فَقَالُواْ رَبَّنَا بَٰعِدۡ بَيۡنَ أَسۡفَارِنَا وَظَلَمُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ فَجَعَلۡنَٰهُمۡ أَحَادِيثَ وَمَزَّقۡنَٰهُمۡ كُلَّ مُمَزَّقٍۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّكُلِّ صَبَّارٖ شَكُورٖ ١٩
Faqālū rabbanā bā'id bayna asfārinā wazalamū anfusahum faja'alnāhum ahādītha wamazzaqnāhum kulla mumazzaqin inna fī dhālika la'āyātil likulli sabbārin shakūr
(Àwọn ará ìlú Saba’) wí pé: “Olúwa wa, mú àwọn ìrìn-àjò wa láti ìlú kan sí ìlú mìíràn jìnnà síra wọn.” Wọ́n ṣe àbòsí sí ẹ̀mí ara wọn.1 A sì sọ wọ́n di ìtàn. A tú wọn ká pátápátá (ìlú wọn di ahoro). Dájúdájú àwọn àmì kan wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́.
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Ọ̀kan nínú oore tí Allāhu - Ọba Olóore - ṣe fún àwọn ará Saba’ ni pé, Ó fi àwọn ìlú tó já mọ́ra wọn yí wọn ká. Wọ́n sì ń rí oore púpọ̀ láti ara àwọn onírìn-àjò tó ń gba ìlú wọn kọjá. Àmọ́ wọn kò mọ ìwọ̀nyí sí oore.