Suratu An-Nisa, aaya 157

4:157

وَقَوۡلِهِمۡ إِنَّا قَتَلۡنَا ٱلۡمَسِيحَ عِيسَى ٱبۡنَ مَرۡيَمَ رَسُولَ ٱللَّهِ وَمَا قَتَلُوهُ وَمَا صَلَبُوهُ وَلَٰكِن شُبِّهَ لَهُمۡۚ وَإِنَّ ٱلَّذِينَ ٱخۡتَلَفُواْ فِيهِ لَفِي شَكّٖ مِّنۡهُۚ مَا لَهُم بِهِۦ مِنۡ عِلۡمٍ إِلَّا ٱتِّبَاعَ ٱلظَّنِّۚ وَمَا قَتَلُوهُ يَقِينَۢا ١٥٧

Waqawlihim innā qatalnal-masīha 'īsabna maryama rasūlallāhi wamā qatalūhu wamā salabūhu walākin shubbiha lahum wa innal-ladhīnakhtalafū fīhi lafī shakkim minhu mā lahum bihī min 'ilmin illat-tibā'az-zanni wamā qatalūhu yaqīnā

Àti nítorí ọ̀rọ̀ wọn (yìí): “Dájúdájú àwa pa Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam Òjíṣẹ́ Allāhu.” Wọn kò pa á, wọn kò sì kàn án mọ́ igi àgbélébùú, ṣùgbọ́n A gbé àwòrán rẹ̀ wọ ẹlòmíìràn fún wọn ni.1 Dájúdájú àwọn tó yapa-ẹnu lórí rẹ̀, kúkú wà nínú iyèméjì lórí rẹ̀; kò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa rẹ̀ àfi títẹ̀lé àbá dídá. Wọn kò pa á ní ti àmọ̀dájú.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìtúmọ̀ mìíràn “ṣùgbọ́n a fi rú wọn lójú / ṣùgbọ́n a dà á rú mọ́ wọn lójú”.