ﴿٩٧﴾
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere, ọkùnrin ni tàbí obìnrin, ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, dájúdájú A óò jẹ́ kí ó lo ìgbésí ayé tó dára. Dájúdájú A sì máa san wọ́n ní ẹ̀san rere wọn tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
إِنَّ ٱلۡمُسۡلِمِينَ وَٱلۡمُسۡلِمَٰتِ وَٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ وَٱلۡقَٰنِتِينَ وَٱلۡقَٰنِتَٰتِ وَٱلصَّٰدِقِينَ وَٱلصَّٰدِقَٰتِ وَٱلصَّٰبِرِينَ وَٱلصَّٰبِرَٰتِ وَٱلۡخَٰشِعِينَ وَٱلۡخَٰشِعَٰتِ وَٱلۡمُتَصَدِّقِينَ وَٱلۡمُتَصَدِّقَٰتِ وَٱلصَّٰٓئِمِينَ وَٱلصَّٰٓئِمَٰتِ وَٱلۡحَٰفِظِينَ فُرُوجَهُمۡ وَٱلۡحَٰفِظَٰتِ وَٱلذَّٰكِرِينَ ٱللَّهَ كَثِيرٗا وَٱلذَّٰكِرَٰتِ أَعَدَّ ٱللَّهُ لَهُم مَّغۡفِرَةٗ وَأَجۡرًا عَظِيمٗا ﴿٣٥﴾
Dájúdájú àwọn mùsùlùmí lọ́kùnrin àti mùsùlùmí lóbìnrin, àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu lọ́kùnrin àti àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu lóbìnrin, àwọn olódodo lọ́kùnrin àti àwọn olódodo lóbìnrin, àwọn onísùúrù lọ́kùnrin àti àwọn onísùúrù lóbìnrin, àwọn olùtẹríba fún Allāhu lọ́kùnrin àti àwọn olùtẹríba fún Allāhu lóbìnrin, àwọn olùtọrẹ lọ́kùnrin àti àwọn olùtọrẹ lóbìnrin, àwọn aláàwẹ̀ lọ́kùnrin àti àwọn aláàwẹ̀ lóbìnrin, àwọn tó ń ṣọ́ abẹ́ wọn lọ́kùnrin àti àwọn tó ń ṣọ́ abẹ́ wọn lóbìnrin, àwọn olùrántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ lọ́kùnrin àti àwọn olùrántí Allāhu (ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀) lóbìnrin; Allāhu ti pèsè àforíjìn àti ẹ̀san ńlá sílẹ̀ dè wọ́n.
لِّلرِّجَالِ نَصِيبٞ مِّمَّا تَرَكَ ٱلۡوَٰلِدَانِ وَٱلۡأَقۡرَبُونَ وَلِلنِّسَآءِ نَصِيبٞ مِّمَّا تَرَكَ ٱلۡوَٰلِدَانِ وَٱلۡأَقۡرَبُونَ مِمَّا قَلَّ مِنۡهُ أَوۡ كَثُرَۚ نَصِيبٗا مَّفۡرُوضٗا ﴿٧﴾
Àwọn ọkùnrin ní ìpín nínú ohun tí òbí méjèèjì àti ẹbí fi sílẹ̀. Àti pé àwọn obìnrin náà ní ìpín nínú ohun tí òbí méjéèjì àti ẹbí fi sílẹ̀. Nínú ohun tó kéré nínú rẹ̀ tàbí tó pọ̀; (ó jẹ́) ìpín tí wọ́n ti pín (tí wọ́n ti ṣàdáyanrí rẹ̀ fún wọn).
وَءَاتُواْ ٱلنِّسَآءَ صَدُقَٰتِهِنَّ نِحۡلَةٗۚ فَإِن طِبۡنَ لَكُمۡ عَن شَيۡءٖ مِّنۡهُ نَفۡسٗا فَكُلُوهُ هَنِيٓـٔٗا مَّرِيٓـٔٗا ﴿٤﴾
Ẹ fún àwọn obìnrin ní sọ̀daàkí wọn tó jẹ́ ọ̀ran-anyàn ní tọkàn-tọkàn. Tí wọ́n bá sì fi inú dídùn yọ̀ǹda kiní kan fún yín nínú rẹ̀, ẹ jẹ ẹ́ pẹ̀lú ìrọ̀rùn àti ìgbádùn.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا يَحِلُّ لَكُمۡ أَن تَرِثُواْ ٱلنِّسَآءَ كَرۡهٗاۖ وَلَا تَعۡضُلُوهُنَّ لِتَذۡهَبُواْ بِبَعۡضِ مَآ ءَاتَيۡتُمُوهُنَّ إِلَّآ أَن يَأۡتِينَ بِفَٰحِشَةٖ مُّبَيِّنَةٖۚ وَعَاشِرُوهُنَّ بِٱلۡمَعۡرُوفِۚ فَإِن كَرِهۡتُمُوهُنَّ فَعَسَىٰٓ أَن تَكۡرَهُواْ شَيۡـٔٗا وَيَجۡعَلَ ٱللَّهُ فِيهِ خَيۡرٗا كَثِيرٗا ﴿١٩﴾
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún yín láti jẹ àwọn obìnrin mógún pẹ̀lú ipá (bíi ṣíṣú obìnrin lópó.) Ẹ má ṣe fúnlẹ̀ mọ́ wọn nítorí kí ẹ le gba apá kan n̄ǹkan tí ẹ fún wọn àyàfi tí wọ́n bá hùwà ìbàjẹ́ tó fojú hàn. Ẹ bá wọn lòpọ̀ pẹ̀lú dáadáa. Tí ẹ bá kórira wọn, ó lè jẹ́ pé ẹ kórira kiní kan, kí Allāhu sì ti fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ oore sínú rẹ̀.