Suratu Al-Isra, aaya 4

17:4

وَقَضَيۡنَآ إِلَىٰ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ فِي ٱلۡكِتَٰبِ لَتُفۡسِدُنَّ فِي ٱلۡأَرۡضِ مَرَّتَيۡنِ وَلَتَعۡلُنَّ عُلُوّٗا كَبِيرٗا ٤

Waqadaynā ilā banī isrā'īla fil-kitābi latufsidunna fil-ardi marratayni walata'lunna 'uluwwan kabīrā

A sì fi mọ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nínú Tírà pé: “Dájúdájú ẹ máa ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ nígbà mejì.1 Dájúdájú ẹ tún máa ṣègbéraga tó tóbi.”

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìbàjẹ́ tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl ní ìsọ ti ìkìlọ̀, òhun ni pípa tí wọ́n máa fi ọwọ́ ara wọn pa Ànábì Zakariyyā - kí ọlà Allāhu máa bá a - àti pípa tí wọ́n tún máa fi ọwọ́ ara wọn pa Ànábì Yahyā - kí ọlà Allāhu máa bá a -.