إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُۚ وَٱذۡكُر رَّبَّكَ إِذَا نَسِيتَ وَقُلۡ عَسَىٰٓ أَن يَهۡدِيَنِ رَبِّي لِأَقۡرَبَ مِنۡ هَٰذَا رَشَدٗا ٢٤
Illā an yashā'allāhu wadhkur rabbaka idhā nasīta waqul 'asā an yahdiyani rabbī li aqraba min hādhā rashadā
Àyàfi (kí o fi kún un pé) “tí Allāhu bá fẹ́.” Ṣe ìrántí Olúwa rẹ nígbà tí o bá gbàgbé (láti sọ bẹ́ẹ̀ lásìkò náà). Kí o sì sọ (fún wọn) pé: “Ó rọrùn kí Olúwa mi tọ́ mi sọ́nà lórí rẹ̀ pẹ̀lú èyí tí ó súnmọ́ jù èyí lọ ní ìmọ̀nà (fún yín).”1
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Okùnfà āyah yìí ni pé, nígbà tí àwọn yẹhudi wá bi Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - léèrè nípa ọ̀rọ̀ àwọn ará inú ọ̀gbun àpáta pẹ̀lú èròǹgbà wọn pé tí ó bá jẹ́ Ànábì Ọlọ́hun ní ti òdodo, ó yẹ kí ó nímọ̀ nípa wọn, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì sọ fún wọn pé kí wọ́n wá gbọ́ ìtàn wọn ní ọjọ́ kejì pẹ̀lú èròǹgbà rẹ̀ pé Allāhu á ti fi ìmísí nípa wọn ránṣẹ́ sí òun. Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò sì sọ fún àwọn yẹhudi náà pé “tí Allāhu bá fẹ́.” Àmọ́ àì sọ bẹ́ẹ̀ rẹ̀ jẹ́ kí ọjọ́ àdéhùn tó ṣe fún wọn yẹ̀.