Suratu An-Nahl, aaya 124

16:124

إِنَّمَا جُعِلَ ٱلسَّبۡتُ عَلَى ٱلَّذِينَ ٱخۡتَلَفُواْ فِيهِۚ وَإِنَّ رَبَّكَ لَيَحۡكُمُ بَيۡنَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فِيمَا كَانُواْ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَ ١٢٤

Innamā ju'ilas-sabtu 'alal-ladhīnakhtalafū fīhi wa inna rabbaka layahkumu baynahum yawmal-qiyāmati fīmā kānū fīhi yakhtalifūn

Àwọn tí wọ́n ṣe (àgbéga) ọjọ́ Sabt fún ni àwọn tó yapa-ẹnu lórí rẹ̀.1 Dájúdájú Olúwa rẹ yóò kúkú ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Yíyapa-ẹnu tí àwọn yẹhudi yapa-ẹnu lórí ṣíṣe àgbéga fún ọjọ́ Jímọ̀, tí wọ́n sì fi ọjọ́ Sabt dípò rẹ̀, l’ó ṣokùnfà bí ọjọ́ náà ṣe di dandan fún ọ̀wọ́ wọn nìkan láti ṣe àgbéga rẹ̀.