Suratu At-Tawbah, aaya 103

9:103

خُذۡ مِنۡ أَمۡوَٰلِهِمۡ صَدَقَةٗ تُطَهِّرُهُمۡ وَتُزَكِّيهِم بِهَا وَصَلِّ عَلَيۡهِمۡۖ إِنَّ صَلَوٰتَكَ سَكَنٞ لَّهُمۡۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ ١٠٣

Khudh min amwālihim sadaqatan tutahhiruhum watuzakkīhim bihā wasalli 'alayhim inna salawātaka sakanul lahum wallāhu samī'un 'alīm

Gba ọrẹ (Zakāh) nínú dúkìá wọn, kí o fi sọ wọ́n di ẹni mímọ́, kí o sì fi ṣe àfọ̀mọ́ fún wọn. Ṣe àdúà fún wọn. Dájúdájú àdúà rẹ ni ìfàyàbalẹ̀ fún wọn. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Àwọn ikọ̀ méjì ni āyah yìí ń sọ nípa wọn. Ikọ̀ kìíní ni àwọn tó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá wọn - ní ìbámu sí āyah 102 tó ṣíwájú. Ikọ̀ kejì ni àwọn tó ń yọ zakāh. Zakāh yíyọ sì jẹ́ àfọ̀mọ́ dúkìá fún ẹni tí ó yọ ọ́.