وَجَعَلۡنَا بَيۡنَهُمۡ وَبَيۡنَ ٱلۡقُرَى ٱلَّتِي بَٰرَكۡنَا فِيهَا قُرٗى ظَٰهِرَةٗ وَقَدَّرۡنَا فِيهَا ٱلسَّيۡرَۖ سِيرُواْ فِيهَا لَيَالِيَ وَأَيَّامًا ءَامِنِينَ ١٨
Waja'alnā baynahum wabaynal-qural-latī bāraknā fīhā quran zāhiratan waqaddarnā fīhas-sayra sīrū fīhā layāliya wa ayyāman āminīn
A sì fi àwọn ìlú kan tó wà ní gban̄gba sí ààrin ìlú tí A rán adágún odò sí1 àti àwọn ìlú tí A fi ìbùkún sí. A sì ṣètò ibùsọ̀ níwọ̀n-níwọ̀n fún ìrìn-àjò ṣíṣe sínú àwọn ìlú náà.2 Ẹ rìn lọ sínú wọn ní òru àti ní ojú ọjọ́ pẹ̀lú ìfàyàbalẹ̀.
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Ìyẹn àwọn Saba’ ní ilẹ̀ Yamọn. [2] Èyí ni pé, tí onírìn-àjò bá gbéra, ó máa kan àwọn ìlú lójú-ọ̀nà. Ó sì máa ríbi sinmi láti ìlú kan sí ìlú mìíràn láààrin àwọn ìlú tí ó wà láààrin ilẹ̀ Saba’ àti ìlú tí Allāhu fi ìbùkún sí, ìyẹn ilẹ̀ Ṣām.