وَإِذۡ أَوۡحَيۡتُ إِلَى ٱلۡحَوَارِيِّـۧنَ أَنۡ ءَامِنُواْ بِي وَبِرَسُولِي قَالُوٓاْ ءَامَنَّا وَٱشۡهَدۡ بِأَنَّنَا مُسۡلِمُونَ ١١١
Wa idh awhaytu ilal-hawāriyyina an āminū bī wabirasūlī qālū āmannā washhad bi annanā muslimūn
(Rántí) nígbà tí Mo fi mọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ1 nínú ọkàn wọn pé kí wọ́n gbàgbọ́ nínú Èmi àti Òjíṣẹ́ Mi. Wọ́n sọ pé: “A gbàgbọ́. Kí o sì jẹ́rìí pé dájúdájú mùsùlùmí ni wá.”
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 “Hawāriyyūn” túmọ̀ sí àwọn ọmọlẹ́yìn. Ipò tí àwọn Sọhābah àti Ansọ̄r wà sí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni ipò tí àwọn hawāriyyūn wà sí Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Nítorí náà, àwọn ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ ara wọn.