مَا جَعَلَ ٱللَّهُ مِنۢ بَحِيرَةٖ وَلَا سَآئِبَةٖ وَلَا وَصِيلَةٖ وَلَا حَامٖ وَلَٰكِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ يَفۡتَرُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَۖ وَأَكۡثَرُهُمۡ لَا يَعۡقِلُونَ ١٠٣
Mā ja'alallāhu mim bahīratin walā sā'ibatin walā wasīlatin walā hāmin walākinnal-ladhīna kafarū yaftarūna 'alallāhil-kadhiba wa aktharuhum lā ya'qilūn
Allāhu kò fi ẹran bahīrah, ẹran sā’ibah, ẹran wasīlah àti ẹran hām lọ́lẹ̀.1 Ṣùgbọ́n àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ni. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò ṣe làákàyè.
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Ìwọ̀nyí ni orúkọ tí àwọn Lárúbáwá fún àwọn ẹran-ọ̀sìn tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún àwọn òrìṣà wọn. Wọ́n sì ka àwọn ẹran náà kún ẹran òrìṣà.