Òpó márùn-ún Ìsìlámù

Ẹ̀kọ́ 3 nínú 5

Kí ni zakat?

Láti inú Al-Qur'ān

خُذۡ مِنۡ أَمۡوَٰلِهِمۡ صَدَقَةٗ تُطَهِّرُهُمۡ وَتُزَكِّيهِم بِهَا وَصَلِّ عَلَيۡهِمۡۖ إِنَّ صَلَوٰتَكَ سَكَنٞ لَّهُمۡۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ ﴿١٠٣﴾

Gba ọrẹ (Zakāh) nínú dúkìá wọn, kí o fi sọ wọ́n di ẹni mímọ́, kí o sì fi ṣe àfọ̀mọ́ fún wọn. Ṣe àdúà fún wọn. Dájúdájú àdúà rẹ ni ìfàyàbalẹ̀ fún wọn. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

At-Tawbah 9:103Kà á nínú Al-Qur'ān

إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَأَقَامُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتَوُاْ ٱلزَّكَوٰةَ لَهُمۡ أَجۡرُهُمۡ عِندَ رَبِّهِمۡ وَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ ﴿٢٧٧﴾

Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n kírun, tí wọ́n sì yọ Zakāh, ẹ̀san wọn ń bẹ fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Kò sí ìpáyà fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.

Al-Baqarah 2:277Kà á nínú Al-Qur'ān

۞ إِنَّمَا ٱلصَّدَقَٰتُ لِلۡفُقَرَآءِ وَٱلۡمَسَٰكِينِ وَٱلۡعَٰمِلِينَ عَلَيۡهَا وَٱلۡمُؤَلَّفَةِ قُلُوبُهُمۡ وَفِي ٱلرِّقَابِ وَٱلۡغَٰرِمِينَ وَفِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱبۡنِ ٱلسَّبِيلِۖ فَرِيضَةٗ مِّنَ ٱللَّهِۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٞ ﴿٦٠﴾

Àwọn tí ọrẹ (Zakāh) wà fún ni àwọn aláìní, àwọn mẹ̀kúnnù, àwọn òṣìṣẹ́ Zakāh, àwọn tí ọkàn wọn fẹ́ gba ’Islām (ìyẹn àwọn tí wọ́n fẹ́ fi fa ọkàn wọn mọ́ra sínú ẹ̀sìn), àwọn ẹrú (fún gbígba òmìnira), àwọn onígbèsè, àwọn tó wà lójú ogun (ẹ̀sìn) Allāhu àti onírìn-àjò (tí agara dá). Ọ̀ran-anyàn ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

At-Tawbah 9:60Kà á nínú Al-Qur'ān

Láti inú Sunnah

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Sàárà kii din dúkìá kù, Ọlọhun kii le ẹrú kún pẹ̀lú amojukuro àyàfi ni iyì, ẹnikan ko nii tẹrí ba fun Ọlọhun àyàfi ki Ọlọhun gbe e ga”

Muslim gba a wa O ni alaafia HadeethEnc.com
Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe saara kii din dúkìá ku, bi ko ṣe pe o maa n ti àwọn nǹkan ti o le ba a jẹ́ danu, Ọlọhun si maa n fi oore ńlá rọ́pò fun ẹni tí n ṣe saara, o maa wa jẹ alekun ni kii ṣe adinku.

Amojukuro pẹlu ikapa lati gba ẹsan kii le ẹni ti o ba ṣe e kun nǹkan kan ayafi ni agbara.

Ẹnikan ko nii tẹrí ba tori ti Ọlọhun, ti kii ṣe ti ibẹru ẹnikẹ́ni, tabi ti ẹ̀tàn, tabi wiwa anfaani kan lọ́dọ̀ rẹ, àyàfi ki ẹsan rẹ o jẹ gíga ati iyì.

Gbogbo ẹ̀kọ́