Suratu Al-Ma'idah, aaya 108

5:108

ذَٰلِكَ أَدۡنَىٰٓ أَن يَأۡتُواْ بِٱلشَّهَٰدَةِ عَلَىٰ وَجۡهِهَآ أَوۡ يَخَافُوٓاْ أَن تُرَدَّ أَيۡمَٰنُۢ بَعۡدَ أَيۡمَٰنِهِمۡۗ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱسۡمَعُواْۗ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡفَٰسِقِينَ ١٠٨

Dhālika adnā an ya'tū bish-shahādati 'alā wajhihā aw yakhāfū an turadda aymānu ba'da aymānihim wattaqullāha wasma'ū wallāhu lā yahdil-qawmal-fāsiqīn

Ìyẹn súnmọ́ jùlọ láti mú ẹ̀rí jíjẹ́ wá ní ojú-pọ̀nnà rẹ̀ tàbí láti (lè là nínú) ìpáyà pé wọ́n yóò da ìbúra kan nù (ìbúra ẹni méjì àkọ́kọ́) lẹ́yìn ìbúra tiwọn (ìbúrà ẹni méjì kejì). Ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì gbọ́ràn. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Òfin yìí, òfin àsọọ́lẹ̀ lórí ogún, igun kan nínú àwọn onímọ̀ sọ pé, wọ́n ti pa ìdájọ́ rẹ̀ rẹ́, àmọ́ igun kejì sọ pé, wọn kò pa ìdájọ́ rẹ̀ rẹ́.