Suratu Al-Isra, aaya 5

17:5

فَإِذَا جَآءَ وَعۡدُ أُولَىٰهُمَا بَعَثۡنَا عَلَيۡكُمۡ عِبَادٗا لَّنَآ أُوْلِي بَأۡسٖ شَدِيدٖ فَجَاسُواْ خِلَٰلَ ٱلدِّيَارِۚ وَكَانَ وَعۡدٗا مَّفۡعُولٗا ٥

Fa idhā jā'a wa'du ūlāhumā ba'athnā 'alaykum 'ibādal lanā ulī ba sin shadīdin fajāsū khilālad-diyāri wakāna wa'dam maf'ūlā

Nítorí náà, nígbà tí àdéhùn fún àkọ́kọ́ nínú méjèèjì bá ṣẹlẹ̀,1 A máa gbé àwọn ẹrúsìn Wa kan, tí wọ́n lágbára gan-an, dìde si yín. Wọn yóò dá rògbòdìyàn sílẹ̀ láààrin ìlú (yín). Ó jẹ́ àdéhùn kan tí A máa mú ṣẹ.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìyẹn ni pé, nígbà tí àsìkò ìyà bá tó fún wọn lórí ìbàjẹ́ wọn tí wọ́n á ṣe nígbà àkọ́kọ́.