Àwọn ìbéèrè tí àwọn ènìyàn máa ń béèrè

Ẹ̀kọ́ 2 nínú 11

Kí ni Ìsìlámù sọ nípa Maryam, ìyá Ànábì Isa (Jésù)?

Ìdáhùn ní ṣókí

Maryam, ìyá Ànábì Isa, jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn obìnrin tí a bọ̀wọ̀ fún jùlọ nínú Ìsìlámù. Al-Qur'ān sọ pé Allāhu ṣà á lẹ́ṣà, Ó fọ̀ ọ́ mọ́, Ó sì ṣà á lẹ́ṣà lórí àwọn obìnrin ayé, èyí tí ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ ṣàlàyé pé ó túmọ̀ sí àwọn obìnrin àsìkò rẹ̀, a sì fi orúkọ rẹ̀ sọ odindi sura kan nínú Al-Qur'ān. Ó bí Isa nígbà tó jẹ́ wúńdíá, nípa iṣẹ́ ìyanu láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Ànábì kà á mọ́ àwọn obìnrin díẹ̀ tó dé ipò pípé.

Qabas ló kọ ọ́, a sì ṣàyẹ̀wò rẹ̀ pẹ̀lú Al-Mukhtasar fī Tafsīr al-Qur'ān al-Karīm, Tafsīr Ibn Kathīr àti àwọn àlàyé HadeethEnc.com.

Láti inú Al-Qur'ān

وَإِذۡ قَالَتِ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ يَٰمَرۡيَمُ إِنَّ ٱللَّهَ ٱصۡطَفَىٰكِ وَطَهَّرَكِ وَٱصۡطَفَىٰكِ عَلَىٰ نِسَآءِ ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿٤٢﴾ يَٰمَرۡيَمُ ٱقۡنُتِي لِرَبِّكِ وَٱسۡجُدِي وَٱرۡكَعِي مَعَ ٱلرَّٰكِعِينَ ﴿٤٣﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí àwọn mọlāika sọ pé: “Mọryam, dájúdájú Allāhu ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Ó fọ̀ ọ́ mọ́. Ó sì ṣà ọ́ lẹ́ṣà lórí àwọn obìnrin ayé (àsìkò tìrẹ). Mọryam, tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ. Forí kanlẹ̀ fún Un. Kí o sì dáwọ́tẹ orúnkún pẹ̀lú àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun).

Al-Imran 3:42-43Kà á nínú Al-Qur'ān

وَٱذۡكُرۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ مَرۡيَمَ إِذِ ٱنتَبَذَتۡ مِنۡ أَهۡلِهَا مَكَانٗا شَرۡقِيّٗا ﴿١٦﴾ فَٱتَّخَذَتۡ مِن دُونِهِمۡ حِجَابٗا فَأَرۡسَلۡنَآ إِلَيۡهَا رُوحَنَا فَتَمَثَّلَ لَهَا بَشَرٗا سَوِيّٗا ﴿١٧﴾ قَالَتۡ إِنِّيٓ أَعُوذُ بِٱلرَّحۡمَٰنِ مِنكَ إِن كُنتَ تَقِيّٗا ﴿١٨﴾ قَالَ إِنَّمَآ أَنَا۠ رَسُولُ رَبِّكِ لِأَهَبَ لَكِ غُلَٰمٗا زَكِيّٗا ﴿١٩﴾ قَالَتۡ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي غُلَٰمٞ وَلَمۡ يَمۡسَسۡنِي بَشَرٞ وَلَمۡ أَكُ بَغِيّٗا ﴿٢٠﴾ قَالَ كَذَٰلِكِ قَالَ رَبُّكِ هُوَ عَلَيَّ هَيِّنٞۖ وَلِنَجۡعَلَهُۥٓ ءَايَةٗ لِّلنَّاسِ وَرَحۡمَةٗ مِّنَّاۚ وَكَانَ أَمۡرٗا مَّقۡضِيّٗا ﴿٢١﴾

Sọ ìtàn Mọryam tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. (Rántí) nígbà tí ó yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ sí àyè kan ní ìlà òòrùn. Ó mú gàgá kan (láti fi ara rẹ̀ pamọ́) fún wọn. A sì rán mọlāika Wa sí i. Ó sì fara hàn án ní àwòrán abara pípé. (Mọryam) sọ pé: “Èmi sá di Àjọkẹ́-ayé kúrò lọ́dọ̀ rẹ, tí o bá jẹ́ olùbẹ̀rù (Allāhu).” (Mọlāika) sọ pé: “Èmi ni Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ, (Ó rán mi sí ọ) pé kí n̄g fún ọ ní ọmọkùnrin mímọ́ kan.” Ó sọ pé: “Báwo ni mo ṣe máa ní ọmọ nígbà tí abara kan kò fọwọ́ kàn mí, tí èmi kò sì jẹ́ alágbèrè.” (Mọlāika) sọ pé: “Báyẹn ló máa rí.” Olúwa rẹ sọ pé: “Ó rọrùn fún mi. Àti pé nítorí kí Á lè ṣe é ní àmì fún àwọn ènìyàn ni. Ó sì jẹ́ ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. Ó tún jẹ́ ọ̀rọ̀ tí A ti parí (tí ó gbọ́dọ̀ wá sí ìmúṣẹ.)”

Maryam 19:16-21Kà á nínú Al-Qur'ān

وَمَرۡيَمَ ٱبۡنَتَ عِمۡرَٰنَ ٱلَّتِيٓ أَحۡصَنَتۡ فَرۡجَهَا فَنَفَخۡنَا فِيهِ مِن رُّوحِنَا وَصَدَّقَتۡ بِكَلِمَٰتِ رَبِّهَا وَكُتُبِهِۦ وَكَانَتۡ مِنَ ٱلۡقَٰنِتِينَ ﴿١٢﴾

Àti Mọryam ọmọbìnrin ‘Imrọ̄n, èyí tí ó ṣọ́ abẹ́ rẹ̀. A sì fẹ́ atẹ́gùn sí i lára nínú atẹ́gùn ẹ̀mí tí A dá. Ó gbàgbọ́ lódodo nínú àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ̀ àti àwọn Tírà Rẹ̀. Ó sì wà nínú àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu.

At-Tahrim 66:12Kà á nínú Al-Qur'ān

Gbogbo ẹ̀kọ́