Suratu Al-Isra, aaya 111

17:111

وَقُلِ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِي لَمۡ يَتَّخِذۡ وَلَدٗا وَلَمۡ يَكُن لَّهُۥ شَرِيكٞ فِي ٱلۡمُلۡكِ وَلَمۡ يَكُن لَّهُۥ وَلِيّٞ مِّنَ ٱلذُّلِّۖ وَكَبِّرۡهُ تَكۡبِيرَۢا ١١١

Waqulil-hamdu lillāhil-ladhī lam yattakhidh waladan walam yakul lahū sharīkun fil-mulki walam yakul lahū waliyyum minadh-dhulli wakabbirhu takbīrā

Kí o sì sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu,1 Ẹni tí kò fi ẹnì kan ṣe ọmọ. Kò sì ní akẹgbẹ́ nínú ìjọba. Kò sì ní ọ̀rẹ́ kan torí àìlágbára.”2 Gbé títóbi fún Un gan-an.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Fātihah;1:2. [2] Ìyẹn ni pé, mímú tí Allāhu - tó ga jùlọ - bá mú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ ní ọ̀rẹ́ kì í ṣe nítorí ìrànlọ́wọ́ wọn tàbí ìkúnlọ́wọ́ wọn, bí kò ṣe nítorí pé, Allāhu gan-an ní Olùrànlọ́wọ́ wọn, Alágbára àti Olùborí lórí wọn.