Suratu At-Tawbah, aaya 36

9:36

إِنَّ عِدَّةَ ٱلشُّهُورِ عِندَ ٱللَّهِ ٱثۡنَا عَشَرَ شَهۡرٗا فِي كِتَٰبِ ٱللَّهِ يَوۡمَ خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ مِنۡهَآ أَرۡبَعَةٌ حُرُمٞۚ ذَٰلِكَ ٱلدِّينُ ٱلۡقَيِّمُۚ فَلَا تَظۡلِمُواْ فِيهِنَّ أَنفُسَكُمۡۚ وَقَٰتِلُواْ ٱلۡمُشۡرِكِينَ كَآفَّةٗ كَمَا يُقَٰتِلُونَكُمۡ كَآفَّةٗۚ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلۡمُتَّقِينَ ٣٦

Inna 'iddatash-shuhūri 'indallāhithnā 'ashara shahran fī kitābillāhi yawma khalaqas-samāwāti wal-arda minhā arba'atun hurumun dhālikad-dīnul-qayyimu falā tazlimū fīhinna anfusakum waqātilul-mushrikīna kāffatan kamā yuqātilūnakum kāffatan wa'lamū annallāha ma'al-muttaqīn

Dájúdájú òǹkà àwọn oṣù lọ́dọ̀ Allāhu ń jẹ́ oṣù méjìlá nínú àkọsílẹ̀ ti Allāhu ní ọjọ́ tí Ó ti dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Mẹ́rin ni oṣù ọ̀wọ̀ nínú rẹ̀.1 Ìyẹn ni ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀.2 Nítorí náà, ẹ má ṣàbòsí sí ara yín nínú àwọn oṣù ọ̀wọ̀. Kí ẹ gbógun ti gbogbo àwọn ọ̀ṣẹbọ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń gbógun tì gbogbo yín. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Àwọn oṣù ọ̀wọ̀ ni oṣù kìíní, Muharram; oṣú keje, Rajab; oṣù kọkànlá, Thul-Ƙọ‘dah àti oṣù kejìlá, Thul-Hijjah. [2] Ìyẹn ni pé, lára ẹ̀sìn àti ìjọ́sìn ’Islām ni lílo àwọn oṣù wọ̀nyí nítorí pé, oṣù náà ni à ń lò fún jíjọ́sìn fún Allāhu - subhānahu -.