Ẹ̀kọ́ 8 nínú 11
Ṣé Ìsìlámù fàyè gba pípa àwọn aláìṣẹ̀?
Ìdáhùn ní ṣókí
Rárá. Ìsìlámù ṣe pípa ẹ̀mí aláìṣẹ̀ èyíkéyìí ní èèwọ̀. Al-Qur'ān sọ pé Allāhu ṣe é ní òfin pé ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹ̀mí kan láìtọ́, “ó dà bí ẹni tí ó pa gbogbo ènìyàn pátápátá”, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gba ẹ̀mí kan là, “ó dà bí ẹni tí ó mú gbogbo ènìyàn ṣẹ̀mí pátápátá”. Nínú ogun, àwọn ọmọ ogun ọ̀tá nìkan ni àwọn Mùsùlùmí lè bá jà, wọn kò sì gbọ́dọ̀ pa àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé, àwọn àgbàlagbà tàbí àwọn mìíràn tí kò jagun láé. Ànábì kìlọ̀ pé ẹnikẹ́ni tó bá pa ẹni tí kì í ṣe Mùsùlùmí tí àwọn Mùsùlùmí ti fún ní àdéhùn ààbò, kò ní gbọ́ òórùn Ọgbà Ìdẹ̀ra rárá.
Qabas ló kọ ọ́, a sì ṣàyẹ̀wò rẹ̀ pẹ̀lú Al-Mukhtasar fī Tafsīr al-Qur'ān al-Karīm, Tafsīr Ibn Kathīr àti àwọn àlàyé HadeethEnc.com.
Láti inú Al-Qur'ān
مِنۡ أَجۡلِ ذَٰلِكَ كَتَبۡنَا عَلَىٰ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ أَنَّهُۥ مَن قَتَلَ نَفۡسَۢا بِغَيۡرِ نَفۡسٍ أَوۡ فَسَادٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَكَأَنَّمَا قَتَلَ ٱلنَّاسَ جَمِيعٗا وَمَنۡ أَحۡيَاهَا فَكَأَنَّمَآ أَحۡيَا ٱلنَّاسَ جَمِيعٗاۚ وَلَقَدۡ جَآءَتۡهُمۡ رُسُلُنَا بِٱلۡبَيِّنَٰتِ ثُمَّ إِنَّ كَثِيرٗا مِّنۡهُم بَعۡدَ ذَٰلِكَ فِي ٱلۡأَرۡضِ لَمُسۡرِفُونَ ﴿٣٢﴾
Nítorí ìyẹn, A sì ṣe é ní òfin fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl pé, dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹ̀mí (ènìyàn) kan láìjẹ́ nítorí pípa ẹ̀mí (ènìyàn) kan tàbí ṣíṣe ìbàjẹ́ kan lórí ilẹ̀, ó dà bí ẹni tí ó pa gbogbo ènìyàn pátápátá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mú ẹ̀mí (ènìyàn) ṣẹ̀mí, ó dà bí ẹni tí ó mú gbogbo ènìyàn ṣẹ̀mí pátápátá. Àwọn Òjíṣẹ́ Wa sì ti wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú. Lẹ́yìn náà, dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú wọn lẹ́yìn ìyẹn ni alákọyọ lórí ilẹ̀.
وَقَٰتِلُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ ٱلَّذِينَ يُقَٰتِلُونَكُمۡ وَلَا تَعۡتَدُوٓاْۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ ٱلۡمُعۡتَدِينَ ﴿١٩٠﴾
Ẹ gbé ogun ẹ̀sìn dìde ní ojú-ọ̀nà Allāhu sí àwọn tó ń gbé ogun dìde sí yín. Kí ẹ sì má ṣe tayọ ẹnu-ààlà. Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ àwọn olùtayọ ẹnu-ààlà.
Láti inú Sunnah
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹni ti o ba pa ẹni a gba adehun lọwọ rẹ ko nii gbọ́ oorun alujanna, ati pe dajudaju oorun rẹ wọn maa n gbọ́ ọ lati ijinna ogoji ọdun”.
Àlàyé
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé adehun iya ti o le koko to wa lori pe dajudaju ẹni ti o ba pa ẹni ti a gba adehun lọwọ rẹ- oun ni ẹni ti o wọ ilẹ̀ Isilaamu ninu awọn alaigbagbọ pẹlu adehun ati ifọkanbalẹ- pe ẹni naa ko nii gbọ́ oorun alujanna, ati pe dajudaju oorun rẹ maa jẹ ijiina irin ogoji ọdun.
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji-: Dajudaju wọn ri arabinrin kan ti wọn ti pa ninu ọkan ninu awọn ogun ti Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- ja, nitori naa, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- kọ pipa awọn obinrin ati awọn ọmọde.
Àlàyé
Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- ri arabinrin kan ti wọn ti pa ni ọkan ninu awọn ogun ti o ja, nitori naa o kọ pipa awọn obinrin ati awọn ọmọde ti wọn o tii balaga.